Tânia Cefira Gomes Burity (tí wọ́n bí ní 28 Oṣù Kẹẹ̀sán, Ọdún 1978) jẹ́ òṣèrébìnrin, olùgbéròyìn, atọ́kùn, àti afẹwàṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Àngólà.

Tânia Burity
Ọjọ́ìbíTânia Cefira Gomes Burity
28 Oṣù Kẹ̀sán 1978 (1978-09-28) (ọmọ ọdún 46)
Luanda
Orílẹ̀-èdèAngolan
Iṣẹ́Actress, journalist, radio host, model
Ìgbà iṣẹ́2001-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Burity ní ìlú Luanda, orílẹ̀-èdè Àngólà. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ́ ìgbéròyìn láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Instituto Médio de Economia de Luanda (IMEL) kí ó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Instituto Superior Privado de Angola. Burity ti ṣe iṣẹ́ olùgbéròyìn bẹ́ẹ̀ ló sì ti ṣiṣẹ́ rí ní ilé-ìtajà ṣáájú kí ó tó bọ́ sídi iṣẹ́ òṣèré.[1]

Láti ọdún 2001 sí 2004, òun ni atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù kan tí wọ́n pè ní Angola dá Sorte. Ní ọdún 2001, Burity kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Vidas Ocultas. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kó ipa ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Djamila nínu eré Reviravolta. Ní ọdún 2005, Burity kó ipa Cláudia nínu eré Sede de Viver. Láti ọdún 2005 sí ọdún 2006, ó kó ipa Eugénia nínu eré tẹlifíṣọ̀nù oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ 113. Òun ni olùkéde àti olóòtú ìròyìn fún ètò rédíò kan tí wọ́n pè ní Boa Noite Angola láti ọdún 2005 sí ọdún 2006.[2] Ní ọdún 2007, òṣèrékùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń ṣe Fredy Costa ṣí ọwọ́ rẹ̀ lé Burity lórí, èyí tí ó mu láti má leè ṣiṣẹ́ fún oṣù méjì tí wọ́n sì dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún Costa náà.[3]

Ní ọdún 2009, Burity kó ipa Camila gẹ́gẹ́ bi olùṣòwò nínu eré Minha Terra, Minha Mãe. Láàrin ọdún 2010 sí 2012, òun ni olùkéde àti olùdarí ètò rédíò kan tí ó wà fún àwọn ọmọdé tí wọ́n pè ní Karibrinca na Rádio. Burity tún ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi afẹwàṣiṣẹ́, ó sì ti ṣe atọ́kùn níbi ìdíje ẹwà Miss Luanda ti ọdún 2011. Ó kó ipa gẹ́gẹ́ bi agbani-nímọ̀ràn lóri ọ̀rọ̀ oge nínu eré kan ti ọdún 2012 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Windeck.[4] Ní ọdún 2014, ó tún ṣe atọ́kùn níbi ètò ìfihàn Big Brother Angola.[3] Ní ọdún 2016, Burity ṣe alága ìgbìmọ̀-onígbẹ̀ẹ́jọ́ fún ètò Casting JC Models àti Casting para Actores Agência Útima.[5]

Ọmọìyá rẹ̀ ni Dicla Burity, ẹni tí òun náà n ṣiṣẹ́ atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù.[6] Ìlú Lisbon ni Tânia Burity fi ṣe ìbùgbé, ó sì ti ní àwọn ọmọbìnrin méjì.[7]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
Year Title Role Notes
2001 Vidas Ocultas Special participant
2002 Reviravolta Djamila Special participant
2005 Sede de Viver Cláudia
2005-2005 113 Eugénia
2007 Entre o Crime e a Paixão
2009 Minha Terra, Minha Mãe Camila Antagonist
2012 Windeck Ofélia Voss Antagonist
2014 Big Brother Angola Special presenter Participant

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Tânia Burity Biografia". Neovibe (in Portuguese). Archived from the original on 2 November 2020. Retrieved 5 November 2020. 
  2. "Tânia Burity Biografia". Neovibe (in Portuguese). Archived from the original on 2 November 2020. Retrieved 5 November 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Yola Araújo e Tânia Burity ultrapassam desavenças" (in Portuguese). http://m.redeangola.info/yola-araujo-e-tania-burity-ultrapassam-desavencas/. Retrieved 5 November 2020. 
  4. "Tânia Burity Biografia". Neovibe (in Portuguese). Archived from the original on 2 November 2020. Retrieved 5 November 2020. 
  5. "Tânia Burity Biografia". Neovibe (in Portuguese). Archived from the original on 2 November 2020. Retrieved 5 November 2020. 
  6. "Tânia Burity indignada com comentários racistas contra a irmã Dicla Burity" (in Portuguese). http://platinaline.com/imprensa-portuguesa-ataca-fredy-costa-escandalo-do-passado-envolvendo-tania-burity-dicla-sofre-comentarios-racistas/. Retrieved 5 November 2020. 
  7. "TÂNIA BURITY: “GOSTO DE HOMENS MUSCULADOS”". Paratudo (in Portuguese). Archived from the original on 2 June 2021. Retrieved 5 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe