Taiwo (Taiye, Taye, Taiyewo)[1] jẹ́ orúkọ Yoruba tí àwọn Yorùbá má ń fún ọmọ tí ó bá kókó wáyé nínú àwọn ìbejì. Ó tún mò sí "ìbejì tí ó kókó tọ́ ayé wò" tàbí ẹni tí ó wá ṣáájú Kehinde.[2] Bí ó tilè jẹ́ wípé Taiwo ní ìbejì tí ó kókó wáyé, àwọn Yorùbá gbàgbó pé Taiwo ni àbúrò, wón sì tún gbàgbọ́ pé Kehinde rán Taiwo wá sínú ayé yìí láti mọ̀ bóyá àsìkò ti tó fún wọn láti wáyé, èyí ni ó jẹ́ kí wọ́n ma pè ọmọ àkókó àwọn ìbejì ní Taiwo, àdàpè fún "Tọ́ ayé wọ̀". Àwọn orúkọ méjèèjì yìí, (Taiwo àti Kehinde) jé orúkọ tí àwọn Yorùbá ń sọ àwọn ìbejì.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Taiye". Retrieved October 25, 2015. 
  2. "Taiwo". Online Nigeria: Nigerian Names and meanings. Retrieved June 10, 2015. 
  3. Herman Bauman (2008). African Safari for Jesus. Xlibris Corporation. ISBN 978-1-462-8253-70. https://books.google.com/books?id=JY6QWgk56a8C&pg=PA46.