The Antique (fíìmù)
The Antique jẹ́ fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ti ọdún 2014, Darasen Richards àti DJ Tee jẹ́ olùdarí rẹ̀. Lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré inú fíìmù yìí ni Olu Jacobs, Bimbo Akintola, Gabriel Afolayan, Ricardo Agbor, Seun Akindele àti Funsho Adeolu.[1][2][3]
The Antique | |
---|---|
Adarí | Darasen Richards DJ Tee |
Olùgbékalẹ̀ | Darasen Richards |
Òǹkọ̀wé | Darasen Richards |
Àwọn òṣèré |
|
Orin | Cobhams Asuquo |
Ìyàwòrán sinimá | DJ Tee |
Olóòtú | Dipo Teniola DJ Tee Darasen Richards |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Darasen Richards Films |
Olùpín | Silverbird Film Distribution |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 105 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
Àhunpọ̀ ìtàn
àtúnṣeFíìmù náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú agbègbè aláyọ̀ kan tí wọ́n ń gbádùn ara wọn nínú ìlú. Àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan kan ṣẹlẹ̀, ní kété tí àwọn àjèjì ènìyàn mẹ́ta wọ inú ìlú náà láti wá ṣàwárí nǹkan àtijọ́ kan tó ní agbára láti ṣe ìdábóòbò àwọn ènìyàn inú ìlú yẹn. Wọ́n borí àwọn jagunjagun ìlú náà, àwọn àjèjì yìí sì gbé nǹkan àtijọ́ náà lọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì mú kí ègún wọ ilẹ̀ náà.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ọmọ kan ṣoṣo tí ọba bí wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, tó sì wá ní bèbè ikú. Babaláwo fi tó wọn létí pé àìsí nǹkan àtijọ́ náà ló fa àìsàn yẹn. Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ yan ọmọbìnrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uki (Oge Indiana) láti lọ sínú igbó àwọn irúnmọlẹ̀, láti gba nǹkan àtijọ́ náà bọ̀,nítorí èyí ló le dẹ́kun ikú òjìji àti ìyàn tó ń mú ní ilẹ̀ náà.
Wọ́n sì tún yan àwọn jagunjagun mẹ́ta tó máa tẹ̀lé Uki títí tí wọ́n yóò fi rí nǹkan náà gbà padà. Ìrìn-àjò náà jọ èyí tí kò lè ṣe é ṣe nítorí wọ́n pàdé àwọn abàmì ẹ̀dá nínú igbó náà tó gbìyànjú láti dè wọ́n lọ́nà.
Àwọn akópa
àtúnṣe- Olu Jacobs bíi Oba Ekpen
- Bimbo Akintola bíi Queen 1
- Gabriel Afolayan bíi Uyi
- Ricardo Agbor bíi Oba Akugba
- Seun Akindele bíi Lead Invader
- Funso Adeolu bíi Enoma
- Oge Indiana bíi Ukinebo
- Kiki Omeili bíi Isoken
- Akpororo bíi Oriri
- Omowunmi Dada bíi Osas
- Theresa Edem bíi Princess
- Samuel Ajibola bíi Prince
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Olu Jacobs, Bimbo Akintola, Gabriel Afolayon & More in 'The Antique' Watch Trailer". bellanaija.com. 10 October 2014. Retrieved 21 March 2015.
- ↑ "Epic movie, 'The Antique' to hit cinemas". The NET NG. Retrieved 21 March 2015.
- ↑ "WATCH THE TRAILER: "THE ANTIQUE" MOVIE STARRING OLU JACOBS, BIMBO AKINTOLA, KIKI OMEILI & AKPORORO". Modern Ghana. Retrieved 21 March 2015.