Thembi Mtshali-Jones (tí wọ́n bí ní 7 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1949) jẹ́ òṣèrébìnrin, akọrin àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà.[1] Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ipa rẹ̀ nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù bíi Sgudi 'Snaysi, Stokvel, Silent Witness àti Imbewu.[2] Ó tún maá n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ ní Global Arts Corps, èyí tí ó wà ní Kosovo.

Thembi Mtshali-Jones
Ọjọ́ìbíThembi Mtshali-Jones
7 Oṣù Kọkànlá 1949 (1949-11-07) (ọmọ ọdún 75)
Vrede, Free State
Orílẹ̀-èdèSouth African
Iṣẹ́Actress, singer, playwright, teacher
Ìgbà iṣẹ́1970–present
Olólùfẹ́Emrys Jones (1999–2016)
Àwọn ọmọPhumzile
AwardsKentucky Colonel

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Thembi ní 7 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1949 ní abúlé Sabhoza nítòsí Ulundi ní ìlú Durban, orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà.[3] Kọ̀pẹ́ sí ìgbà tí wọ́n bi ni àwọn òbí rẹ̀ kọrawọn sílẹ̀.[4] Ó dàgbà ní ìlú KwaMashu níbití ó ti ní àwọn ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀.[5] Ó fi ilé-ìwé sílẹ̀ lẹ́hìn tí ó lóyún sínú.[6]

Ó ní ọmọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Phumzile, èyí tí ó bí fún ọkọ àkọ́kọ́ rẹ̀. Orúkọ ọkọ ẹ̀kejì rẹ̀ n ṣe Emrys Jones, ẹnití ó kéré sí Thembi lọ́jọ́ orí. Àwọn méjèjì pàdé nígbà tí Emrys wá láti wo eré tí Thembi dánìkan ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Woman in Waiting. Wọ́n gbé papọ̀ fún ọdún mẹ́tàdínlógún títí di ọjọ́ ikú Emrys ní ọdún 2016.[7]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

àtúnṣe

Thembi kópa nínu eré Welcome Msomi kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Umabatha. Lẹ́hìn náà ló darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin kan tó sì padà di asíwájú níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi 'Mama Tembu'. Ó lọ sí orílẹ̀-èdè USA láti tẹ̀síwájú iṣẹ́ orin rẹ̀, níbẹ̀ ló ti pàdé àwọn gbajúgbajà akọrin mìíràn tí orúkọ wọn ń ṣe Hugh Masekela àti Miriam Makeba,[8] tí wọ́n síì dì jọ ṣe eré orin káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù àti Áfríká fún àwọn ọdún bíi mẹ́lòó kan. Ní ọdún 1987, Thembi padà sí Gúúsù Áfríkà, ó síì darapọ̀ mọ́ ilé-ìṣeré Market Theatre. Ní ilé-ìṣeré náà ló ti ní ànfààní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Janice Honeyman nínu eré Black And White Follies.[9]

Láti ọdún 1970, ó ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré orí-ìpele. Òun pẹ̀lú Gcina Mhlophe àti Maralin Vanrenen dìjọ kọ eré kan tí wọ́n sì tún kópa nínu erè náà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Have You Seen Zandile. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ kan níbi ayẹyẹ Edinburgh Festival Fringe fún ipa rẹ̀ nínu eré náà. Lẹ́hìn náà, ó tún fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lúBarney Simon láti dìjọ kọ eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Eden and Other Places and Women of Africa.[10]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Àkọ́lé eré Ipa Irúfẹ̀ Ìtọ́kasí
1986 Sgudi 'Snaysi Thoko TV series
1988 Mapantsula Pat Film
2002 Stokvel Hazel TV series
2003 The Wooden Camera Madiba's Mother Film
2004 In My Country Lizzie Film
2004 Cape of Good Hope Ms. Silemeni Film
2010 Silent Witness Zali Silongo TV series
2010 Themba Sister Princess Film
2011 Buschpiloten küsst man nicht N'Nanga TV movie
2012 Copposites Constance Ralapele Film
2013 Weit hinter dem Horizont Desi TV movie
2014 Konfetti Lerato Cwele Film
2015 While You Weren't Looking Shado's Gogo Film
2015 Bleeding Gospel Theresa Short film
2018 Imbewu MaNdlovu Bhengu TV series
2019 Mother to Mother Mother Film

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe