Toks Olagundoye
Ọlátòkunbọ̀ Susan Ọlasobunmi Àbẹ̀kẹ́ Ọlágùndóyè (tí a bí ní 16 Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 1975) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ bi Hayley Shipton nínu Castle àti Jackie Joyner-Kersee nínu eré aláwàdà ABC TV kan tí a mọ̀ sí The Neighbors
Toks Olagundoye | |
---|---|
Olagundoye ni April 2013 | |
Ọjọ́ìbí | Olatokunbo Susan Olasobunmi Abeke Olagundoye 16 Oṣù Kẹ̀sán 1975[1] Lagos, Nigeria[2] |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Smith College |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 1996–iwoyi |
Olólùfẹ́ | Sean Quinn (m. 2015) |
Àwọn ọmọ | 1 |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Ọlátòkunbọ̀ Susan Olasobunmi Àbẹ̀kẹ́ Ọlágùndóyè ní ìlú Èkó. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nọ́rwèy tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ní ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Nàìjíríà, Swítsàlandì, àti Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì.[3][4] Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ ní ìtàgé láti Ilé-ẹ̀kọ́ Smith College.[5]
Iṣẹ́ ìṣe
àtúnṣeỌlágùndóyè ṣe ìfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ lóju amóhù-máwòran fún ti eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò ní ọdún 2002 nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Education of Max Bickford; àti fíìmù Brown Sugar. Ní ọdún 2001, ó kópa nínu eré orí ìpele kan, Saint Lucy's Eyes, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ruby Dee.[6] Ní ọdún 2005, ó ṣe àjọdásílẹ̀ ilé-iṣé ìtàgé kan tí wọ́n pè ní Three Chicks Theatre, èyítí ó ṣe àgbéjáde eré Andrea Lepcio kan, One Nation Under ní ọduń 2008.[1] Ọlágùndóyè ti ní ìfihàn àlejò nínu àwọn eré bi Ugly Betty, Law & Order, CSI: NY, Switched at Birth, NCIS: Naval Criminal Investigative Service àti Prime Suspect. Àwọn fíìmù míràn tí ó ní lórúkọ rẹ̀ pẹ̀lú A Beautiful Soul, Come Back to Me, Absolute Trust àti The Salon.
Ní ọdún 2012 Ọlágùndóyè jẹ́ olùkópa dédé nínu eré aláwàdà ABC kan The Neighbors,[7][8][9][10] níbi tí ó ti kó ipa Jackie Joyner-Kersee títí di ìgbà tí eré náà fi jẹ́ fífagilé ní ọdún 2014.[11] Lẹ́hìn náà ni ó tún ní àwọn ipa nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù méjì kan tí wọ́n ṣe fún ìwádì: Feed Me, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Mary-Louise Parker fún ilé-iṣẹ́ NBC; àti Salem Rogers ti Ámázọ̀n, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Leslie Bibb.[12][13] Ọlágùndóyè darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa ti eré aláwàdà ti ABC kan, Castle ní ọdún 2015 gẹ́gẹ́ bi olùkópa déédé fún ipa ti Hayley Shipton.[14]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Toks Olagundoye: Biography at TVGuide.com
- ↑ Toks Olagundoye at ABC MediaNet
- ↑ Àdàkọ:IMDb name
- ↑ Get To Know Toks Archived 2012-11-04 at the Wayback Machine. at her official website
- ↑ Get To Know Toks Archived 2012-11-04 at the Wayback Machine. at her official website
- ↑ Matthew Murray (2001-04-12). "Saint Lucy's Eyes Theatre Review by Matthew Murray". Matthew Murray. Talkin' Broadway.com, Inc.. https://www.talkinbroadway.com/ob/4_12_01.html. Retrieved 22 September 2015. "Though the new play, Saint Lucy's Eyes, which opened last night,"
- ↑ The Neighbors: First Look at ABC's New Alien Family Comedy Archived 2017-01-12 at the Wayback Machine., TVovermind.com, 15 May 2012.
- ↑ Andreeva, Nellie (December 11, 2011). "Pilot Castings: Four In Dan Fogelman Comedy, Jeff Eastin Drama Adds One". Deadline.com. PMC. Retrieved July 30, 2012.
- ↑ The Neighbors at ABC
- ↑ 31 Fresh Faces of Fall TV 2012, Zimbio.com
- ↑ Goldberg, Lesley (May 9, 2014). "ABC Cancels 'The Neighbors'". The Hollywood Reporter. Retrieved May 9, 2014.
- ↑ Nellie Andreeva. "Toks Olagundoye Joins NBC Pilot ‘Feed Me’, JoBeth Williams In ‘Your Family Or Mine’ - Deadline". Deadline. Retrieved 7 July 2015.
- ↑ "'The Neighbors' Actress Joins Amazon Comedy Pilot (Exclusive)". The Hollywood Reporter. Retrieved 7 July 2015.
- ↑ "'Castle' Enlists 'Neighbors' Favorite as Regular for Season 8". The Hollywood Reporter. Retrieved 7 July 2015.