Tokunbo Abiru
Mukhail Adetokunbo Abiru FCA (tí a bí ní 15th March ọdún 1964) jẹ́ òṣìṣẹ́ báǹkì àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni sẹ́nátọ̀ tó ń sojú àgbègbè senatorial Lagos east ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Tokunbo Abiru | |
---|---|
Senator for Lagos East | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga December 2020 | |
Asíwájú | Bayo Osinowo |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹta 1964 Lagos State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Feyishola Abiru |
Education | Harvard Business School Lagos State University |
Occupation | Banker |
Website | tokunboabiru.org |
Ó jẹ́ Olùdarí àti alákòso àgbà ilé ìfowópamọ́ Polaris bank limited, Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí. Ó lọ sí ètò ìṣàkóso ìlọsíwájú ti ilé-ìwé ìṣòwò Harvard tí ó wáyé fún òsẹ̀ mẹ́fà.[2] Ó gba òye B.Sc (Economics) ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ipínlẹ̀ èkó.[3] Ó jẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ tí institute of chartered accountants of Nigeria (ICAN) àti olùkọ́ni ọlà ti chartered institute of bankers of Nigeria (CIBN). Ní ọjọ́ 24th oṣù kẹ́jọ̀ ọ̀dún 2020, Abiru fi ìpò sílẹ ní báǹkì Polaris láti dijé du ìpò ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní èkó east lábẹ́ ìpìlẹ ẹgbẹ́ All Progressives Congress.[4]
Ọnà Iṣẹ́
àtúnṣeÒun ni ó jẹ́ Olùdarí àgbà ilé ìfọwópamọ́ First bank Nigeria Ltd láàrin ọdún 2013 sí 2016, ó sì tún jẹ́ kọmísónà fún ètò ìnáwó ní ìpìnlẹ̀ èkó láárín ọdún 2011 sí 2013 lábẹ́ ìdarí Babatunde R. Fashola (SAN) gẹ́gẹ́ bí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó.[5]
Central Bank of Nigeria (CBN) yàn án ní òṣù kèje ọdún 2016 gẹ́gẹ́ bí alákòso ẹgbẹ́ kan láti ran ilé ìfowópamọ́ Skye Bank nínú ewu tí ó ń báwọn fínra. Àṣeyọrí ẹgbẹ́ yìí ni ó jẹ́ kí ilé ìfowópamọ́ Polaris wà ní òní
.[6]
Tokunbo tún ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ pẹ̀lú Airtel Mobile Networks Limited, (báyìí FBN Quest Merchant Bank Limited); FBN bank sierra-leone limited; àti Nigeria inter-bank settlement system PLC(NIBBS). Lákọkọ́ àjàkáyé àrùn covid 19, ó ti ṣètorẹ̀ àwọn ìbojú ìparada 150,000 sí àwọn ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè rẹ̀.[7]
Àkọsílẹ Aladani
àtúnṣeLásìkò Abiru gẹ́gẹ́ bí kọmísónà fún ètò ìnáwó nípìnlẹ̀ èkó, ìpínlẹ̀ náà fi owo 80 billion naira, eléyìí tí ó gbà àmi ẹyẹ EMEA finance best local currency bond award fún 2012.[8] Ó ṣí àwọn ijiroro lórí owó-orí ní ìpínlẹ̀ èkó lẹ́hìn tí ìsawárí tí àwọn ènìyàn tí ó gbà owó-orí tí ó jù 5.5 million ní ọdún 2013.[9] Ìgbìyànjú rẹ̀ tún yọrí sí àlekùn àwọn ìrànwọ́ owo-wíwọlé lílò ile-ile sí ohun tí N6.2bn.[10]
Abiru tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Lagos HOMs committee, tí ó wà ní alábojuto Lagos state home ownership mortgage scheme (HOMs) tí á ṣe láti dínkù àìpé ilé ní ìpínlẹ̀ náà.
W
Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ ti Lagos East senatorial district nínú ìdìbò a ọjọ́ karùn-ún December, ọdún 2020
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe.[11]
- ↑ "Mirroring Abiru's strides in Lagos East - The Nation Newspaper". thenationonlineng.net. Retrieved 2022-03-16.
- ↑ "INEC declare APC Tokunbo Abiru winner of Lagos east senatorial seat". BBC News Pidgin. https://www.bbc.com/pidgin/tori-55205226.
- ↑ "CBN appoints Abiru, former Lagos finance commissioner, as Skye Bank CEO". The Cable. Retrieved 8 July 2016.
- ↑ "Tokunbo Abiru retires from Polaris Bank ahead of the senatorial election to replace Osinowo". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-08-24. Retrieved 2020-08-26.
- ↑ "Seven things you should know about Lagos East Senator-Elect, Abiru". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-06. Retrieved 2021-03-17.
- ↑ "Seven things you should know about Lagos East Senator-Elect, Abiru". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-06. Retrieved 2021-03-17.
- ↑ "Tokunbo Abiru Archives". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-03-17.
- ↑ Adagba (2 July 2013). "Lagos Bags International Award for Successful Local Bond Issue". News Herald. Archived from the original on 13 August 2018. Retrieved 8 July 2016.
- ↑ "LASG uncovers 5.5m tax evaders in informal sector - Vanguard News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-05-23. Retrieved 2016-07-08.
- ↑ "Lagos rakes in N6.28bn from Land Use Charge". Africa Aboard. 27 May 2013. Archived from the original on 13 August 2018. Retrieved 8 July 2016.
- ↑ "Lagos Homes Mortgage Scheme Takes Off As Fashola Inaugurates Board, Website (www.lagoshoms.gov.ng)". www.tundefashola.com. Retrieved 2016-07-08.
- ↑ "INEC declare APC Tokunbo Abiru winner of Lagos east senatorial seat". BBC News Pidgin. https://www.bbc.com/pidgin/tori-55205226.