Tosin Igho
Tosin Igho jẹ́ olùdarí fíìmù àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Tosin Igho | |
---|---|
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | AFDA, The School of motion picture medium |
Iṣẹ́ | Film director |
Gbajúmọ̀ fún | Seven (2019 Nigerian film) The Even. Nneka the pretty serpent 2020 |
Parent(s) | Peter Igho |
Awards | Africa Magic Viewers Choice Award Winner |
Ìgbésí-ayé àti iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeTosin jẹ́ ọmọ olóòtú ètò NTA tó gbajúmọ̀, tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Peter Igho.[1] Ó gba òye ẹ̀kọ́ nínú ìmọ Visual Effects láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti AFDA ní Cape Town, South Africa tí ó sì tún gba oyè bachelor's degree nínú ìmọ motion picture medium.[2][3] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórin, tí ó sì tún jẹ́ olùdarí àwọn fídíò orin lóríṣíriṣi. Ó ti fìgbà kan jẹ́ olùdarí fídíò orin èyí tí àwọn gbajúmọ̀ olórin bíi Mo' Hits Records' D'banj, Terry G, Faze, Yung L, Aramide àti Sammie Okposo.[4]
Àwọn fíìmù tó ti ṣe
àtúnṣeÓ jẹ́ aṣàgbéjáde àgbà fún àwọn ètò bíi Once Upon A Time, Judging Matters, Love Come Back (2020-2022), I am Laycon.[2][1]
Ó jẹ́ olùdarí fíìmù Seven (2019), The Eve (2018), Nneka the Pretty Serpent (2020), Team Six (2021), bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣiṣẹ́ lórí fíìmù Suspicion (2023)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Nollywood director, Tosin Igho set to launch films showcasing Nigeria". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-11-22. Retrieved 2022-07-20.
- ↑ 2.0 2.1 "Here is why Tosin Igho is currently one of the leading movie directors in Africa". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-18. Retrieved 2022-07-20.
- ↑ "Meet Nollywood leading movie director, Tosin Igho, flying Africa". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-16. Retrieved 2022-07-20.
- ↑ ogunlami, yinka (2018-04-11). "This might be the most colourful Nollywood film you'll see in 2018". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-20.