Ìmọ̀ Aáyan Ògbufọ̀

(Àtúnjúwe láti Translation studies)

Ìmọ̀ Aáyan-ògbufọ̀ jẹ́ ìmọ̀ iṣẹ́ alákadá tí ó kó ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ pọ̀ tí ó sì ń dojú kọ lílo ètò tíọ́rì, àpèjúwe àti ìṣàmúlò ìgbufọ̀ ṣíṣe, tapítà, àti ìsọdonílé. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ìmọ̀ ọlọ́pọ̀ ẹ̀ka, aáyan-ògbufọ̀ ṣe ọ̀pọ̀ ìmọ̀ láti inú àwọn ẹ̀ka-ẹ̀kọ tí wọ́n ṣe ìrànwọ́ fún aáyan-ògbufọ̀. Lára àwọn wọ̀nyí ni ìmọ̀ ìṣàfiwéra lítíréṣọ̀, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kọ́mpútà, imo-itan, ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè, ìmọ̀ àjọṣepọ̀ èdè, ìmọ́doyè, ìmọ̀ ìfara-fohùnsọ, àti ìmédèbágbàmu.

Èdè ìperí yìí "translation studies" jẹ́ èyí tí onímọ̀ ọmọ ilẹ̀ America tí ó Amsterdam ṣe ibùjókòó ni James S. Holmes fi lọ́lẹ̀ nínú bébà akadá rẹ̀ ti ọdún 1972 "The name and nature of translation studies",[1] èyí tí ó di ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ọ̀rọ̀ fún ẹ̀ka-ìmọ̀ náà.[2] Àwọn tí wọ́n ń fi èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ̀wé máa ń lo èdè ìpérí "translatology" lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan (ìlò "traductology" kò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́ pọ̀) láti pè ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀, èdè ìperí tí ó sì bá èyí mu nínú èdè Faranse ni "traductologie" (gẹ́gẹ́ bí Société Française de Traductologie ṣe sọ). Ní United States, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti lo èdè ìperí "ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ àti tapítà" (gẹ́gẹ́ bí ó se wà nínú American Translation and Interpreting Studies Association), Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀dálẹ̀ ìmọ̀ yìí ní Europe náà máa ń sọ̀rọ̀ tapítà gẹ́gẹ́ bí àkóónú ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú European Society for Translation Studies Àjọ Ìmọ̀ Aáyan-ògbufọ̀ ti ilẹ̀ Europe).

Àwọn Ìwádìí Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ ti wà, ó pẹ́ gẹhgẹ́ bí "ìwòye" (tí ó ń sọ bí àwọn ògbufọ̀ ṣe lè se ìgbufọ̀), títí tí ó fi dé ọ̀gangan pé àwọn àṣàrò tí ó jẹmọ́ aáyan-ògbufọ̀ tí kò fi ti ìwòyè (ìfitàlàyéṣe) kò di ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí àṣàrò nípa aáyan-ògbufọ̀ rárá. Nígbà tí àwọn òǹpìtàn nípa ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ tọpasẹ̀ èrò ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn èrò ilẹ̀ Apá Ìwò-oòrùn nípa aáyan-ògbufọ̀, bí àpẹerẹ, wọ́n máa ń lọ ìbẹrẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ gbájúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nì Cicero nípa bí ó ṣe ṣàmúlò aáyan-ògbufọ̀ láti inú èdè Greek sí Latin láti jẹ́ kí ipá ìṣọwọ́sọ̀rọ̀ rẹ̀ lè gbèrú si — èyí tí ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ohun tí Jerome padà pè ní aáyan-ògbufọ̀ ìfòye-dí-òyè. Ìtàn ìṣàpèjúwe àwọn tapítà ní Egypt tí Herodotus sọ ní ọ̀pọ̀ sẹ́ntúrì sẹ́yìn kì í ṣe èyí tí wọ́n gbà lẹ́rò ní ìlànà ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ — ní apá kan torí kò fi ìlànà aáyan-ògbufọ̀ ṣíṣe sílẹ̀ fún àwọn ògbufọ̀ láti mọ ìlànà ṣíṣe ìgbufọ̀. Ní China, ìtakùrọ̀sọ lórí bí wọ́n ṣe ìgbufọ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ìlànà títú Buddhist sutras ní àsìkò Tí Ìran Han Ń ṣèjọba.

Àwọn Ìpè fún Iṣẹ́ àti Akitiyan Ìmọ̀ Akadá

àtúnṣe

Ní 1958, ní ibi Àpérò àwọn Slavist Kẹrin ní Moscow, àríyànjiyàn nípa ìlànà lìǹgúísíìkì àti lítíréṣọ̀ ĺti ṣe aáyan-ògbufọ̀ dé ọ̀gangan ibi tí wọ́n ti dábàá pé ohun tí ó dára jùlọ lè jẹ́ láti ní ìmọ̀ sáyẹ́ńsì tí ó nípá láti ṣàlàyé gbogbo onírúnrú ìmọ̀ nípa aáyan-ògbufọ̀, láìṣe pé ó fi gbogbo ara mọ́ ìmọ̀ lìngúísíìkì tàbí kí ó fi gbogbo ara mọ́ ìmọ̀ lítíréṣọ̀.[3] Lágbo ìmọ̀ ìṣàfiwéra lítíréṣọ̀, àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ aáyan-ògbufọ̀ ni wọ́n gbé lárugẹ́ láàrin ọdún 1960 ní àwọn fásitì ilẹ̀ Amẹ́ríkà kọ̀ọ̀kan bí Fásitì ti Iowa University of Iowa àti Princeton.[4] Láàrin ọdún 1950 sí 1960, fífi ìmọ̀ lìǹgúísíìkì ajẹmétò kọ́ ìmọ̀ aáyan-ògufọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbodè. Ní 1958, onímọ̀ lìǹgúísíìkì ọmọ ilẹ̀ Faransé Jean-Paul Vinay àti Jean Darbelnet ṣe àfiwéra èdè Faransé àti Gẹ̀ẹ́sì [5] Ní 1964, Eugene Nida ṣe àtẹ̀jáde Toward a Science of Translating, tí ó jẹ́ atọ́nà fún ìlànà aáyan- ògbufọ̀ Bíbélì èyí tí ó kọ́ ìmọ̀ púpọ̀ lára iṣẹ́ Harris transformational grammar.[6] Ní 1965, J. C. Catford ṣe ìmọ̀ aáyan-ògbufọ̀ onítíọ́rì nípa ìwòye lìǹgúísíìkì.[7]Ní gbèdéke 1960s àti ní ìbẹ̀rẹ̀1970, onímọ̀ orílẹ̀-èè Czech tí ó ń jẹ́ Jiří Levý àti àwọn ti ilẹ̀ Anton Popovič àti František Miko ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ ìṣọwọ́lò-èdè aáyan-ògbufọ̀ ajẹmọ́lítíréṣọ̀.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Holmes, James S. (1972/1988). "The Name and Nature of Translation Studies". In Holmes, Translated! Papers on Literary Translation and Translation Studies, Amsterdam: Rodopi, pp. 67–80.
  2. Munday, Jeremy. 2008. Introducing Translation Studies. London and New York: Routledge. pp. 4
  3. Cary, Edmond. 1959. '"Murimi James". Introduction à la théorie de la traduction." Babel 5, p. 19n.
  4. Munday, Jeremy. 2008. Introducing Translation Studies. London and New York: Routledge. pp. 8
  5. Vinay, Jean-Paul and J.Darbelnet. 1958/1995. Comparative Stylistics of French and English: A Methodology for Translation. Amsterdam and Philadelphia: John Benjamins.
  6. Nida, Eugene. 1964. Toward a Science of Translating. Leiden: Murimi James.
  7. Catford, J.C., (1965). A Linguistic Theory of Translation. London: Longman.
  8. Levý, Jiří (1967). "Translation as a Decision Process". In To Honor Roman Jakobson. The Hague: Mouton, II, pp. 1171–1182.