Tunde Bakare, tí wọ́n bí ní November 11, 1954, jẹ́ wòlíì àti olùṣọ́-àgùntàn ti orílẹ́-èdè Nàìjíríà.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀-òfin ní University of Lagos, ó sì fi ṣiṣé látàri ṣíṣí ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀. Ó padà fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ Olúwa. Óṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i amòfin àgbà ní Deeper Life Bible Church, àmọ́ ó padà lọ sí Redeemed Christian Church of God, níbi tí ó ti di olùṣọ́-àgùntàn, tí ó sì ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ ìgbàlódé, ìyẹn Model Parish. Lẹ́yìn tí ó darapọ̀ mọ́ Redeemed Christian Church of God, Bakare kúrò láti lo ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ tirẹ̀, tí ó sọ ní Latter Rain Assembly Church. Lásìkò tí ó sì jẹ olùṣọ́-àgùntàn ìjọ náà, ó díje dupò ààrẹ orílẹ́-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú Muhammadu Buhari2011 Nigerian presidential election.[2] Ní ọdún 2019, Bakare ṣe ìkéde láti fi èrò rẹ̀ hàn láti díje dupò fún ipò ààrẹ, lẹ́yìn ìṣèjọba Buhari ẹlẹ́ẹ̀kejì.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ìdílé mùsùlùmí ni wọ́n bí Bakare sí, àmọ́ ó gba ẹ̀sìn kìrìsìtẹ́ẹ́nì ní ọdún 1974.[3][4]

Bakare lọ sí ilé-ìwé All Saints Primary School, Kemta, ní Abeokuta, àti Lisabi Grammar School, Abeokuta, lẹ́yìn tí ó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀-òfin ní University of Lagos láàrin ọdún 1977 àti 1980. Wọ́n pè é sí ẹgbẹ́ àwọn adájọ́ ti ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1981. Lásìkò tó ń sin orílẹ̀-èdè rẹ̀, ìyẹn National Youth Service Corps (NYSC), ó ṣiṣẹh ní Gani Fawehinmi Chambers, Rotimi Williams & Co., àti Burke & Co., Solicitors. Ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ tó pè ní Tunde Bakare & Co. (El-Shaddai Chambers), ní October 1984.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. New religious movements in the twenty-first century. Routledge. 2004. p. 174. https://archive.org/details/newreligiousmove0000unse_t4s7. 
  2. "Nigeria's 'prophet of doom' detained". The Independent (South Africa). 3 March 2002. http://www.iol.co.za/index.php?sf=86&set_id=1&click_id=68&art_id=qw1015158240108B252. Retrieved 26 April 2009. 
  3. McAnthony, Michael (29 July 2019). "I was once a Muslim- Pastor Tunde Bakare". The Christian Cornet. Retrieved 9 September 2019. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. 4.0 4.1 Bakare, Tunde. "About Tunde Bakare". tundebakare.com. Archived from the original on 2014-10-06. Retrieved 2023-11-23.