Uche Ekwunife
Uche Lilian Ekwunife (Orúko abiso rè ni Ogudebe) ti a bi 12 January 1970 jẹ oloṣelú omobibi orílè-èdè Nàìjirià. Ó wà lara awon ti ọmọ ile igbimọ aṣo(Senato) kesan ti Nàìjirià, óún se a o ṣoju awọn eniyan Anambra Central Senatorial District ti Anambra. [1]
Uche Ekwunife | |
---|---|
Senator Uche Ekwunife | |
Senator ikọ̀ Anambra Central Senatorial District | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga June 2015 | |
Asíwájú | Victor Umeh |
Member of the Nigerian House of Representatives from Anambra | |
In office June 2007 – June 2015 | |
Constituency | Anaocha/Njikoka/Dunukofia |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Uche Lilian Ogudebe 12 Oṣù Kejìlá 1970 Igbo-Ukwu, Anambra, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | People's Democratic Party (PDP) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Larry Ekwunife |
Alma mater | University of Calabar (BSc) Nnamdi Azikiwe University (MBA) |
Website | https://senucheekwunife.com |
Àárò ayé àti èkó rè
àtúnṣeA bi Ekwunife ni 12 December 1970 ni ilu Igbo-Ukwu, Anambra si inú idile Emmanuel ati Lucy Ogudebe. Ekwunife losi yunifasiti ti Calabar, o si kékó gboye ninu Business ati Accounting ni odun 1993. O tesiwaju lati gba oye MBA re ní ilé-ìwé giga Nnamdi Azikiwe ni 2002. [2] Ó fé Chief Larry Ekwunife [3]
Òsèlú
àtúnṣeEkwunife díje fun ipo gomina Anambra lẹẹmeji laisi aṣeyọri. O díje fun ile igbimo asofin kekere(house of representative) lati se aṣoju agbegbe Anaocha/Njikoka/Dunukofia ti Anambra ni odun 2007, o sì jawe olubori.[4] O jẹ ọkan ninu awọn obinrin mokanla ti a diboyan sí ipò náà ní ọdun 2007 ti a tún diboyan ni ọdun 2011. Awọn obinrin toku ti a yan ni Juliet Akano, Mulikat Adeola-Akande, Abike Dabiri, Nkiru Onyeagocha, Nnena Elendu-Ukeje, Olajumoke Okoya-Thomas, Beni Lar, Khadija Bukar Abba-Ibrahim, Elizabeth Ogbaga ati Peace Uzo.
Ní ọdún 2015, a yàn sí ipò Sẹ́nétọ̀ Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin mẹ́fà tí a yàn sí National Assembly kejo. Awọn obinrin yooku ni Rose Okoji Oko, Stella Oduah, Fatimat Raji Rasaki, Oluremi Tinubu ati Binta Garba.[5] Nitoripe Ekwunife yí padà lati egbé oselu kan sí imiran láti jawe olubori ninu idibo odun 2015, a yó kuro nípò Senato ní December 2015, a si yan Victor Umeh sí ipò Senato. [6]
O jawe olubori fún ipo ile igbimọ aṣofin agba ti ipinlẹ Anambra ni ọdun 2019 labẹ egbe oselu People's Democratic Party(PDP) , o se asoju Anambra Central Senatorial District, Nàìjirià, oludije alatako rè, Victor Umeh fìdíremi.
Àwon Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "ShineYourEye". ShineYourEye. Retrieved 2022-05-20.
- ↑ "EKWUNIFE, Sen Uche Lilian". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-08-23. Retrieved 2022-05-20.
- ↑ "Lilian Ekwunife biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 2015-12-07. Retrieved 2022-05-20.
- ↑ "Ekwunife wins re-run poll in Anambra". Premium Times Nigeria. 2012-02-16. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ Obiajuru, Nomso (2015-05-29). "MEET The 6 Female Senators In 8th National Assembly (PHOTOS)". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ Owete, Festus (2016-01-21). "APC panel disqualifies “fair-weather” Ekwunife from contesting Senate rerun on party’s platform". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-05-21.