Victor Ndoma-Egba
Olóṣèlú Nàìjíríà
Victor Ndoma-Egba (bíi ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹta ọdún 1956) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n dìbò yàn wọlé gẹ́gẹ́ bí aṣojú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti ilẹ̀ Nàìjíríà láti ọdún 2003.[1]
Victor Ndoma-Egba | |
---|---|
Aṣojú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti ilẹ̀ Nàìjíríà | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga Odún 2003 | |
Constituency | Àárín Cross River |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 8 Oṣù Kẹta 1956 |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | People's Democratic Party (PDP) |
Profession | Amòfin àti olóṣèlú |
Ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Victor Ndoma-Egba ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹta ọdún 1956 ní ilù Ikom, Ìpínlẹ̀ Cross River. Ó gba ìwé ẹ̀rí àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ òfin láti University of Lagos. Wọ́n pèé sí àwùjọ amòfin gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò ní ọdún 1978 tí ó si di Senior Advocate of Nigeria (SAN) ní ọdún 2004.[2] Ó ti fi ìgbàkan jẹ́ alága Nigerian Bar Association ti ẹ̀ka Calabar.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Sen. Victor Ndoma-Egba". National Assembly of Nigeria. Archived from the original on 2008-06-07. Retrieved 2009-09-16.
- ↑ "Senator Victor Ndoma-Egba: A Leader For The Ages". Times of Nigeria. July 10, 2009. Retrieved 2009-09-16.