Victor Olaotan
Victor Olaotan /θj/ (17 February 1952 – 26 August 2021) jẹ́ òṣèré Nàìjíríà tí ó gbajúmọ̀ fún ipa tó síwájú tí ó kó nínú soap opera Tinsel.[1]
Victor Olaotan | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Lagos, Nigeria | 17 Oṣù Kejì 1952
Aláìsí | 26 August 2021 | (ọmọ ọdún 69)
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan Obafemi Awolowo University |
Iṣẹ́ | Actor |
Notable work | Tinsel |
Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé àti Ẹ̀kọ́ Rẹ̀
àtúnṣeA bíi ní ìlú èkó, Lagos, Nigeria, ní 1952. Ó kẹkọọ ní University of Ibadan, Obafemi Awolowo University, àti Rockets University, United States.[2]
Iṣẹ́
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré University of Ibadan , níbi tí ó ti pàdé àwọn òṣèré míràn bíi ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka àti Jimi Solanke láàrin àwọn mìíràn. Ó di òṣèré nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹẹdogun nípasẹ̀ olùkọ́ kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèré Ori Olokun, ní ọdún 70's , látàrí ikú bàbá rẹ̀.[3] Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀,ó lọ sí United States ní 1978 ṣùgbọ́n ó padà sí Nàìjíríà ní 2002 láti t'ẹ̀síwájú nínú eré rẹ̀ ní ṣíṣe. Ó gbajúmọ̀ síi ní 2013 lẹ́yìn ipa tí ó síwájú tí ó kó nínú soap opera Tinsel ti Nàìjíríà èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí afẹ́fẹ́ ní oṣù kẹjọ ọdún 2008.[4] Òṣèré yìí ní ìjànbá ọkọ̀ ní oṣù kẹwa ọdún 2016 ó sì ní ìfarapa nervous system . Ó ń wa ọkọ̀ lọ sí ibùdó eré nígbà tí ìjànbá náà wáyé ní agbègbè Apple Junction, ní Festac, Èkó.
Ikú
àtúnṣeOlaotan kú ní 26 August 2021 ẹni ọdún ọ̀kan-dín-ní- àádọ́rin nípasẹ̀ ìfarapa ọpọlọ èyí tí ó wáyé látàrí ìjànbá ọkọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ síi ní October 2016.[5]
Filmography
àtúnṣe- Tinsel – Fred Ade-Williams (2008–2013)
- Towo Tomo (2013)
- Lovestruck
- Three Wise Men
See also
àtúnṣeReferences
àtúnṣe- ↑ "Age shouldn't be a barrier to looking good –Victor Olaotan, veteran actor". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 10 December 2014. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "Victor Olaotan : No woman can tempt me". Sun News. http://sunnewsonline.com/new/?p=71564. Retrieved 7 February 2015.
- ↑ ADETUTU AUDU & AYODELE OLALERE. "After 22 yrs in US, I returned to Nigeria with only 100----Victor Olaotan – nigeriafilms.com". nigeriafilms.com.
- ↑ "We earn peanuts – Tinsel star laments – Vanguard News". Vanguard News. 28 November 2013.
- ↑ "Nigerian Actor Victor Olaotan Is Dead At 69". The Guardian (Nigeria) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-08-27. Archived from the original on 27 August 2021. Retrieved 2021-08-27.