Wajiha Jendoubi (tí wọ́n bí ní ọdún 1972) jẹ́ òṣèrébìnrin àti apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Tùnísíà.

Wajiha Jendoubi
Wajiha Jendoubi, lórí ẹ̀rọ rédíò ti orílẹ̀-èdè ní ọjọ́ karùn ún oṣù kẹfà, ọdún 2017
Ọjọ́ìbí1972 (ọmọ ọdún 52–53)
Orílẹ̀-èdèTunisian
Iṣẹ́Actress, comedian
Ìgbà iṣẹ́1998-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Jendoubi lẹni tí wọ́n bí ní ọdún 1960[1] tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Kairouan, orílẹ̀-èdè Tùnísíà. Ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ eré ìtàgé ní ọdún 1995. Láti ṣe ọ̀kan nínu àwọn ojúṣe rẹ̀ fún ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, Jendoubi àti akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ kan dì jọ kọ ìtàn-eré kan tí wọ́n síì kó àwọn ipa eré náà. Ó ṣe àpèjúwe àwọn ipa náà bíi máleègbàgbé. Àwọn olùdarí eré tó n bẹ ní orílẹ̀-èdè Tùnísíà ṣe àkíyèsí rẹ̀ tí wọ́n sì fun ní ànfààní láti kópa nínu àwọn eré bíi Mnamet Aroussia, Ikhwa wa Zaman àti Aoudat Al Minyar. Eré Aoudat Al Minyar jẹ́ eré tí àwọn ènìyàn mọ̀ọ́ mọ́ jùlọ.[2] Ní ọdún 2010, ó kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Season of Men.[3]

Jendoubi kópa nínu eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Madame Kenza ní ọdún 2010, eré tí òun nìkan dá ṣe. Ó rí ìdùnnú látara dídánìkan wà lóri ìpele fún ṣíṣe eré náà.[4]

Ní ọdún 2015, wọ́n yan òun pẹ̀lú Myriam Belkadhi àti Emna Louzyr Ayari láti lọ ṣojú orílẹ̀-èdè Tùnísíà níbi àpèjọ kan tí ó wà fún ìjíròrò lóri fífi òpin sí ṣíṣe ẹ̀yàmẹyà sí àwọn obìnrin.[5]

Ní ọdún 2017, Jendoubi kópa gẹ́gẹ́ bi Bahja nínu fíìmù Salma Baccar kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ El Jaida.[6] Wọ́n yẹsí ní ọdún 2019 pẹ̀lú oyẹ̀ ìlú kan tí wọ́n pè ní Officer of the Order of the Republic.[7] Ní Oṣù Kejìlá Ọdún 2019, Jendoubi sọ di mímọ̀ wípé òun kò gba owó lọ́wọ ilé-iṣẹ́ ìkànnì Attessia TV fún iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe níbi àwọn ètò Le Président, Flashback àti Ali Chouerreb.[8]

Ó ti ṣe ìgbéyàwó, ó sì ti ní àwọn ọmọ méjì. Ọkọ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Mehdi ni ó maá n ṣe àkóso àwọn ohun èlò iná títàn àti gbígbé ohùn jáde níbi àwọn ètò ìfihàn rẹ̀.[9]

Àtòjọ àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2000: Akoko Awọn ọkunrin nipasẹ Moufida Tlatli: Salwa
  • 2001: Fatma nipasẹ Khaled Ghorbal
  • 2010: Dirty Laundry (fiimu kukuru) nipasẹ Malik Amara: Jamila
  • 2016: lofinda orisun omi nipasẹ Férid Boughedir
  • 2017: El Jaida nipasẹ Salma Baccar: Bahja
  • 2019: Porto Farina nipasẹ Ibrahim Letaïef: Monia

Tlifíṣọ̀n

àtúnṣe
  • 1998: Îchqa wa Hkayet nipasẹ Slaheddine Essid: Chrifa
  • 2000: Mnamet Aroussia nipasẹ Slaheddine Essid: Lilia Thabti-Chared
  • 2002: Gamret Sidi Mahrous nipasẹ Slaheddine Essid: Sabiha Souilah
  • 2003: Ikhwa wa Zaman nipasẹ Hamadi Arafa: Souad
  • 2004: Ọpa Slaheddine Essid: Dorra
  • 2005: Aoudat Al Minyar nipasẹ Habib Mselmani: Rakia
  • 2009: Aqfas Bila Touyour (Larubawa) nipasẹ Ezzeddine Harbaoui
  • 2010: Garage Lekrik nipasẹ Ridha Béhi
  • 2012: Dipanini nipasẹ Hatem Bel Hadj
  • 2013: Yawmiyat Imraa nipasẹ Khalida Chibeni: Daliya
  • 2015: Naouret El Hawa (akoko 2) nipasẹ Madih Belaïd: Safia
  • 2016: Nsibti Laaziza (akoko 6) nipasẹ Slaheddine Essid ati Younes Ferhi: Rafika
  • 2016: Aare Jamil Najjar
  • 2016: Bolice 2.0 nipasẹ Majdi Smiri
  • 2017: Dawama nipasẹ Naim Ben Rhouma : Zayneb Kadri
  • 2017: Olusọ irun (Larubawa) nipasẹ Zied Litayem
  • 2017: Flashback (akoko 2) nipasẹ Mourad Ben Cheikh
  • 2019: El Maestro nipasẹ Lassaad Oueslati
  • 2019: Ali Chouerreb (akoko 2) nipasẹ Madih Belaïd ati Rabii Tekali: Ms. Abid
  • 2020: Seamstress nipasẹ Zied Litayem
  • 2021 -2022: Harga (Larubawa) nipasẹ Lassaad Oueslati: Naâma

Ifiweranṣẹ

àtúnṣe
  • 2009-2013: Tunis 2050 nipasẹ Sami Faour: Aziza (ohùn)
  • 2007: Awọn ọrọ kikoro, ọrọ nipasẹ Dhafer Néji ati itọsọna nipasẹ Chedly Arfaoui
  • 2008: Madame Kenza, ọrọ ati itọsọna nipasẹ Moncef Dhouib
  • 2013: Ifcha, mon amour, ọrọ ati itọsọna nipasẹ Chedly Arfaoui ati Wajiha Jendoubi
  • 2019: Big Bossa, ọrọ ati itọsọna nipasẹ Wajiha Jendoubi

Awọn iyatọ

àtúnṣe
  • Oṣiṣẹ ti aṣẹ ti Orilẹ-ede Tunisia.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Wajiha Jendoubi". Elcinema.org (in Arabic). Retrieved 14 November 2020. 
  2. "Wajiha Jendoubi. Le triomphe de l'authenticité". Tunivisions.net (in French). Archived from the original on 7 December 2017. Retrieved 14 November 2020. 
  3. "Wajiha Jendoubi". Elcinema.org (in Arabic). Retrieved 14 November 2020. 
  4. "Wajiha Jendoubi. Le triomphe de l'authenticité". Tunivisions.net (in French). Archived from the original on 7 December 2017. Retrieved 14 November 2020. 
  5. "Myriam Belkadi, Emna Louzyr Ayari, Wajiha Jendoubi : ambassadrices pour la CEDAW". Femmesdetunisie.com (in Èdè Faransé). 14 August 2015. Archived from the original on 7 December 2017. Retrieved 14 November 2020. 
  6. Marzouk, Hamza (14 November 2017). "El Jaïda : zoom sur la réclusion au féminin". Leconomistemaghrebin.com (in French). Retrieved 14 November 2020. 
  7. "Célébration de la fête de la femme : Ennaceur propose un nouveau contrat social pour "protéger la dignité, les droits et la liberté de la femme"". Leaders.com.tn (in French). 13 August 2019. Retrieved 14 August 2019. 
  8. "Wajiha Jendoubi accuse : «Attessia TV ne m'a pas payée mes droits!»". Kapitalis.com. 17 December 2019. Retrieved 14 November 2020. 
  9. "Wajiha Jendoubi: ‘Theatre is my weapon’". Al Jazeera. 13 November 2017. https://www.aljazeera.com/program/episode/2017/11/13/wajiha-jendoubi-theatre-is-my-weapon/. Retrieved 14 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe