Wande Abimbola
Wándé Abímbọ́lá (ọjọ́ ìbí Oṣù Kẹfà 26, 1932 ní. ìlú Ọ̀yọ́, Nigeria) ó jẹ́ olùkọ́ lítírésọ̀ ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Èdè àti Lítírésọ̀ Aáfíríkà ní Yunifasiti Obafemi Awolowo ní Ile-Ife, Nigeria.[1] Ó jẹ́ olórí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ yìí fún ọjọ́ pípé kí ó tó wá di 'Dean Faculty of Arts' ní ilé-ẹ̀kọ́ kan náà. Ìgbà tí ó ṣe ni ó di olórí oko fún Obafemi Awolowo University OAU. Sáà méjì ni ó fi je olórí oko yìí. Lẹ́yìn ìgbà tí ó fi ipò olórí oko yìí sílẹ̀ ni ó fẹ̀yìn tì. Ó se ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lórí èdè Yorùbá ní pàtàkì jùlọ lórí Ifá.[2][3]
Chief Ògúnwán̄dé Abím̄bọ́lá | |
---|---|
Ọjọ́ ìbí | 24 Oṣù Kejìlá 1932 ọ̀yọ́, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | olórí ẹsìn, ònímọ̀-àgbà fásitì, ati olóṣèlú |
Alma mater | University of Ibadan |
Ìkẹ́kọ̀ọ̀ rẹ́
àtúnṣeNí ọdún 1963, Abimbola kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ nípa ìtàn ní University College, Ibadan. [4] Ní ọdún 1971, ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Masters ní Northwestern University, Evanston, Illinois. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Doctorate nípa ìtàn àròsọ láti University of Lagos ní ọdún 1966.[5] Abímbólá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè PhD àkọ́kọ́ ní University of Lagos. [6] Ó di ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) ni3 1976.[7]
Abimbola kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Fáṣítì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, awon náà ní; University of Ibadan láàrin ọdún 1963 sí 1965, University of Lagos láàrin 1966 sí 1972, University of Ifè láàrin ọdún 1972 sí 1991. Ó ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn fásitì àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn bí Indiana University, Amherst College, Harvard University, [8] Boston University, Colgate University, University of Louisville.
Abimbola ti kọ àwọn ìwé lórí Ifá àti àsà Yórùbá. Ní ọdún 1977, NOK Publishers tẹ ìwé tí Abímbólá kọ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ifá Divination Poetry.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Abimbda, Wande; Abimbola, Wande. "Wande Abimbola". AfroCubaWeb. Retrieved 2019-05-28.
- ↑ "Ifa, wandeabimbola.com Home". Ifa, wandeabimbola.com Home. 2011-10-28. Retrieved 2019-05-28.
- ↑ Published (2015-12-15). "I was ridiculed for returning home a poor senator –Prof. Wande Abimbola". Punch Newspapers. Retrieved 2019-05-28.
- ↑ "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-09-29.
- ↑ "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-23.
- ↑ "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-23.
- ↑ "Wande Abimbola celebrates His Birthday". Oduduwa Watch. Archived from the original on 2021-01-20. Retrieved 2021-01-23.
- ↑ "Wande Abimbola". www.afrocubaweb.com. Retrieved 3 May 2019.