Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 44 ọdún 2011
Jamáíkà (pípè /dʒəˈmeɪkə/) je orile-ede erekusu ni Antilles Gbangba, to je 234 kilometres (145 miles) ni gigun ati bi 80 kilometres (50 miles) ni fife, ti isodipupo won je 11,100 km2. O budo sinu Okun Karibeani, bi 145 kilometres (90 miles) guusu Kuba, ati 190 kilometres (120 miles) iwoorun Hispaniola, erekusu to je ile fun awon orileabinibi-ileijoba Haiti ati Orile-ede Olominira Dominiki. Awon elede Arawak abinibi eya Taino ti won gbe nibe pe oruko erekusu ohun ni Xaymaca, to tumosi "Ile Igi ati Omi", tabi "Ile Isun Omi".
Nigba kan bi ini Spein ti won si pe ibe ni Santiago, ni 1655 o di ibiamusin Ilegeesi, ati leyin eyi o di ti Britani, toruko re n je "Jamaica". Pelu awon eniyan ti won to egbegberun 2.8, o je orile-ede keta eledegeesi to ni awon eniyan pipojulo ni orile àwon Amerika, leyin awon orile-ede Iparapo awon Ipinle ati Kanada. O wa ninu ile Ajoni pelu Queen Elizabeth II bi Olori Orile-ede. Kingston ni ilu titobijulo ati oluilu re.
Awon eya abinibi Arawak ati Taino ti won gbera lati Guusu Amerika budo sori erekusu na larin odun 4000 ati 1000 kJ. Nigbati Christopher Columbus de be ni 1494 o ba awon abule to ju 200 lo nibe ti won ni awon olori abule nibe. Ebado guusu Jamaika je ibi ti awon eniyan posijulo nigbana, agaga layika agbegbe ti a mo loni bi Old Harbour. Awon Tainos si je onibugbe Jamaika nigbati awon Geesi gba idari ibe. Jamaican National Heritage Trust nsise lati wari, ki won o si sakosile eri yiowu toba le wa nipa awon Taino/Arawak. Christopher Columbus gba Jamaica fun Spein leyin to bale sibe ni 1494. O se e se ko je pe ibi ti Columbus bale si ni Dry Harbour, loni to n je Discovery Bay. Maili kan ni iwoorun St. Ann's Bay ni ibi ibudo akoko awon ara Spein lori erekusu na, Sevilla, ti won pati ni 1554 nitori opo awon olosa ti won ja be. (tẹ̀síwájú...)
Ṣíṣàtúnṣe ojúewé yìí látọwọ́ àwọn oníṣe tuntun tàbí àwọn oníṣe aláìtíìforúkọsílẹ̀ jẹ́ tí tìpa lọ́wọ́lọ́wọ́. See the protection policy and protection log for more details. If you cannot edit this ojúewé and you wish to make a change, you can submit an edit request, discuss changes on the talk page, request unprotection, log in, or create an account. |