Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 4 ọdún 2011
Áfríkà ni orílẹ̀ kejì tótóbijùlọ àti tóní àwọn ènìyàn jùlọ láàgbáyé lẹ́yìn Ásíà. Pẹ̀lú ààlà ilẹ̀ tó tó 30.2 ẹgbẹgbẹ̀rún km² (11.7 ẹgbẹgbẹ̀rún sq mi) lápapọ̀ mọ́ àwọn erékùṣù tó súnmọ́ ibẹ̀, ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ 6% nínú àpapọ̀ gbogbo ojúde Ayé ati 20.4% gbogbo ile Aye. Pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ̀rúnkejì 1 eniyan (ní ọdún 2009, ẹ wo tabili) nínú àwọn agbègbèilẹ̀ 61, èyí ṣàṣirò fún 14.72% gbogbo iye àwọn ènìyàn ní Àgbáyé. Ní àríwá rẹ̀ ni Òkun Mẹditéránì wà, sí àríwáìlàorùn rẹ̀ ni Ìladò Suez àti Òkun Pupa wà nítòsí Sìnáì, sí gúsùìlaòrùn rẹ̀ ni Òkun Índíà, àti sí ìwọ̀ọrùn rẹ̀ ni Òkun Atlántíkì wà. Áfríkà ní àwọn orílẹ̀-èdè 54 lápapò mọ́ Madagáskàr, ọ̀pẹ̀ erékùṣù àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Áràbù Sàhráwì, tó jẹ́ ọmọẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan Áfríkà bótilẹ̀jẹ́pẹ́ Mòrókò lòdì sí èyí.
Áfríkà, àgàgà àringbàngàn apáìlàorùn Áfríkà, jẹ́ gbígbàgbọ́ gidigidi ní àwùjọ sáyẹ́nsì bíi orísun àwọn ọmọnìyàn àti ẹ̀ka ẹ̀dá Àwọn Irúọmọnìyàn (Hominidae) (àwọn Òbọ Únlá), gẹ́gẹ́bí ó ṣe hàn pẹ̀lú ìwárí awon irúọmọnìyàn àtètèjùlọ àti àwọn babaúnlá wọn, àti àwọn tí wọ́n wá lẹ́yìn wọn tí wọn jẹ́ bíi ẹgbẹgbẹ̀rún méje ọdún sẹ́yìn – lápapọ̀mọ́ Sahelanthropus tchadensis, Australopithecus africanus, A. afarensis, Homo erectus, H. habilis and H. ergaster – pẹ̀lú Homo sapiens (eniyan odeoni) àtètèjùlọ tó jẹ́ wíwárí ní Ethiopia tó jẹ́ ọdún bíi 200,000 sẹ́yìn.
Áfríkà fẹ̀ kákiri orí agedeméjì, ó sì ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ojúọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀; òhun ni orílẹ̀ kan soso tó gùn láti ibi alọ́wọ́rọ́ apáàríwá dé ibi aláwọ́rọ́ apágúsù.
Afri ni orúkọ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé ní Àríwá Áfríkà nítòsí Kártágò. Àwọn wọ̀nyí tanmọ́ "afar" èdè àwọn Finísíà, tó túmòsí "eruku", sùgbọ́n àbárò 1981 kan ti sọ pé ó wá láti ọ̀rọ̀ èdè àwọn Berber ifri tabi Ifran tótúmọ̀sí "iho", láti tókasí àwọn tí úngbé inúihò. Áfríkà tàbí Ifri tàbí Afer ni ọrúkọ Banu Ifran láti Àlgéríà àti Tripolitania (ẹ̀yà Berber ti Yafran).
Lábẹ́ ìjọba àwọn ará Rómù, Kártágò di olúìlú Ìgbèríko Áfríkà, tó tún jẹ́ mímúpọ̀mọ́ apá etíomi Líbyà òní. Àlẹ̀mẹ́yìn "-ka" ("ca") àwọn ará Rómù tókasí "orile-ede tabi ile". Ilẹ̀ọba àwọn Musulumi Ifrikiya tó wá lẹ́yìn rẹ̀, Tùnísíà òdeòní, náà tún lo irú orúkọ yìí.
Áfríkà àṣiwájú aláàmúsìn ṣe é ṣe kí ó ní orílẹ̀ìjọba àti ìṣèjọba ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ju 10,000 lọ, tí wọ́n ní oríṣiríṣi irú àgbájọ olóṣèlú àti ìjọba. Nínú àwọn wọ̀nyí ni àdìpọ̀ abáratan kékeré àwọn aṣọdẹ bíi àwọn San ní apágúsù Áfríkà; àwọn àdìpọ̀ dídìmúlẹ̀ bi awon asọèdè Bantu ní àringbàngàn àti apágúsù Áfríkà, àwọn àdìpọ̀ abáratan dídìmúlẹ̀ gidigidi ní Ibi Ìwo Orí Áfríkà, àwọn ileoba Ṣàhẹ́lì gbàngbà, àti àwọn ìlú-orílẹ̀-èdè aládàáwà àti àwọn ilẹ̀ọba bíi ti àwọn Yorùbá ní Ìwọ̀orùn Áfríkà, àti àwọn ìlú ọjà etíomi àwọn Swahili ní Ilaorun Afrika. (ìyókù...)