Wikipedia:Ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́

(Àtúnjúwe láti Wikipedia:Ilana)
Ojúewé yìí ní ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ kan Wikipedia nínú. Ó jẹ́ èso ìfohùnṣọ̀kan, bẹ́ ẹ̀ sì ni ó jẹ́ gbígbàgbọ́ pé gbogbo àwọn oníṣe gbọ́dọ̀ tẹ̀lé wọn gbámúgbámú. Ẹ le ṣàtúnṣe àkóónú ojúewé náà sùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ọ mọ́ ṣe ìyípadà ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ kankan láì kọ́kọ́ filọ àwọn oníṣe yìókù.
Àkékúrús:
WP:Ìmúlò
WP:Ìtọ́nisọ́nà
WP:ÌÌ

Ojú ewé yìí ní kúkurú: Ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà Wikipédíà jẹ́ Ojú ewé tó tọ́ka sí ìlànà tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ní àwùjọ Wikipédíà. Ìmúlò yìí ṣe àpèjúwe bí a ṣe lè máa mú ìdàgbàsókè bá àwọn Ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà Wikipédíà.

Àwùjọ Wikipédíà ṣe Ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà yìí lati ṣe àpèjúwe ọ̀nàn tó dára jùlọ lati ṣàgbékalẹ́ ọ̀rọ̀, yanjú ìjà àti lati mú ìtẹ̀síwájú bá ìlépa wa fún ṣiṣẹda ìmọ ọfẹ. Kò pọn dandan lati ka Ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà ojú ewé yìí lati bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ṣíṣàtúnkọ. Wikipédíà:Orígun máàrún Wikipédíà ṣe àlàyé ránpẹ́ nípa ìlànà Wikipédíà. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé Wikipédíà Kò ní gba lílé ati sáré òfin, àwọn ojú ewé Ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà ti ṣàgbékalẹ́ bí ohun gbogbo ṣe gbọ́dọ̀ máa lọ. Ìmúlò ṣe àlàyé àwọn ìlànà tí alàtúnkọ gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ní àwùjọ Wikipédíà. Bakan náà ni ìtọ́nisọ́nà ṣe àlàyé ọ̀nàn tí a yàn lááyò lati tẹ̀lé ìlànà yìí. A gbọ́dọ̀ máa lo ìtọ́nisọ́nà pẹ̀lú láákáyè.

Ìpinlẹ̀ṣẹ̀

àtúnṣe

Àjọ kòsí fún èrè Wikimedia Foundation ni ó n se alàkóso Wikipédíà pẹ̀lú àwọn òfin kan (wo ibí fún àkójọ Ìmúlò). Tún wo Ipa Jimmy Wales. ṣùgbọn, Wikipédíà ṣàkóso ara ẹ̀ nipase oníwé àwùjọ

Àkékúrú:
WP:Ìmúlò

Ìmúlò jẹ́ ohun tí gbogbo alàtúnkọ gbà. Osì tún se àpèjúwe ìlànà tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ní àwùjọ. Gbogbo ojú ewé ìmúlò wà ní Wikipédíà: Gbogbo ìmúlò àti ìtọ́nisọ́nà àti . Fún kúkurú ojúlówó àwọn ìmúlò, wo Wikipédíà: Àwọn ìmúlò

Wikipedia Yorùbá únlo àwọn ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ tó wà fún Wikipedia èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Tí ẹ bá fẹ́ ẹ lè lọ sí ojúewé ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fọ̀rọ̀wérọ̀ nípa wọn tàbí dámọ̀ràn ìpínu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ míràn