Irinṣẹ́ Ìdápadà ẹ̀tọ́ oníṣẹ́ ni ó ma fún oníṣẹ́ tí ó ní àṣẹ àsíá ní bọ́tìnì (ìdápadà), tí yóò lè ṣe ìdápadà àṣìṣe tàbí ìbàjẹ́ tí ó ti ọwọ́ oníṣẹ́ kan wá ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé ní ọwọ́ kan. Irinṣẹ́ yí wúlò láti ṣàyípadà ìbàjẹ́ ojú-ewé.

Oníṣẹ́ tí ó ní àṣẹ ìdápadà yóò ní bọ́tìnì tí ó ní àwọn irinṣẹ́ mìíràn lójú ìwò oníṣẹ́, lórí ojú-ewé oníṣẹ́ oníṣẹ́ náà àti àti (tiwọn), àti ti ojú-ewéìtàn.

Irinṣẹ́ ìdápadà ni ó wà fún alákòóso àgbà láì sí ìdíwọ́, a sì tún lè fún oníṣẹ́ tí ó bá bèrè fun lábẹ́ ìyọnda alákòóso agbà. Ẹnkẹ́ni tí ó bá ní àsíá yí ni a ń pè ní aláyìípadà. Lọ́wọ́ yí, iye àwọn oníṣẹ́ tí ní àṣẹ yí ni olóòtú àgbà àti5 administrators and 0 (7 total), ó yàtọ̀ sí aláyìípadà gbogbo gbò alákòóso gbogbo gbò tí ó ti ní àṣẹ àti agbára láti ṣe ohun kóhun lórí àwọn pèpéle Wikimedia pátá.

Àwọn àsìkò tí a lè lo irinṣẹ́ ìdápadà oníṣẹ́ tí ó bá ṣi irinṣẹ́ yí lò nípa yí yí àpilẹ̀kọ gidi dà sí àìda (bí àpẹrẹ) tí ó sì hàn lábẹ́ iṣẹ́ wọn yóò pàdánù àṣẹ àti àsíá irinṣẹ́ ìdápadà rẹ̀, fẹ̀kàn tẹ́lẹ̀, olóòtú tàbí alákòóso àgbà nìkan ló ní ẹ̀tọ́ sí irinṣẹ́ náà jùlọ. Olóòtú àgbà lè bèrè kí wọ́n yọ òun nípò kí ó lè pàdánù àṣẹ ìlò irinṣẹ́ náà.

Àwọn òfin àti ààlà ìlò

àtúnṣe
  • Bọ́tìnì ìdápadà yóò hàn ní ẹ̀gbẹ́ àpilẹ̀kọ tí wọ́n bá túnṣe jùlọ.
  • Bí wọ́n bá tún ṣe àtúnṣe sí ojú-ewé àpilẹ̀kọ ṣáájú kí onírinṣẹ́ ìdápadà tó tẹ̀ẹ́, ìgbésẹ̀ náà yóò pòfo, àyà fi tí olùṣàtúnṣe naa bá ṣe tán.
  • O kò lè ṣe àṣàyàn èyíkéyí tí ó bá wù ọ́ láti wù ọ́ láti dá padà. Èyí tún lè fún ọ níṣòro díẹ̀, àfi kí o ṣọ́ra.
  • Bí àtúnṣe àìmọye bá wá wáyé láti ọwọ́ oníṣẹ́ kan náà léra-léra, gbogbo rẹ̀ yóò ṣe é ṣàyípadà lọ́wọ́ kan. Àmọ́, bí o bá fẹ́ ṣàyípadà ìwọ̀nba àṣìṣe díẹ̀ kúrò, o ní láti dá yọ ọ́ kúrò ni.
  • O kò lè lo irinṣẹ́ ìdápadà lórí àyọkà tàbí àpilẹ̀kọ tí oníṣẹ́ kan ṣoṣo ti ṣiṣẹ́, nítorí wípé kò ní sí nkan rẹpẹtẹ láti ṣàyípadà.
  • Ìdápadà yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lórí àyọkà, kò ní sí ìfilọ̀ kankan bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú-ìwé yóò fi àtúnṣe àti ìdápadà tí o ṣẹ́ṣẹ́ ṣe láìpẹ́ hàn ọ́.

Olóòtú àgbà lè fòpin sí àṣẹ ìdápadà tàbí kí ó fagilé oníṣẹ́ tí wọ́n fún ní àṣẹ ilò irinṣẹ́ ìdápadà nígbà tí kò bá lè ṣe alàyé lórí ìdápadà tí ó bá ṣe lórí bí ó ti wulẹ̀ kí ó rí. Ẹ̀wẹ̀, a ní láti fàyè gba oníṣẹ́ tí wọ́n fún ní àṣẹ ilò irinṣẹ́ ìdápadà láti ṣàlàyé kí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ìdí tí ó fi ṣe àyípadà rẹ̀.

Bí a ṣe lè béèrè fún ìlò àṣẹ ìdápadà

àtúnṣe

Láti béèrè fún àṣẹ yí, tọrọ rẹ̀ request rollback rights, ask at Wikipedia:Requests for permissions/níbí tàbí kí o béèrè lọ́wọ́ àwọn olóòtú àgbà níbí. Èyíkéyí Any olóòtú àgbà ni ó lè yọ̀nda tàbí gba àṣẹ náà kúrò lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fún. Ẹ wo ojú-ìwé àwọn ẹ̀tọ́ oníṣẹ́.

Lóòtọ́, kò sí ohun àmúyẹ kánkán tí a ma ń wò kí a tó fún ẹnkẹ́ni tó bèrè fún àṣẹ ìlò irinṣẹ́ ìdápadà ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fẹ́ lo àṣẹ yí ní láti ṣiṣẹ́ jìnà tí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yóò sì ma tọ́ka sí akitiyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní àgbọ́nọ̀gbẹ ìmọ̀ àti ìrírí nípa dídá àti ìlè ṣe ìyàtọ̀ láàrín àṣìṣe àti ìbàjẹ́ tí oníṣẹ́ kan bá ṣe sí ijú-ìwé àyọkà tàbí àpilẹ̀kọ kan. Irinṣẹ́ ìdápadà (rollback) kò sí fún àwọn oníṣẹ́ titun. Láfikún, oníṣẹ́ tí ó bá ma ń fa whálà pẹ́lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà kó ní lẹ́tọ̀ọ́ sí irinṣẹ́ abiyi yí; nítorí kí má ba máa sìílò lọ́nà ìjàmbá.

Ẹ tún wo

àtúnṣe