Àjẹsára Ọ̀fìnkì oríṣi B tí kòkòrò àrùn Haemophilus ń fà

Àjẹsára Ọ̀fìnkì oríṣi B tí kòkòrò àrùn Haemophilus ń fà jẹ́ àjẹsára tí ń lò láti dènà àkóràn Ọ̀fìnkì oríṣi B tí kòkòrò àrùn Haemophilus ń fa (Hib).[1] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti kàá kún ara àjẹsára tí à ń lò lóòrèkóòrè, iye àkóràn àrùn Hib tó ní ipá ti dín kù pẹ̀lú ìwọ̀n tó ju 90% lọ. Èyí sì ti mú kí àwọn àrùn bíi dídáranjẹ̀ awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bo ọpọlọ àti ọ̀pá-ẹ̀yìn (meningitis), dídáranjẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró (pneumonia), àti dídáranjẹ̀ bèlú-bèlú (epiglottitis) dín kù lọ́pọ̀lọpọ̀.[1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn fọwọ́sí ìmúlò rẹ̀.[2][1] Ìwọ̀n egbògi náà méjì tàbí mẹ́ẹ̀ta ni a gbọ́dọ̀ fún ènìyàn kí ó tó pé ọmọ oṣù mẹ́ẹ́fà. Ìwọ̀n egbògi àkọ́kọ́ ni a gba ni nímọ̀ràn láti gbà bí ènìyàn bá ti ń pé ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ́fà, èkejì sì gbọdọ̀ wáyé ní ọ̀sẹ̀ kẹẹ̀rin sí àsìkò yìí. Bí ó bá jẹ́ ìwọ̀n àjẹsára náà méjì péré ni a fún ni, a gba ni nímọ̀ràn láti gba ìwọ̀n àjẹsára náà mìíràn lọ́jọ́ iwájú. A má a ń gbàá gẹ́gẹ́ bí abẹ́rẹ́ tí a gún sínú ẹran-ara ẹni.[1]

Àtúnbọ̀tán tó ní ipá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Iye àwọn ènìyàn tó tó 20 sí 25% a má a ní ìrora ní ojú ibi abẹ́rẹ́ náà, àwọn bíi 2% a sì má a ní ibà. A kò rí ẹ̀rí tó fihàn kedere pé àjẹsára náà ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìfèsì ara ẹni lọ́nà òdì sí ohun tí ènìyàn kòrira. Àjẹsára Hib wà gẹ́gẹ́ bí èyí tó dádúró, bí èyí tó jẹ́ àdàlù pẹ̀lú àjẹsára ikọ́ gbẹ̀fun-gbẹ̀fun/àwàlù eyín/ikọ́ọfe, àti bí èyí tó jẹ́ àdàlù pẹ̀lú àjẹsára Ibà jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ oríṣi B, láàárín àwọn oríṣiríṣi mìíràn. Gbogbo àwọn àjẹsára Hib tí à ń lò báyìí jẹ́ àjẹsára aláàsopọ̀.[1]

Àjẹsára Hib àkọ́kọ́ ni a ṣe jáde ní ọdún 1977, èyí tí a rọ́pò pẹ̀lú àgbéjáde mìíràn tí nṣiṣẹ́ dáradára jùú lọ ní àwọn ọdún 1990. Ní ọdún 2013, orílẹ̀-èdè 184 ni wọ́n fi sí ara àwọn àjẹsára òòrèkóòrè wọn.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[3] Iye owó rẹ̀ lójú pálí fún àjẹsára tó ní ojú ibi àsopọ̀ máàrún, ọ̀kan lára èyítí ó jẹ́ Hib, jẹ́ 15.40 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[4] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ bíi 25 sí 50 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Haemophilus influenzae type b (Hib) Vaccination Position Paper – July 2013."
  2. "Haemophilus b conjugate vaccines for prevention of Haemophilus influenzae type b disease among infants and children two months of age and older.
  3. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  4. "Vaccine, Pentavalent" Archived 2020-01-25 at the Wayback Machine..
  5. Hamilton, Richart (2015).