Olóyè Wuraola Adepeju Esan (tí a bí ní ọdún1909, tí ó sì kú ní ọdún1985) fìgbà kan jẹ́ olùkọ́ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ajàfẹ́tọ̀ọ́mọbìrin, àti olóṣèlú. Ó pa iṣẹ́ ìṣèlú rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn adarí ìlú gẹ́gẹ́ bíi Iyalode ìlú Ibadan.[1]

Chief
Wuraola Esan
Fáìlì:Wuraola Esan.jpg
Ọjọ́ìbí1909
Calabar
Aláìsí1985
Orílẹ̀-èdèNigeria
Iṣẹ́Educator, politician
Gbajúmọ̀ fúnNational Council of Women Societies
TitleIyalode of Ibadan
Olólùfẹ́Victor Esan
Parent(s)Thomas Ade-Ojo

Ìtàn ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Wuraola Adepeju Esan ní ọdún 1909 ní ìlú Calabar.[2] Àwọn òbí rẹ̀ ò gbé ní ilẹ̀ Yoruba títí tí wọ́ fi dàgbà àmọ́, wọ́n mú ìtẹ̀síwájú bá àṣà Yoruba. Ilé-ìwé Baptist Girls College ní Abeokuta ni Esan ti kàwé alákọ̀ọ́bèrẹ̀, kí ó tó wá lọ sí United Mission ary College láti lọ gboyè níní iṣẹ́ olùkọ́ni. Láti ọdún 1930 títí wọ 1934, ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ń kọ́ àwọn ọmọ ní Missionary training school kan ni,́ Akure. Ní ọdún 1934, ó fẹ́ Victor Esan, wọ́n sì gbé ní ìpílẹ̀ Èkó fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, wọ́n kón padà lọ sí Ibadan.[3]

Iṣẹ́ òṣèlú rẹ̀

àtúnṣe

Bí ó tilè jé pé ètò-ẹ̀kọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún àwọn obìrin láyé ọjọ́un, ó tiraka láti dá ilé-ìwé Ibadan People's Girls Grammar School kalẹ̀ ní ọdún 1944 ní Mọ̀leté.[4] Èyí wà láti kọ àwọn obìrin ní ẹ̀kọ́ lóríṣiríṣi.[5]

Ní ọdún 1950, ó darapọ̀ mọ́ òsèlú, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìrin tó wà ní action group.Nígbà náà lọ́hùn-ún, bí ó tilè jé pé àwọn obìnrin ní ipa ribiribi tí wọ́n ń kó nínú ìsèlú, àmọ́ wọn ò kìí fún wọn ní àǹfààní láti darí ìlú tàbí láti pàsẹ. Àmọ́ ṣáá, arábìnrin Esan tiraka láti gòkè nínú ìṣèlú, ó sì jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Nigerian National Assembly, wọ́n sì yàn án láti jẹ́ Sénétọ̀ ti apá ìwọ̀-oòrùn ti ìlú Ibadan. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ egbẹh National Council of Women Societies. Ní ọdún 1975, ó joyè Iyalode, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ipò tó ga jù lọ ní Ibadan.[6]

Àwọn ìtọkasí

àtúnṣe
  1. Roberta Ann Dunbar. Reviewed Work(s): "People and Empires in African History: Essays in Memory of Michael Crowder" by J. F. Ade Ajayi; J. D. Y. Peel; Michael Crowder, The Journal of African History, Vol. 34, No. 3, 1993.
  2. Professor Henry Louis Gates Jr.; Professor Emmanuel Akyeampong; Mr. Steven J. Niven (2 February 2012). Dictionary of African Biography. OUP USA. pp. 311–. ISBN 978-0-19-538207-5. https://books.google.com/books?id=39JMAgAAQBAJ&pg=PA301. 
  3. Kathleen E. Sheldon. Historical Dictionary of Women In Sub-Saharan Africa, Scarecrow Press, 2005, p 74. ISBN 0-8108-5331-0
  4. Cheryl Johnson-Odim. For Women and the Nation: Funmilayo Ransome-Kuti of Nigeria, University of Illinois Press, 1997, p 48. ISBN 0-252-06613-8
  5. Karen Tranberg Hansen. African Encounters with Domesticity, Rutgers University Press, 1992, p 133.
  6. Roberta Ann Dunbar. Reviewed Work(s): "People and Empires in African History: Essays in Memory of Michael Crowder" by J. F. Ade Ajayi; J. D. Y. Peel; Michael Crowder, The Journal of African History, Vol. 34, No. 3, 1993.