Xolile Tshabalala (tí wọ́n bí ní 9 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1977) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà[1] Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ipa rẹ̀ nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù bíi 4Play: Sex Tips for Girls, Secrets & Scandals, Blood & Water àti Housekeepers.[2][3]

Xolile Tshabalala
Ọjọ́ìbíXolile Tshabalala
Oṣù Kẹrin 9, 1977 (1977-04-09) (ọmọ ọdún 46)
Vrede, Free State
Orílẹ̀-èdèSouth African
Iléẹ̀kọ́ gígaNational School Of The Arts Theatre
New York Film Academy
Iṣẹ́Director, producer, writer, editor
Ìgbà iṣẹ́2002–present

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Xolile ní ọdún 1977 ní ìlú Vrede, èyí tí ó wà ní ìgbèríko Free State, orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà.[4] Wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ láti fi jọ ti ìya bàbá rẹ̀. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga National School Of The Arts Theatre, òun sì ni akẹ́kọ̀ọ́ tó peregedé jùlọ láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.[5]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀ àtúnṣe

Ní àkókò ìgbà tí Xolile wà ní ilé-ẹ̀kọ́ National School Of The Arts Theatre, ó ní ànfààní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Thembi Mtshali-Jones, ẹnití ó padà dà gẹ́gẹ́ bi alámọ̀ràn rẹ̀. Àwọn méjéèjì dìjọ kópa nínu eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Crucible. Xolile tún ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù tó fi mọ́ eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Soul City, níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi Zama. Ó tún ti kópa nínu eré "Another Child." [6][7]

Ọdún 2002 ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Generations. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi 'Julia Montene' nínu eré náà láti ọdún 2002 sí 2005. Eré náà gbajúmọ̀ gidigan láàrin àwọn ará ìlú.[8] Ní ọdún 2007, ó darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa ti eré NCIS nígbà tí eré náà dé apá kaàrún tó síì kópa gẹ́gẹ́ bi 'Sayda Zuri'. Lára àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù míràn tí ó tún ti ṣe ni Secret in my Bosom, Scoop Schoombie, Justice for All, Isidingo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.[9][10]

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n ti yàán fún àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi àwọn ayẹyẹ ẹ̀yẹ, pàápàá jùlọ àwọn ayẹyẹ ẹ̀yẹ tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà. Ní ọdún 2006, wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Golden Horn Awards fún ipa rẹ̀ nínu eré Generations. Ní ọdún 2012, wọ́n tún yàán fún àmì-ẹ̀yẹ kan náà níbi ayẹyẹ Golden Horn Awards bákan náà fún ipa rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Fallen.[11]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ àtúnṣe

Ọdún Àkọ́lé Ipa Irúfẹ̀ Ìtọ́kasí
2002 Generations Julia Montene TV series
2005 Rift Video short
2007 NCIS Sayda Zuri TV series
2007 90 Plein Street Precious TV series
2007 Jacob's Cross Busi TV series
2007 Rhythm City Stella TV series
2008 Hard Copy Teacher TV series
2008 Sokhulu & Partners Nosipho Nokwe TV series
2010 4Play: Sex Tips for Girls Noma TV series
2010 Intersexions Doctor TV series
2011 Fallen Mandi Mbalula TV series
2011 Muvhango Senamile TV series
2013 High Roller Gugu Mogale TV series
2014 Kota Life Crisis Hlengiwe TV series
2014 Soul City Sister Zama TV series
2015 Rise Fezeka Dlamini TV series
2017 Miraculous Weapons Lesedi, producer Film
2017 Secrets & Scandals Felicia Okpara TV series
2018 Ingozi Angela Ndamase TV series
2020 Blood & Water Nwabisa Bhele TV series
2020 Housekeepers Noluthando Ngubane TV series

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "A Mother's Touch". magzter. Retrieved 17 October 2020. 
  2. "Xolile Tshabalala biography". briefly. Retrieved 17 October 2020. 
  3. "The interesting & personal facts about Xolile Tshabalala we didn't know". zalebs. Archived from the original on 19 October 2020. Retrieved 17 October 2020. 
  4. "Xolile Tshabalala news". Vantu News. Archived from the original on 18 October 2020. Retrieved 17 October 2020. 
  5. "Xolile Tshabalala biography". briefly. Retrieved 17 October 2020. 
  6. "Xolile Tshabalala biography". briefly. Retrieved 17 October 2020. 
  7. "Xolile Tshabalala career". tvsa. Retrieved 17 October 2020. 
  8. "Xolile Tshabalala news". Vantu News. Archived from the original on 18 October 2020. Retrieved 17 October 2020. 
  9. "Xolile Tshabalala biography". briefly. Retrieved 17 October 2020. 
  10. "Xolile Tshabalala career". tvsa. Retrieved 17 October 2020. 
  11. "Xolile Tshabalala biography". briefly. Retrieved 17 October 2020.