Ìpínlẹ̀ Yobe

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà
(Àtúnjúwe láti Yobe State)
Yobe State
State nickname: the young shall grow
Location
Location of Yobe State in Nigeria
Statistics
Governor
(List)
Ibrahim Geidam (APC)
Date Created 27 August 1991
Capital Damaturu
Largest City Damaturu
Area 45,502 km²
Ranked 6th
Population
1991 Census
2005 estimate
Ranked 32nd
1,411,481
2,532,395
GDP (PPP)
 -Total
 -Per Capita
2007 (estimate)
$2.01 billion[1]
$843[1]
Official Language English
ISO 3166-2 NG-YO

Ìpínlẹ̀ Yòbè je okan ninu awon Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ni orile-ede Naijiria. Ìpínlẹ̀ Yóbè jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Borno.

Ìpínlẹ̀ Yóbè jẹ́ ipínlẹ̀ awọn nnkan ọ̀ọ̀gbìn. Ọjó kẹ́tadinloogbọn osù kèjọ Ọdún 1991 ni wón dá sílẹ̀. Ara ìpìnlẹ̀ Bòrnó ni wọ́n ti yọ Ìpínlẹ̀ Yóbè. Damaturu jẹ́ olulu Ìpínlẹ̀ Yóbè.

Ìrísí Ìpínlẹ̀ náà

àtúnṣe

Àwọn Ìpínlẹ̀ tí Yóbè múlé tìí ni Bauchi, Borno, Gombe, ati Jigawa. Ìpínlẹ̀ Yóbè wa ni gbòngbò àríwá Diffa ati agbègbè Zinder ti olulu Niger.

Ítàn Ìdásílẹ̀

àtúnṣe

Ìpínlẹ̀ Yóbè jẹ́ dídásílẹ̀ ní Ọjó kẹ́tadinloogbọn, osù kèjọ, Ọdún 1991 nígbà ìsèjọba Babangida. Ìpínlẹ̀ Yóbè jẹ́ dídásílẹ̀ nitoripe ìpínlẹ̀ Borno ìgbánnà tóbi jù láti bójútó, tí ó sí mú kí wọ́n yọ ìpìnlẹ̀ Yóbè lára rẹ̀.

Ijọba Ìbílẹ̀

àtúnṣe

Awọn ijọba íbílẹ̀ tí ó wà nì ìpínlẹ̀ Yóbè jẹ́ mẹ́tàdìnlógún. Awọn ná ní:

  • Bade
  • Bursari
  • Damaturu
  • Geidam
  • Gujba
  • Gulani
  • Fika
  • Fune
  • Jakusko
  • Karasuwa
  • Machina
  • Nangere
  • Nguru
  • Potiskum
  • Tarmuwa
  • Yunusari
  • Yusufari

Ẹ̀yà

àtúnṣe

Ìpínlẹ̀ Yóbè kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà tí Fúlàní ati Kanuri jẹ́ gbòngbò. Awọn ẹ̀yà míràn ni ẹkùn náà ni Bolewa, Ngizim, Bade, Hausa, Ngamo, Shuwa, Bura, Marghi, karai-karai and Manga.

Awọn èdè

àtúnṣe

Awọn orísìrísí èdè tí ó wà ní ìpínlè Yóbè nítítò Ijọba ìbílẹ̀:[2]

LGA èdè
Bade Bade, Duwai, Kanuri
Bursari Kanuri, Fulani
Damaturu Yerwa Kanuri
Fika Karai-Karai, Bolewa, Ngamo
Fune Karai-Karai, Ngizim, Bura-Pabir
Geidam Kanuri, Karai-Karai, Fulani
Gujba Kanuri, Karai-Karai
Gulani Maaka, Karai-Karai, Bura-Pabir, Kanuri
Jakusko Bade, Karai-Karai
Machina Manga
Nangere Karai-Karai
Nguru Kanuri
Potiskum Karai-Karai, Ngizim, Bolewa

Awọn èdè ìpínlè Yóbè míràn ni Duwai, Shuwa Arabs, ati Zarma.[2]

Ilé ẹ̀kọ́ gíga

àtúnṣe
  • Federal College of Education (Technical), Potiskum
  • The Federal Polytechnic Damaturu
  • Federal University, Gashua
  • Mai-Idris Alooma Polytechnic
  • Shehu Sule College of Nursing and Midwifery, Damaturu
  • Umar Suleiman College of Education
  • Yobe State University

Àwọn èèyàn jànkànjànkàn

àtúnṣe
  • Uwani Musa Abba Aji - CFR (tí wọ́n bi ni ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdún 1956) jẹ́ ámòfin orile-ede Nàìjíríà is atí adájọ́ Supreme Court ti orile-èdè Nàìjíríà
  • Usman Albishir - (15 June 1945 – 2 July 2012) Ṣẹ́nitọ́ teleri
  • Mamman Bello Ali - (1958 – 26 January 2009) sẹ́nitọ̀ ati gómínà àna tí Ìpínlẹ̀ Yobe.
  • Ibrahim Mohammed Bomai - (10 February 1960) olóṣèlú ati sẹ́nítọ̀.
  • Imrana Alhaji Buba - ( 6 August 1992) Ajafeto-omoniyan.
  • Mai Mala Buni - ( 11 November 1967) olóṣèlú ati gómìnà ìpínlè Yobe.
  • Goni Modu Bura - igbákejì gómìnà ana, sẹ́nítọ̀, atí asójú fún orile-èdè Nàìjíríà si orile-èdè Syria ati Lebanon
  • Adamu Ciroma - (20 November 1934) mínísítà teleri ati gómìnà àná ti ifowopamọ gbogbogo orile-èdè Nàìjíríà.
  • Ibrahim Gaidam - gómìnà àná ati sẹ́nitọ̀ fun Yobe Zone A
  • Buba Galadima - olóṣèlú ati akòwé fun the Congress for Progressive Change(CPC) party
  • Bukar Ibrahim - ( October 1950) gómìnà ìpínlè Yobe teleri ati sẹ́nítọ̀ ti orile-èdè Nàìjíríà.
  • Alwali Kazir - olórí àná fun àwọn ọmọ ológun
  • Ahmed Lawan -sẹ́nitọ̀
  • Adamu Garba Talba - olóṣèlú ati sẹ́nítọ̀ àná ti Yobe south
  • Ibrahim Talba - akòwé ànási ọfisi ti arẹ orile-èdè Nàìjíríà.
  • Adamu Waziri - ( 14 September 1952)