Yoruba name
Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń lò jákè-jádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Yorùbá tí ó fi mọ́ ìlú bíi Ìbíní,Tógò àti àwọn ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ní orílẹ̀-èdèNàìjíríà àti àgbáyé pátá. Nípaṣe ìṣe àti àṣà Yorùbá, wọ́n ma ń fún ọmọ wọn lórúkọ níbi ayẹyẹ tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ lẹ́yìn ìbímọ.[1] Sísọ orúkọ àwọn ọmọ jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ifá dídá tí Babaláwo bá dá. Ṣùgbọ́n ní ayé òde-òní, orúkọ ọmọ tún lè wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó bá ní ipò tóga nínú ẹbí àwọn òbí méjéèjì tàbí ẹni tí ó súnmọ́ wọn gbágbá. Ìyá àti bàbá tó bímọ, pẹ̀lú àwọn alásùn-ún-mọ́ wọn lè fún ọmọ tàbí àwọn ọmọ ní orúkọ tóbá wù wọ́n. Nínú ìgbàgbọ́ Yorùbá ni kí wọ́n dífá orúkọ ọmọ lọ́dọ̀ Babaláwo ṣáájú ìsọmọlórúkọ, èyí ń ṣe àfihàn àṣà dídífá àkọsẹ̀jayé ọmọ láti mọ irúfẹ́ ohun tí ó bá kádàráa rẹ̀ mu. Irúfẹ́ Oúnjẹ tí ó yẹ kí ó ma jẹ, irúfẹ́ aṣọ tí ó yà kí ó ma wọ̀, irúfẹ́ iṣẹ́ tí yóò ṣe láyé àti irúfẹ́ ìyàwó tàbí ọkọ tí ó bá akọsẹ̀jayé rẹ̀ mu, àti èèwọ̀ ayé rẹ̀.
Ìwúlò orúkọ
àtúnṣeorúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá sábà máa ń kíyèsí tí wọ́n sì ma ń wo ṣàkun ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ irúfẹ́ orúkọ bẹ́ẹ̀; ṣáájú kí wọ́n tó fi má a pe ọmọ tuntun. Àwọn ẹ̀yà Yorùbá gbà wípé orúkọ ẹni a máa roni, ìdí nìyí tí wọ́n ma ń pàṣamọ̀ wípé orúkọ ẹni nì'jánu ẹni. Bákan náà ni wọ́n ma ń kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan kí wọ́n tó sọ orúkọ ọmọ, ìdí nìyí tí wọ́n tún fi ma ń sọ wípé ilé làáwò, k'átó sọ'mọ lórúkọ. Ẹ̀yà Yorùbá ma ń sọ'mọ wọn lórúkọ tó dára tó sì ma ń buyì kún àṣà, ìṣe, àti ẹwà èdè Yorùbá.
Ìpín sí ìsọ̀rí orúkọ Yorùbá
àtúnṣeOrúkọ àyànmọ́
àtúnṣeÈyí ni a tún mọ̀ sí orúko àmútọ̀runwá tàbí orúkọ àyànmọ,(orúkọ tí a gbà wípé ọmọ gbé wá láti òde ọ̀run làti ọ̀run). Àpẹẹrẹ ni Àìná, Ìgè, Òjò, Yéwándé, Abọ́ṣẹ̀dé, Táíwò, Kẹ́hìndé, Ìdòwú, Àlàbá, Babátúndé, Ájàyí, Abíọ́nà, Dàda, Ìdògbé, Yéwándé àti bbl
ORÚKỌ ÀBÍSỌ
àtúnṣeÈyí ni orúkọ tí a fún ọmọ ní ọjọ́ tí ań ṣàjọyọ̀ ìbí rẹ̀,yálà látẹnu àwọn òbí rẹ̀. Èyí sábà má ń jẹ mọ́ ipò tí ẹbí tábí àwọn òbí ọmọ náà wà ní àwùjọ. Díẹ̀ lára orúkọ àbísọ ni: Ọmọtáyọ̀, Ìbílọlá, Adéyínká, Ọláwùmí, Ọládọ̀tun, Ìbídàpọ̀, Ọládàpọ̀, Ọlárìndé, Adérónkẹ́, Ajíbọ́lá, Ìbíyẹmí, Morẹ́nikẹ́, Mojísọ́lá, Fọláwiyọ́, Ayọ̀délé, Àríyọ̀, Oyèlẹ́yẹ, Ọmọ́táyọ̀, Fadérera. [2]
ORÚKỌ ORÍKÌ
àtúnṣeÀwọn orúkọ yìí ni: Àyìnlá, Àjíkẹ́, Àlàó, Àdìó, Àkànmí, Àmọ̀ó, Àríkẹ́, Àgbékẹ́, Àjìún, Àlàkẹ̀, Àwẹ̀ró, Àbẹ̀bí, Àrẹ̀mú, Àlàní, Àyìnké.
ORÚKỌ ÀBÍKÚ
àtúnṣeÈyí ń ṣàfihàn ìmọ̀sílára àwọn Yorùbá àti ìgbàgvọ́ eọn nípa ẹ̀mí àìrì,ikú àti àkúdàáyà. Àpẹẹrẹ orúkọ àbíkú ni: Málọmọ́, Kòsọ́kọ́, Dúrósinmí, Ikúkọ̀yí, Bíòbákú, Kòkúmọ́, Ikúdàísí, Ìgbẹ́kọ̀yí, Àńdùú, Kásìmáawòó, Ọmọ́túndé, Dúrójayé, Kalẹ̀jayé.
ORÚKÓ ÌNAGIJẸ
àtúnṣeOrúkọ ìnagijẹ ni orúkó tí wọ́n ma ń fúni látàrí ìhùwà sí,ìrísí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ ni Eyínfúnjowó, Eyínafẹ́, Ajíláran, Ajíṣafẹ́, Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, Arikúyẹrí, Agbọ́tikúyọ̀, Awẹ́lẹ́wà, ìbàdí àrán àti bbl. éjì nínú orúkọ àmútọ̀run wá Yorùbá tó gbajúmọ̀ jù ni Táíwò (tàbí Táyé) àti Kẹ́hìndé tí wọ́n fún àwọn ìbejì ní pàtàkì. Ó jẹ́ ìgbàgbọ́ pé àkọ́kọ́ nínú ìbejì ni Táíwò(tàbí Táyé)tí ó gbèrò láti kọ́kọ́ jáde wá sáyé láti finmú fínlẹ̀ bóyá agbègbè ibi tí wọ́n fẹ́ wọ̀ dára tàbí kò dára láti wà sínú ẹ̀.Tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn á tẹ́wọ́ gba ìkejí rẹ̀ Kẹ́hìndé (nígbà mííràn á dá kẹ́hìndé padà)kó ní kó má a bọ̀. Òmíràn pẹ̀lú ẹ̀sìn àbáláyé àpẹẹrẹ ni : Ifáṣọlá-Ifá ṣe àṣeyọrí. ó ṣeéṣe fífún ọmọ tí wọ́n máa kọ́ gẹ́gẹ́ bí i babaláwo àti iṣẹ́ ifá máa jẹ́ kí ó dọlọ́rọ̀ àti aláṣeyọrí. Àwọn obí onígbàgbọ́ ìgbàlódé fún ìṣe kí wọ́n máa lo orúkọ àbáláyé fún pípáàrọ̀ orúkọ òrìsà fún OLÚ tàbí OLúWA,ìtumọ̀ olúwa tàbí olúwa mi tí ó ń tọ́ka sí èròǹgbà onígbàgbọ́ nípa ỌLỌ́RUN àti Jésù kírísítì.Fún àpẹẹrẹ Olúwatiṣé-olúwa ti ṣé,àwọn òbí gbàdúrà fún ọmọ olúwa náà sì fún wọn níkan. Àwọn òbí mùsùlùmí máa ń fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn ní orúkọ Lárúbáwá nígbàmííràn pẹ̀lú pípè Yorùbá,Ràfíáh di Ràfíátù. Orúkọ ipaṣẹ̀ tún lè ṣàkàwé ipò tí ìdílé náà wà láwùjọ(àpẹẹrẹ "Adéwálé" orúkọ ìdílé ọba àtàtà)Ó tún lè ṣàkàwé iṣẹ́ abínibí ìdílé kan(àpẹẹrẹ"àgbẹ̀dẹ",àwọn Alágbẹ̀dẹ). Yorùbá tún ní oríkì irú èyí tí àwọn akọ́ríkì máa ń lò láti tẹpẹlẹ mọ́ Àṣeyọrí aṣáájú ti oríṣìíríṣìí ìdílé.Oríkì tún lè jẹ́ ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ bì i "Àdúnní"tàbí kí ó jẹ́ ẹṣẹ̀ ìwé tàbí jáǹtìrẹrẹ.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kì í ṣe ipa àtàtà ni ó ń kó nínú orúkọ gidi,oríkì máa ń sáábà jẹ́ lílò ní ẹ̀gbẹ́ kan ,ó máa ń sáábà jẹ́ ohun tí gbogbogbò mọ̀ mọ̀ọ̀yàn ní àkókò kan.Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ni àwọn ará ìlú mìíràn lè dámọ̀ kódà ìdílé wọn nípa lílo oríkì okùn ìrandíran won. Iṣẹ́ kékeré ni Yíyan orúkọ níṣẹ̀yí nítorí kòsí àkójọpọ̀ orúkọ Yorùbá tó pé. síbẹ̀síbẹ̀ iṣẹ́ àgbéṣe titun Látọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣe gbogbo orúkọ Yorùbá sí kíkọ sílẹ̀ sínú ìwé arídìí ní ti ìlànà onírúurú ọ̀nà ìgbàròyìn.
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Significance of Names and Naming Ceremonies in the Yoruba Culture". Nigerian Center. 2023-07-29. Retrieved 2024-11-28.
- ↑ "YorubaNames". YorubaNames. Retrieved 2024-11-23.