Yvonne Jegede
Yvonne Jegede jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, olùgbéré-jáde, model àti adarí ètò lórí ẹrọ amóhù-máwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Jẹ́gẹ́dẹ́ di ìlú-mòọ́ká látàrí eré kan tí ó gbé jáde tí ó pè ní 3 is Company. Ó di ẹni ayé ń fẹ́ lẹ́yìn tí ó kópa nínú fọ́rán àwo orin African Queen tí gbajú-gbajà olótin 2Face Idibia àti Annie Macaulay gbé jáde.[2]
Yvonne Jegede | |
---|---|
[[file:|frameless|alt=]] | |
Yvonne Jegede | |
Ilẹ̀abínibí | Nàìjíríà |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Yvonne Jẹ́gẹ́dẹ́ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbòn oṣù Kẹ́jọ ọdún 1983 ní agbègbè Agenebode ní Ìpínlẹ̀ Edo, ní orílẹ̀-èdèNàìjíríà . Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama ní Ìpínlẹ̀.Èkó, tí ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nílé ẹ̀kọ́ Yunifásitì Cyprus, nínú ìmọ̀ "International Relations".[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeJegede bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré ní ọdún 2014 nibi tí ó ti kòpa nínú eré Missing Angels. Lẹ́yìn èyí, ó tún fara hàn nínú fọ́nrán àwo orin African Queen tí gbajúmọ̀ olórin 2Face Idibia tí wọ́n tún mọ̀ sí 2Baba gbé jáde ní ọdún 2005. Ó ti kó kópa nínú àwọn eré bíi: Okafor's Law, Single and Married, 10 Days in Sun City àti bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ. Ní ọdún 2015, ó gbé eré tirẹ̀ jáde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní 3 is Company tí ó sì kópa nínú eré náà gẹ́gẹ́ bí olú-èdá ìtàn where she starred as the lead character.[4]Ní ìparí ọdún 2016, ìwé ìròyìn ìgbàfẹ́ ti Genevieve Nnaji[5] Yàtọ̀ sí eré ṣíṣe, Yvonne Jegede ó ti fara hàn nínú fọ́nrán àwo orin "Ego" tí olórin ilẹ̀ Nàìjíríà Djinee àti fọ́nrán àwo orin Kokose tí Sound Sultan gbé jáde.
Àwọn eré tí ó ti kópa
àtúnṣe- Missing Angels
- Husbands of Lagos
- 3 is Company
- Okafor's Law
- Pot of Life
- Gold Statue
- Side Chic Squad
- Single and Married
- 10 Days in Sun City
- The Fight for the Family
- The Silver Spoon
- The Sassy One
- Climax
- Gone to America
- Crazy Ex-Girlfriend
- Forget Me Not
- True Lies
- Smiles of Sweet Love
- Two Hearts That Binds Together
- Strange Affection
- Abike
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Olowolagba, Fikayo (22 June 2018). "Yvonne Jegede challenges Atuma to name prostitutes in Nollywood". Daily Post. http://dailypost.ng/2018/06/22/yvonne-jegede-challenges-atuma-name-prostitutes-nollywood/amp/. Retrieved 16 October 2018.
- ↑ Izuzu, Chidumga (25 August 2016). "5 reasons to love "The First Lady" actress". Pulse Nigeria. Archived from the original on 15 December 2018. https://web.archive.org/web/20181215224712/https://www.pulse.ng/entertainment/movies/yvonne-jegede-5-reasons-to-love-the-first-lady-actress-id5418813.html. Retrieved 16 October 2018.
- ↑ Anonymous (9 April 2017). "My big boobs not my selling point". Punch. https://www.punchng.com/my-big-boobs-not-my-selling-point/amp/. Retrieved 16 October 2018.
- ↑ Izuzu, Chidumga (17 June 2015). "Movie starring Yvonne Jegede, OC Ukeje, Wole Ojo gets DVD release date". Pulse Nigeria. Archived from the original on 16 December 2018. https://web.archive.org/web/20181216031932/https://www.pulse.ng/entertainment/movies/3-is-company-movie-starring-yvonne-jegede-oc-ukeje-wole-ojo-gets-dvd-release-date-id3876238.html. Retrieved 16 October 2018.
- ↑ Peters, Seyi (16 December 2016). "Yvonne Jegede Covers Genevieve Magazine’s Annual Bridal Issue". Information Nigeria. https://www.informationng.com/2016/12/yvonne-jegede-covers-genevieve-magazines-annual-bridal-issue.html/amp. Retrieved 16 October 2018.