Àdéhùn Àbùrí
Wọ́n ṣe Àdéhùn Àbùrí lọ́dún 1967 níbi ìpàdé kan tí ó wáyé láàárín àwọn aṣojú olórí ìṣèjọba ológun ti ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn aṣojú olórí àwọn ènìyàn ní apá ìlà-oòrùn Nàìjíríà tí Ajagun Colonel Odumegwu Ojukwu darí. Wọ́n pe ìpàdé yìí láti wá ọ̀nà àbáyọ ìkẹyìn kí ogun abẹ́lé, Biafra máà bẹ́ sílẹ̀ nígbà náà.[1] Ìpàdé yìí wáyé lọ́jọ́ kẹrin àti karùn-ún oṣù kìíní ọdún 1967.
Ibi ìpàdé Àbúrì
àtúnṣeÀbúrì jẹ́ ìlú kan lápá ìlà oòrùn lórílẹ̀-èdè Ghana, wọ́n yan ìlú yìí fún ìpàdé àlàáfíà náà nítorí àbò olórí àwọn aṣojú ìlà oòrùn Nàìjíríà, Odimegwu Ojukwu, tí ó jẹ́ Gómìnà nibẹ nígbà náà kò dájú láwọn ẹkùn àríwá àti ìwọ oòrùn Nàìjíríà nígbà rògbòdìyàn náà[2]
Àwọn kókó ìpàdé Àbúrí
àtúnṣe- Àtúntò ọmọ-ogun Nàìjíríà
- Òfin Nàìjíríà Arrangement
- Ọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n sá kúrò nílé wọn nítorí rògbòdìyàn ní Nàìjíríà.[3](c)1999-2006 Segun Toyin Dawodu
Àwọn aṣojú
àtúnṣeÀwọn wọ̀nyí ni aṣojú kọ̀ọ̀kan níbi ìpàdé Àbúrí:
- Alága Ghana National Liberation Council, Ọ̀gágun Lt.-General J.A. Ankrah-Chairman
- Ọ̀gágun Lt.-Col. Yakubu Gowon- Ààrẹ Ológun Nàìjíríà
- Ọ̀gágun, Lt.-Col. Odumegwu Ojukwu - Gómìnà ẹkùn ìlà Òòrùn Nàìjíríà
- Ọ̀gágun, Major Mobolaji Johnson - Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó
- Ọ̀gágun, Lt.-Col. Hassan Katsina - Gómìnà ẹkùn àríwá
- Ọ̀gágun, Lt.-Col. David Ejoor - Gómìnà ẹkùn ààrin ìwọ oòrùn
- Ọ̀gágun, Commodore Joseph Edet Akinwale Wey - Igbakeji Ààrẹ Nàìjíríà
- Ọ̀gágun, Colonel Robert Adebayo - Gómìnà ẹkùn ìwọ oòrùn
- Alhaji Kam Selem
- Mr. T. Omo-Bare
Àwọn yòókù ni:
- N. Akpan, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ìlà Òòrùn Nàìjíríà
- Alhaji Ali Akilu Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn àríwá Nàìjíríà
- D. Lawani Under, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ààrin ìwọ oòrùn Nàìjíríà
- P. Odumosu, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ìwọ Òòrùn Nàìjíríà
- S. Akenzua (ẹni tí ó wá jọba ní ìlú Benin, Erediauwa I[4]Àdàkọ:Circular reference)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ / Biafra Story, Frederick Forsyth ,Leo Cooper, 2001 ISBN 0-85052-854-2
- ↑ Ethnic politics in Kenya and Nigeria By Godfrey Mwakikagile, Nova Publishers, 2001.ISBN 1-56072-967-8
- ↑ http://www.dawodu.com/aburi1.htm
- ↑ Erediauwa I