Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Málì

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Málì ní oṣù kẹta ọdún 2020.

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Málì
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiMali
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, China
Index caseBamako, Kayes
Arrival date25 March 2020
(4 years, 6 months, 3 weeks and 1 day)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn2,467 (as of 17 July)[1]
Active cases555 (as of 17 July)[1]
Iye àwọn tí ara wọn ti yá1,791 (as of 17 July)[1]
Iye àwọn aláìsí
121 (as of 17 July)[1]

Ìpìnlẹ̀

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù ìkíní ọdún 2020, àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ni àgbáyé (World Health Organization) fìdí rẹ múlẹ̀ pé kòkòrò àrùn ẹ̀rankòrónà ni ó fa àrùn atégùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan, agbègbè Hube ní orílẹ̀-èdè China èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]

Ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ti SARS tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2003[3][4] sùgbọ́n bí àrùn yí ṣe ń tàn káàkà kiri pọ̀ púpọ̀ ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsì.[5]

Àwọn àkókò tí àrùn yí ń tàn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó n ṣẹlẹ̀

àtúnṣe

Oṣù Kẹta Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè Málì fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 méjì àkọ́kọ́ múlẹ̀.[6]

Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ilé-iṣẹ́ ti ìlera àti àwùjọ ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méjì. Ní èròngbà àti dojúkọ àjàkálẹ̀-àrùn tí ó n ja orílẹ̀-èdè yí, Ààre orílẹ̀-èdè olómìnira ti Málì, Ibrahim Boubacar keta, kéde ipò pàjáwìrì ní ìlú àti òfin kónílé ó gbélé láti agogo ̀mẹ́sán án àsálẹ́ sí agogo márùn ún òwúrọ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Málì.[7]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, pẹ̀lú àyẹ̀wò tuntun méje tí ó fìdí ẹ̀rankòrónà múlẹ̀ ní Málì, ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀rankòrónà ní orílẹ̀-èdè Málì lọ sókè sí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kànlá.[8]

Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, wọ́n fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méje múlẹ̀, àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ti ní àrùn COVID-19 wá di méjìdínlógún.[9] Isele eni akoko ti o je alaisi latipase ajakale-arun COVID-19 ni o waye ni osu yi.[10]

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ènìyàn márùndínlọ́gbọ̀n ni àyèwò fìdí rẹ múlẹ̀ pé wọ́n ní àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19. Àwọn tí ń ṣe àkóso ètò ìlera sọ wípé àwọn ènìyàn méjì ló jẹ́ aláìsí.[11]

Oṣù Kẹrin Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ìparí oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ 490 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn 329 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ́n si ti jẹ́ aláìsí.

Oṣù Kárùn ún Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ìparí oṣù kárùn ún, ìṣẹ̀lẹ̀ 1265 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn 472 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn mẹ́tàdínlógórin ti jẹ́ aláìsí.

Oṣù Kẹfà Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ìparí oṣú kẹfà, ìṣẹ̀lẹ̀ 2181 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí ̀awọn ènìyàn 591 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn 116 ti jẹ́ aláìsí.

Osu Keje Odun 2020

àtúnṣe

Ni osu keje, isele 354 ni won fidi re mule, eyi ti o mu ki apapo gbogbo isele arun korona ni orile-ede mali di 2,535 ninu eyi ti awon eniyan 474 ti won n se aisan lowolowo ni opin osu keje. Iye awon alaisan ti won ti je alaisi lo soke lati mejo si merinlelogofa(124).

Osu Kejo Odun 2020

àtúnṣe

Lati ojo kini osu kejo si ojo kerindinlogun osu kejo,eyi ti i se ojo meji saaju isote ti o yori si eyi ti awon ologun fi gba ijoba ni orile-ede yi, isele 2,640 ni won fidi re mule. awon alaisan 528 ni won n gba itoju lowolowo nigbati awon 1,987 alaisan ti ri iwosan gba ti awon alaisan ti o ti ku je marundinlaadoje(125). Ni osu kejo yi, awon isele ojilenigba le kan(241) ni won tun suyo eyi ti o mu ki apapo iye awon isele arun yi di 2,776. Iye awon alaisan ti o ku lo soke si merindinlaadoje(126). Ni opin osu yi, awon ti o n gba itoju lowolowo je 481.

Osun Kesan an Odun 2020

àtúnṣe

Titi di ojo kejila osu kesan an, 2,916 ni iye awon isele ti won fidi re mule , ninu eyi ti o je wipe awon ti o n gba itoju lowolowo je 512, awon alaisan ti o ti ri iwosan gba je 2,276 nigba ti awon alaisan ti o ti ku je mejidinlaadoje(1280). Ninu awon ojo ti o seku ninu osu kesan an, awon isele marundinlaadowaa(185) miran ni o tun suyo eyi ti o mu ki apapo iye awon isele arun korona di 3,101 ni orile-ede Mali. Awon meta ti o tun je alaisi mu ki apapo iye awon ti o ti ku di mokanlelaadoje(131). Iye awon alaisan ti won ti gba iwosan lo soke si 2,443 eyi ti o wa mu ki iye awon alaisan ti o n gba itoju lowolowo je 527 ni opin osu kesan an.

Àwọn ọ̀nà láti dènà àrùn COVID-19

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kejídínlógún oṣù kẹta, Ààrẹ Ibrahim Boubacar Keita dá àwọn ọkọ̀ òfurufú tí wọ̀n ń bọ̀ láti orílẹ̀-èdè tí àjàkálẹ̀ àrùn yí ti ń ṣẹlẹ̀ dúró. Ààrẹ tún ti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ pa, ó sì fagilé àwọn àpèjọ tí ó bá tóbi. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìdìbò tí wọ́n ti gbèrò pé yí ò wáyé ní oṣù kẹta sí oṣù kẹrin, èyí tí wọ́n ti ń sún síwájú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀ nítorí pé ipò tí ètò ààbò wa ní orílẹ̀-èdè kò dára, ni wọ́n tẹ̀ síwájú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti gbèrò rẹ.[12]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 "Coronavirus in Africa tracker". bbc.co.uk. Retrieved 17 July 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-07-24. 
  3. "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-07-24. 
  4. "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-07-24. 
  5. Higgins, Annabel (2020-07-24). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-07-24. 
  6. "Mali reports first 2 confirmed cases of COVID-19 - English.news.cn". Xinhua (in Edè Ṣáínà). 2020-03-25. Archived from the original on 2020-03-25. Retrieved 2020-07-24. 
  7. "Coronavirus au Mali : •4 cas enregistrés en deux jours • Le Président déclare l’état d’urgence sanitaire et instaure le couvre-feu". maliweb.net (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24.  horizontal tab character in |title= at position 57 (help)
  8. COULIBALY, Mariam. "7 nouveaux tests positifs de Coronavirus : le Mali passe à 11 cas". Studio Tamani : Toutes les voix du Mali : articles, journaux et débats en podcast (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24. 
  9. Boureima (2020-03-28). "Coronavirus au Mali: sept nouveaux cas confirmés, le total passe à 18". Wakat Séra (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24. 
  10. Dakaractu (2020-03-28). "Coronavirus : Le Mali enregistre son premier décès.". DAKARACTU.COM (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24. 
  11. "Mali: Situation du Coronavirus au Mali ; Le pays enregistre 25 cas et 2 décès en mois d’une semaine". maliactu.net (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24. 
  12. "Mali Proceeds With Elections Despite Coronavirus Fears". Channels Television. 2020-03-19. Retrieved 2020-07-24.