Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Gàbọ̀n
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-9 wọ orílẹ̀-èdè Gabon ní inú oṣù kẹ́ta ọdún 2020.
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-9 ní Orílẹ̀-èdè Gabon | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Gabon |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Arrival date | 12 March 2020 (4 years, 9 months, 1 week and 1 day) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 6,588 (as of 23 July)[1] |
Active cases | 2,306 (as of 23 July) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 4,235 (as of 23 July) |
Iye àwọn aláìsí | 47 (as of 23 July) |
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
àtúnṣeNí ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí [2][3] Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003. Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpò ènìyàn lágbáyé,[4][5][6]
Àwọn àsìkò kọọ̀kan tí ó ṣẹlẹ̀
àtúnṣeOṣù kẹ́ta ọdún 2020
àtúnṣeWọ́n kéde akọsílẹ̀ àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà tí a tún mọ̀ sí COVID-9 ní orílẹ̀-èdè Gabon ní ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹ́ta ọdún 2020, lára ìkan nínú ọmọ orílẹ̀-èdè wọn tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju mẹ́tadínlógbọ̀n lọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀-èdè Faransé. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tin tí ó dé ni wọ́n tó fìdí àrùn náà múlẹ̀ lára rẹ̀.[7] Ní ọjọ́ Kẹtalélógún oṣù kẹta, wọ́n tún ṣàwárí àwọn méjì míràn tí wọ́n ti ní àrùn yí, tí ó fi mọ́ obìnrin kan tí ó ń ṣíṣe ní ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ó ń rí sí ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè Gabon ní ilẹ̀ òkèrè. Lẹ́yìn tí ó ti lọ sí orílẹ̀-èdè bíi: Marseille àti Paris, ṣáájú kí ó tó padà wá sílé. [8]ẹnìkẹ́ta jẹ́ ọlọ́pá tí ọjọ́ otí rẹ̀ kò ju ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí ó ń ṣiṣẹ́ ní pápákọ̀ òfurufú Léon-Mba International Airport. Òun ló yẹ ìwé-ìrìnà ẹni akọ́kọ́ tí kó àrùn náà wọ orílẹ̀-èdè Gabon nígbà tí ó ń bọ̀ láti orílẹ̀-èdè Faransé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹ́ta ọdún 2010.[9]
Ní ogúnjọ́ oṣù kẹ́ta, orílẹ̀-èdè Gabon ní akọsílẹ̀ ẹni akọ́kọ́ tí ó papò dà.[10]
Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù kẹ́ta, ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ó ń rí ètò ìlera tẹpá mọ́ Ìṣàyẹ̀wò àrùn COVID-9 pẹ̀lú bí àrùn náà ṣe ń gbilẹ̀ si ní orílẹ̀-èdè Gabon. Lára rẹ̀ ni ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta tí ó tún jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Togo, àmọ́ tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Gabon tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darí dé láti orílẹ̀-èdè Senegal ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ́ta. Ẹlòmíràn náà tún ni ẹni tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Gabon, amọ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀-èdè Faransé ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹ́ta.[11]
Láàrín oṣù yí, wọ́n ti ní akọsílẹ̀ méje mìíràn, ẹnìkan papò dà, bẹ́ẹ̀ ni ó ku àwọn mẹ́fà tí wọ́n kù. [12]
Oṣù kẹ́rin ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù kẹrin, iye àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùún mẹ́fà ó lé mèsàán. Àwọn mẹ́ta péré ni wọ́n papò dà. Àwọn mètadínlọ́gọ́rin. Tí ó sì ku àwọn ọgọ́rún méjì ó lé mẹ́fà ní ìparí oṣù kẹrin. [13]
Oṣù karùún ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù Karùún, wọ́n tún ní akọsílẹ̀ ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùún mẹ́ta ó lé mọ́kandílọ́gọ́jọ, tí ó mú iye àwọn tí ó ti kó àrùn Kòrónà l9 sí ẹgbẹ̀rún méjì ati ọgọ́rùún mẹ́fà ó lé márùndínlọ́gọ́ta. Iye àwọn tí wọ́ papò dà jẹ́ mẹ́tàdínlógún. Iye àwọn tí wọ́n rí ìwòsàn gbà jẹ́ ọgọ́rùún méje ó lé méjìlélógún. [14]
Oṣù Kẹfà ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù Kẹfà, wọ́n tún ní akọsílẹ̀ tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì ati ọgọ́rùún méje ó lé mọ́kandínlógójì. Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n papò dà jẹ́ méjìlélógójì. Iye àwọn tí wọ́n rí ìwòsàn gbà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùún mẹ́rin ó lé ogún.[15]
Oṣù keje ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù keje, orílẹ̀-èdè Gabon fòpin sí fífòntẹ̀ lu ìwé ìrìnà àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ láti wá sí Gabon láti àwọn orílẹ̀-èdè Europe àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí àrùn náà ti gbilẹ̀ jùlọ.[16]
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Infos Corona Virus – Informez-vous sur le Corona Virus" (in Èdè Faransé). Archived from the original on 2020-06-03. Retrieved 2020-07-23.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ {cite web |url= https://www.imperial.ac.uk/news/196137/crunching-numbers-coronavirus/ |title=Crunching the numbers for coronavirus |website=Imperial News|access-date=15 March 2020|archive-url= https://web.archive.org/web/20200319084913/https://www.imperial.ac.uk/news/196137/crunching-numbers-coronavirus/%7Carchive-date=19 March 2020|url-status=live}}
- ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Ghana, Gabon confirm first cases of coronavirus". National Post (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Reuters. 13 March 2020. Retrieved 13 March 2020.
- ↑ "Urgent : 2 nouveaux cas confirmés de Covid-19". GabonActu. 17 March 2020. Retrieved 20 March 2020.
- ↑ "2 new COVID-19 cases confirmed in Gabon - Xinhua | English.news.cn". xinhuanet.com. Archived from the original on 2020-03-26. Retrieved 2020-03-26.
- ↑ "Coronavirus : premier décès enregistré au Gabon". GabonMediaTime. 20 March 2020. Archived from the original on 10 April 2020. Retrieved 20 March 2020.
- ↑ "Covid-19 : Le Gabon enregistre son 6è cas positif". 23 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 72" (PDF). World Health Organization. 1 April 2020. p. 8. Retrieved 24 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 102" (PDF). World Health Organization. 1 May 2020. p. 5. Retrieved 24 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 133" (PDF). World Health Organization. 1 June 2020. p. 6. Retrieved 24 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 163" (PDF). World Health Organization. 1 July 2020. p. 6. Retrieved 24 July 2020.
- ↑ "Gabon Bans European Travelers After Exclusion From Safe List". www.msn.com. Retrieved 2020-07-16.