Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní ilẹ̀ Màláwì
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé ilẹ̀ Màláwì ní́ ọjó kejì oṣù kẹrin ọdún 2020.[1]
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní ilẹ̀ Màláwì | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Malawi |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China via India |
Index case | Lilongwe |
Arrival date | 2 April 2020 (4 years, 8 months, 3 weeks and 5 days) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 2,810 |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,111 |
Iye àwọn aláìsí | 55 |
Ìpìlẹ̀
àtúnṣeNí ọjọ́ kejìlá oṣù kíní ọdún 2020, àjọ tí ó ń rí si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization fìdí rẹ múlẹ̀ pé àrùn kòrónà ni ó fa àìsàn atégùn níbi àpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn ní Wuhan, agbegbe Hubei, ní orílẹ̀-èdè China èyí tí wọ́n ròyìn rẹ fún àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]
Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ti SARS tí ó wáyé ní ọdún 2003,[3][4] sùgbọ́n ìtànkálẹ̀ rẹ pọ̀ gidigidi tí a bá wo àwọn tí ó tí di olóògbé.[5]
Àkójọpọ̀ Àkókò
àtúnṣeOṣù Kẹrin Ọdún 2020
àtúnṣeÀàrẹ orílẹ̀-èdè Malawi, Peter Mutharika fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́ lórí ti àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 múlẹ̀ ní orílẹ̀-èd̀e Malawi ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin. Ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta yi ni ti arábìnrin kan, ọmọ orílẹ̀-èdè Malawi tí wọ́n bí sí ilẹ̀ Asian, pẹ̀lú ìbátan rẹ àti ọmọ ọ̀dọ̀ wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀-èdè Indian.[6]
Ìṣẹ̀lẹ̀ kẹrin ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin èyí tí ó ní ṣe pẹ̀lú ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà dé láìpẹ́ láti ilẹ̀ aláwọ̀funfun (United Kingdom).[7] Ìṣẹ̀lẹ̀ karùn ún ni ti arábìnrin kan tí ó ti padà dé láti ilẹ̀ aláwọ̀funfun (United Kingdom) tí wọ́n sì ti yà sọ́tọ̀ fún òsẹ̀ mélò ó kan seyin.[8] Ní ọjọ́ keje oṣù kẹrin ni wọ́n kéde pé arábìnrin yi ti jẹ́ aláìsí.[9] Orílẹ̀-èdè Màláwì tún ṣe àwárí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta míràn tí ó dájú èyí tí ó mú kí àpapọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yí di mẹ́jọ. Ọ̀kan ni ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n kan tí ó ti kọ́kọ́ ní ìfarakanra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú ẹni tí ó ti kọ́kọ́ fi orúkọsílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yi ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin. Ìṣẹ̀lẹ̀ kejì ni ti ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n tí ó padà dé láti ilẹ̀ aláwọ̀funfun (United Kingdom) ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹta nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kẹta jẹ́ ti arákùnrin ọmọ ọgbọ̀n ọdún kan tí ó rin ìrìnàjò lọ sí apá ilẹ̀ gúúsù ti Áfríkà (South Africa) ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta.[10]
Ní oṣú yí, ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàdínlógójì(37) ni wọ́n fìdí ẹ múlẹ̀, àwọn ènìyàn mẹ́ta jẹ́ aláìsí nígbàtí àwọn ènìyàn méje gba ìwòsàn, ó wá ku ènìyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n(27) tí àrùn yí ṣi n bájà lọ́wọ́lọ́wọ́.
Oṣù karùn ún Ọdún 2020
àtúnṣeNí oṣù karùn ún ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun òjìlénígba lé méje(247) ni ó ṣẹlẹ̀, èyí tí ó mú kí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí ẹ múlẹ̀ di ọ̀rìnlénígba lé mẹ́rin(284). Aláìsàn kan kú, èyí tí ó mú kí àwọn ènìyàn tí ó ti kú di mẹ́rin. Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn ń pọ̀ si láti márùndínlógójì(35) lọ sí méjìlélógójì(42), ó wá ku òjìlénígba dín méjì(238) àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìparí oṣù yí.
Oṣù Kẹfà Ọdún 2020
àtúnṣeNi osu kefa, ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 940 ni ó ṣẹlẹ̀, èyí tí ó mú kí iye àwọn tí wọ́n ti fìdí ẹ múlẹ̀ pé ó ní àrùn yí di 1224. Àwọn tí ó ti kú di mẹ́rìnlá. Àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn ń pọ̀ si láti okòólénígba dín méjì(218) sí ọ̀tàlénígba(260), ó wá jẹ́ wípé 950 àwọn ènìyàn ni wọ́n ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìparí oṣù yí.
Oṣù keje Ọdún 2020
àtúnṣeÌṣẹ̀lẹ̀ tuntun 2854 ni ó ṣẹ́yọ ní oṣù keje, èyí tí ó sọ àpapọ̀ iye ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ di 4078. Iye àwọn aláìsàn tí ó ti kú lọ sókè láti ọgọ́rùn ún(100) sí mẹ́rìnléláàdófa(114). Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti rí ìwòsàn gbà lọ sókè si i láti 1615 sí 1875, èyí tí ó mú kí iye àwọn aláìsàn tí ó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ jẹ́ 2089 ní òpin oṣù keje (èyí tí ó lọ sókè pẹ̀lú ìda a ọgọ́fà(120) nínú ọgọ́rùn ún (120%) láti òpin oṣù kẹfà).
Oṣù Kẹjọ Ọdun 2020
àtúnṣeNí ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ, iye àwọn aláìsàn tí ara wọ́n ti bọ̀sípò ti rékọjá ìdá á ààdọ́ta nínú ọgọ́rùn ún(50%) fún ìgbà akọ́kọ́.
Ìgbéṣè Ìjọba
àtúnṣePẹ̀lú bí kò ti ṣe sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìd́i rẹ múlẹ̀ kí ó tó di ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, Ààrẹ Mutharika kéde àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀rankòrónà gẹ́gẹ́ bi i àjálù tí ó dé bá orílẹ̀-èdè wọn. Lára àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní fífagilé àwọn àpéjọ tí ó bá ti ju ọgọ́rùn ún ènìyàn lọ ní àwọn ilé ìjọsìn, àwọn ibi àpéjọpọ̀, àwọn ibi ìgbéyàwó àti àwọn ibi ìsìnkú. Ààre tún sọ wípé kí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba àti ti aládàáni di títìpa láti ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta. Ó tún tẹ̀síwájú láti rọ ìjọba pé kí wọ́n dáwọ́ gbígba àwọn àlejò láti òkè-òkun fún àwọn ìpàdé dúró, nígbà tí ó tun fi òfin de àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba làti lọ sí àwọn ìpàdé ní àwọn agbègbè àti òkè-òkun. Ààre tún rọ àwọn olùgbé ìlú àti àwọn àlejò tí wọ́n ń bọ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn yí ti ń jà lọ́wọ́lọ́wọ́ pé kí wọ́n fí ara wọn sílẹ̀ fún ìfinipamọ́.[11]
Lẹ́hìn ìgbàtí wọ́n ti rí àrídájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ ní oṣù kẹrin ni Ààrẹ Mutharika ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tuntun nípa dídá àwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ,àti àwọn àpérò dúró. Ó tún pàṣẹ fún ẹ̀ka tí ó wà nípa àkóso ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ti ilé àwọn ọmọ aláìgbọràn láti pèsè àkójọpọ̀ orúko àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ti àwọn ọmọ aláìgbọràn tí wọ́n ṣẹ àwọn ẹṣẹ kéékèké pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti lo iye àkóko tí ó pọ̀ nínú àkókò tí ó yẹ kí wọ́n lò lórí ẹ̀ṣẹ̀ ìwà ọ̀daràn tí kò pọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀. Ó ní kí wọ́n mú àkójọpọ̀ orúko yi lọ sí ọ̀dọ Minisita fún ààbò lórí ilé àti ilẹ̀ láti pé kí ó lè dín àpọ̀jù àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Malawi kù.[12] Àwọn ìgbésẹ̀ míràn tí wọ́n tún gbé ni díndín owó epo pẹtirolu kù àti mímójúkúrò lórí àsìnrù tí ki i ṣe ti àwọn arìnrìnàjò láti lè fi ran ilé-iṣẹ́ tí ó ń ri si àwọn arìnrìnàjò lọ́wọ́. Wọ́n tún mójúkúró lórí gbígba owó-orí olùgbé lórí àwọn àjèjì dókítà àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera. Wọ́n pe ẹ̀ka tí ó ń ri sí àpò ìṣura láti dín àwọn owó oṣù Ààrẹ, ti Mínísítà àti ti àwọn igbákejì Mínísítà kù ní ìwọn ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún fún oṣù mẹ́ta láti lè fi àwọn owó yi kojú àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀rankòrónà. Ẹ̀ka tí ó ń pa owó wọlé ní orílẹ̀-èdè Malawi ni wọ́n sọ fún wípé kí wọ́n ṣí àpò òṣùnwọ̀n kan fún àwọn tí wọ́n fẹ́ finú fẹ́dọ̀ san owó orí fún oṣù mẹ́fà láti lè tún fi ààyè gba àwọn tí wọ́n ti jẹ gbèsè owó orí láti lè sán án.[13] Ààrẹ Mutharika pe àwọn òṣìṣẹ́ láti pé kí wọ́n ma a gba iṣẹ́ ṣe lọ́wọ́ ara wọn yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì, ní èròngbà àti dín iye àwọn òṣìṣẹ́ tí yi o ma péjọpọ̀ ní ibi iṣẹ́ kù. Ní ọjọ́ kẹrìnlá, Ààrẹ Mutharika kéde ìsémọ́lé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún bẹ̀rẹ̀ láti alẹ́ Sátidé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin.[14] Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin, ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ní orílẹ-èdè Màláwì dá ìjọba lọ́wọ́ kọ́ fún ìgbà díẹ̀ lórí ìmúṣẹ ìsémọ́lé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún tí ó fẹ́ wáyé. Ìdálọ́wọ́kọ́ yi wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé àtakò tí àpapọ̀ àwọn àjọ tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn kọ.[15] Àríyànjiyàn tí àjọ tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn gùn lé lórí ni wípé wọ́n nílò àwọn òfin díẹ̀ si láti le dáàbò bo àwọn aláìní àti wípé ìsémọ́lé yi yíò mú ìpalára wá sí àwùjo.[16]
Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Foundation, Thomson Reuters (2020-04-02). "Malawi records first three cases of coronavirus". news.trust.org. Archived from the original on 2020-05-30. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ Higgins, Annabel (2020-04-14). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "Malawi confirms three cases of coronavirus: President Mutharika calls for calm - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-04-02. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ "Malawi records another Covid-19 patient, says Minister of Health - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-04-04. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ Ngwira, Robert (2020-04-06). "Malawi registers 5th COVID-19 case". Face Of Malawi. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ Chitsamba, Misso (2020-04-07). "JUST IN: MALAWI REGISTERS FIRST COVID-19 DEATH". Face Of Malawi. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "Malawi confirmed Covid-19 cases rise to 8, as first death recorded - Minister - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-04-07. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "Mutharika lays out Malawi ‘response plan’ on Coronavirus: Bans gatherings of 100 people, schools closing - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-03-20. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ "Mutharika urges Malawi unity and 'steadfast' in Covid-19 fight: Announce new measures to stop spread of outbreak - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-04-04. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ "Mutharika orders fuel price slash, pay cuts for Executive: Tax relief in Malawi - News from Malawi about Malawi". Malawi Nyasa Times - News from Malawi about Malawi. 2020-04-04. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ Editorial, Reuters (2020-04-14). "Malawi joins other southern African nations in coronavirus lockdown". U.S. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ Kondowe, Rabson. "Malawi court blocks coronavirus lockdown to protect the poor". Quartz Africa. Retrieved 2020-07-22.
- ↑ "Malawi high court blocks coronavirus lockdown". Al Jazeera. 2020-04-17. Retrieved 2020-07-22.