Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Western Sahara

Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ ní Western Sahara ní oṣù kẹrin ọdún 2020. Àgbègbè tí orílẹ̀ èdè Morocco pàṣẹ dé ní Western Sahara nìkan ni àrùn náà wà, kò sí ní àgbègbè Western Sahara tí Sahrawi Arab Democratic Republicpàṣẹ dé .[2]

Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Western Sahara
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní Western Sahara
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiWestern Sahara
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, China
Index caseBoujdour
Arrival dateỌjọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2020
(4 weeks)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn10 (as of 26 Jun)[1]
Active cases1 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá8 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà)
Iye àwọn aláìsí
1 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà)

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe

Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[3][4]

Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[5][6] ṣùgbọ́ rírànkálẹ̀ àrùn pọ̀ gidigidi, pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tí àìsàn náà pá.[7][5]

Bí àrùn náà ṣe ń tànkálẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà àtúnṣe

Ìlú Boujdour ni àwọn àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ilé-iṣẹ́ kan tó wà lábẹ́ àjọ àgbáyé tí wọ́n ń pè ní [United Nations Mission for the Referendum in Western Sahara]] (MINURSO) kọ́kọ́ kéde ẹni mẹ́rin àkọ́kọ́ tí wọ́n ní àrùn náà lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2020.[8]

Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsàn-án Osun kẹrin, MINURSO tún kéde ènìyàn méjì tuntun tí wọ́n tún lùgbàdì àrùn náà Dakhla, èyí tí ó mú àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní àrùn di mẹ́fà.[9]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Western Sahara Coronavirus: 10 Cases and 1 Deaths - Worldometer". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-26. 
  2. "Regular Updates by MINURSO on COVID-19". United Nations Mission for the Referendum in Western Sahara. 5 June 2020. Archived from the original on 30 April 2020. Retrieved 10 June 2020. 
  3. Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus. 
  5. 5.0 5.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "4 April 2020: REGULAR UPDATES BY MINURSO ON COVID-19". United Nations Mission for the Referendum in Western Sahara (MINOSUR). 4 April 2020. Archived from the original on 30 April 2020. https://web.archive.org/web/20200430224322/https://minurso.unmissions.org/regular-updates-minurso-covid-19. Retrieved 5 April 2020. 
  9. "9 April 2020: REGULAR UPDATES BY MINURSO ON COVID-19". United Nations Mission for the Referendum in Western Sahara. 9 April 2020. Archived from the original on 10 April 2020. Retrieved 12 April 2020.