Àjẹsára rotavirus
Àjẹsára rotavirus jẹ́ àjẹsára tí a fi ń dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn kan tí à ń pè ní rotavirus.[1] Àwọn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn wọ̀nyí ló má a ń sábà ṣe òkùnfà ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ láàárín àwọn ọmọdé.[1] Àjẹsára náà a má a dènà ìwọ̀n 15 sí 34% ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń tẹ̀síwájú, àti ìwọ̀n 37 sí 96% ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìtẹ̀síwájú.[2] Àjẹsára náà dàbí èyí tó má a ń dín ewu ikú tó ti ipasẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru wáyé kù láàárín àwọn ọmọdé.[1] Fífún àwọn ọmọ-ọwọ́ ní àjẹsára náà dàbí ohun tó má a ń dín ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà kù láàárìn àwọn àgbàlagbà àti láàárín àwọn tí kò tíì gba àjẹsára náà tẹ́lẹ̀ rí.[3]
Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbani nímọ̀ràn pé kí àjẹsára rotavirus jẹ́ ara àwọn àjẹsára tí à ń gbà lóòrèkóòrè, pàápàá júlọ ní àwọn agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀. A gbọ́dọ̀ ṣe èyí ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú gbígbé àwọn ohun bíi fífún ọmọ lọ́yàn, fífọ ọwọ́ ẹni, àti lílo omi tó mọ́ àti ìmọ́tótó lárugẹ. Ẹnu ni a ń gbà fúnni ní àjẹsára náà, ènìyàn sì nílò ìwọ̀n egbògi náà méjì sí mẹta. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fúnni láti ìgbà tí ènìyàn bá ti tó ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́fà.[1]
Lílò àjẹsára náà kò léwu. Èyí kan lílò fún àwọn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS pàápàá. Ẹ̀yà ìṣáájú àjẹsára náà níí ṣe pẹ̀lú lílọ́pọ̀ ìfun, ṣùgbọ́n ẹ̀yà titun rẹ̀ ní báyìí kò tíì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú èyí dájúdájú. Nítorí ewu tó lè wáyé, a kò gbani nímọ̀ràn láti lòó fún àwọn ọmọ-ọwọ́ tí ìfun wọn ti lọ́ pọ̀ rí. A ṣe àgbéjáde àwọn àjẹsára náà nípasẹ̀ kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn rotavirus tí a ti sọ di aláìlágbára.[1]
Àjẹsára náà di èyí tó wà fún lílò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 2006.[4] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 6.96 sí 20.66 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[6] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ ju 200 USD lọ.[7] Dí ọdún 2013 oríṣi àjẹsára náà méjì ni ó wà káàkiri àgbáyé, Rotarix àti RotaTeq, pẹ̀lú àwọn oríṣi díẹ̀ mìíràn tó tún wà ní àwọn orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan.[1]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Rotavirus vaccines. WHO position paper – January 2013.". Releve epidemiologique hebdomadaire / Section d'hygiene du Secretariat de la Societe des Nations = Weekly epidemiological record / Health Section of the Secretariat of the League of Nations 88 (5): 49-64. 1 February 2013. PMID 23424730. http://www.who.int/wer/2013/wer8805.pdf?ua=1.
- ↑ Soares-Weiser, Karla, ed (2012). "Vaccines for preventing rotavirus diarrhoea: vaccines in use". Cochrane Database Syst Rev 11: CD008521. doi:10.1002/14651858.CD008521.pub3. PMID 23152260.
- ↑ Patel MM, Steele D, Gentsch JR, Wecker J, Glass RI, Parashar UD (January 2011). "Real-world impact of rotavirus vaccination". Pediatr. Infect. Dis. J. 30 (1 Suppl): S1–5. doi:10.1097/INF.0b013e3181fefa1f. PMID 21183833.
- ↑ "Rotavirus Vaccine Live Oral". The American Society of Health-System Pharmacists. Retrieved Dec 14, 2015.
- ↑ "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014.
- ↑ "Vaccine, Rotavirus". International Drug Price Indicator Guide. Retrieved 6 December 2015.
- ↑ Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 317. ISBN 9781284057560.