Àwọn Obìnrin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Àdàkọ:Infobox women by region Àdàkọ:Women in society sidebar Ipa tí Àwọn Obìnrin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kó láwùjọ yàtọ̀ lóríranǹran nípa ọ̀rọ̀ ajẹmọ́ ẹ̀sìn àti àgbègbè tí wọ́n bá wà. Ipa pàtàkì tí a mọ̀ mọ àwọn obìnrin ni ipa gẹ́gẹ́ bí ìyá, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò obìnrin àti ìyàwó. Ní àfikún, ipa obìnrin nígbà mìíràn máa ń dá lórí ẹ̀yà àti ẹ̀sìn tí wọn ba n ṣe. Bíi àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin lápá ìlà oòrùn sáàbà máa ń kópa gẹ́gẹ́ bí ìyàwó-ilé póńbélé, èyí kò sìn rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin lápá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó jẹ́ wípé wọ́n máa ń àwọn ipa mìíràn láwùjọ. Lára àwọn ìpèníjà ayé òde-òní fún àwọn obìnrin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni; Ìgbéyàwó Ọmọdé[1] àti abé dídá fún ọmọbìnrin.[2]

Àwọn ìpèníjà àwùjọ

àtúnṣe

Ìgbéyàwó ọmọdé

àtúnṣe

Ìgbéyàwó ọmọdé wọ́pọ̀ ni Nàìjíríà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi jẹ́ pé idà mẹ́tàlélógójì (43%) nínú ọgọ́rùn-ún ni àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọn kò ì tí ì bàlágà tàbí tó ọmọ ọdún méjìdínlógún tí Wọ́n ń gbé ní ìyàwó, ìdá mẹ́tàdínlógún (17%) nínú wọn ni kò tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kí wọ́n tó gbé wọn ní ìyàwó.[1] The prevalence, however, varies greatly by region.[1] Nigeria's total fertility rate is 5.07 children/woman.[3] Ìṣọ̀wọ́ bímọ bí eku ẹdá ní Nàìjíríà ń fa ìṣòro àwùjọ, ètò ọ̀rọ̀ ajé àti àìdàgbàsókè lórílẹ̀ èdè náà.[4][5]

Àṣà abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin

àtúnṣe

Abẹ́ dídá fún àwọn ọmọbìnrin jẹ àṣà tí ó wọ́pọ̀ jùlo lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ju àwọn orílẹ̀-èdè tó kù lọ ní àgbáyé.[6] Àṣà yìí jẹ́ àṣà tí ó léwu fún ọmọbìnrin, ó sìn tàbùkù fún àwọn ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn.[7] O máa ń fa àìrọ́mọbí, ikú ìyá ọmọ, àwọn àrùn, àti àìlègbádùn ìbálópọ̀ ọkùnrin àti obìnrin.[8]

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìdá mẹ́tàdínlọ̀gbọ̀n (27%) àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà ní mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ókàndínlààádọ́ta ni àṣà abẹ́ dídá tí ṣe àkóbá fún títí di ọdún 2012.[9] Fún nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn báyìí, àṣà yìí tí dín kù sí bí i ìdá àádọ́ta (50%) ní àwọn àgbègbè mìíràn ni Nàìjíríà.[7]

ṣíṣeṣẹ́ lọ́mọdébìnrin

àtúnṣe

Púpọ̀ nínú àwọn ọmọdébìnrin ni Wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọọ̀dọ̀ nílé, nílé ìtajà tàbí kí kiri ọjà káàkiri ojúlé. Lílọ àwọn ọmọdébìnrin fún ètò ọ̀rọ̀ ajé máa ń fa ìbínú àti àwọn ìjàmbá mìíràn bíi ìbálòpọ̀ tipátipá, ọmọ sísọnù, àìrí ìtọ́jú òbí, àti àṣìlò ọmọdébìnrin.[10]

Rògbòdìyàn abẹ́lé

àtúnṣe

Oyún ṣíṣẹ́

àtúnṣe

Fífẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó

àtúnṣe
 
The 12 Muslim majority states in Nigeria's north where polygamy is legal.

Méjìlá nínú àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló fọwọ́ sí fífẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó. Gbogbo àwọn Ìpínlẹ̀ yìí ni Wọ́n faramọ́ lílọ òfin ṣàríyà, òfin ẹ̀sìn Mùsùlùmí. Àwọn Ìpínlẹ̀ náà tí Wọ́n jẹ́ Ìpínlẹ̀ lókè ọya Nàìjíríà ni; Ìpínlẹ̀ Bauchi, Ìpínlẹ̀ Borno, Ìpínlẹ̀ Gombe, Ìpínlẹ̀ Jigawa, Ìpínlẹ̀ Kaduna, Ìpínlẹ̀ Kano, Ìpínlẹ̀ Katsina, Ìpínlẹ̀ kebbi, Ìpínlẹ̀ Niger, Ìpínlẹ̀ Sokoto, Ìpínlẹ̀ Yobe, Ìpínlẹ̀ Zamfara [11] which allows for a man to take more than one wife.[12]

NÍ àwọn Ìpínlẹ̀ tó kù, ìgbéyàwó aláya kan àti ọlọ́pọ̀ ìyàwó nínú ẹ̀sìn kírísítẹ̀nì àti ẹ̀sìn àbáláyé ni Wọ́n wà lábẹ́ òfin ìgbéyàwó orílẹ̀-èdè.

Iṣẹ́ aṣẹ́wó

àtúnṣe

Ẹ̀kọ́ kíkà ọmọbìnrin

àtúnṣe

Ìṣègbè-fábo

àtúnṣe

Wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ àjọ ìṣègbè-fábo lọ́dún 1982, tí wọ́n ṣe ìpéjọ rẹ̀ ní Ahmadu Bello University. Nínú ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ tó wáyé níbẹ̀ fihàn pé àwọn ọmọbìnrin Nàìjíríà tí Wọ́n ti lẹ́kọ̀ọ́ ifáfitì ti ń ìtagìrì àti ṣe ìpolongo tó lóòrì nípa bí ipa obìnrin ṣe nílò ìtajìgí àti akitiyan tó dọ́ṣọ̀ láti lè jẹ́ kí ó wà nínú àwọn ètò pàtàkì nínú ìṣẹ̀jọba. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, èyí kò ì tíì rí bẹ́ẹ̀ láwùjọ wá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin ìyálọ́jà ni Wọ́n ṣe àtakò àwọn àjọ ìṣègbè-fábo ní ìlú Ibadan nígbà tí wọ́n pe àpérò láti ṣe àtakò ìgbéyàwó aláya púpọ̀. Àwọn ìyálọ́jà wọ̀nyí jiyàn pé àwọn faramọ́ ìgbéyàwó aláya púpọ̀ nítorí pé ó fún wọn ní anfaani lati gbájúmọ́ olówò wọn àti bákan náà ṣe ìtọ́jú ẹbí wọn. Ìwádìí fihàn pé àwọn obìnrin lápá ìlà ìwọ oòrùn Nàìjíríà kò faramọ́ ìgbéyàwó aláya púpọ̀, tí púpọ̀ nínú wọn sìn máa gbìyànjú láti bímọ púpọ̀ láti dènà kí ọkọ wọn máa fẹ́ ìyàwó kejì. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, ipò obìnrin láwùjọ Nàìjíríà yóò gbájúmọ́ síi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́-ọ̀la obìnrin Nàìjíríà kò ì tí ní ẹ̀tọ́ bí ti ọkùnrin.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 https://www.girlsnotbrides.org/child-marriage/nigeria/
  2. Okeke, T.; Anyaehie, U.; Ezenyeaku, C. (2012). "An Overview of Female Genital Mutilation in Nigeria". Annals of Medical and Health Sciences Research 2 (1): 70–73. doi:10.4103/2141-9248.96942. PMC 3507121. PMID 23209995. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3507121. 
  3. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2009-10-28. Retrieved 2020-05-05. 
  4. https://www.vanguardngr.com/2018/04/nigeria-high-fertility-rate-fueling-underdevelopment-experts/
  5. https://www.nytimes.com/2012/04/15/world/africa/in-nigeria-a-preview-of-an-overcrowded-planet.html
  6. Okeke, TC; Anyaehie, USB; Ezenyeaku, CCK (2012-01-01). "An overview of female genital mutilation in Nigeria" (in en). Annals of Medical and Health Sciences Research 2 (1): 70–3. doi:10.4103/2141-9248.96942. PMC 3507121. PMID 23209995. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3507121. 
  7. 7.0 7.1 Muteshi, Jacinta K.; Miller, Suellen; Belizán, José M. (2016-01-01). "The ongoing violence against women: Female Genital Mutilation/Cutting". Reproductive Health 13: 44. doi:10.1186/s12978-016-0159-3. ISSN 1742-4755. PMC 4835878. PMID 27091122. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=4835878. 
  8. Topping, Alexandra (2015-05-29). "Nigeria's female genital mutilation ban is important precedent, say campaigners". the Guardian. Retrieved 2016-05-28. 
  9. "Female Genital Mutilation/Cutting in the United States: Updated Estimates of Women and Girls at Risk, 2012". Public Health Reports (U.S. Government Printing Office). Mar 2016. https://www.uscis.gov/sites/default/files/USCIS/Humanitarian/Special%20Situations/fgmutilation.pdf. Retrieved 29 May 2016. 
  10. Audu, B., Geidam, A. and Jarma, H. 2009. Child labor and sexual assault among girls in Maiduguri. Nigeria International Journal of Gynecology and Obstetrics, 104:64–67.
  11. "Analysis: Nigeria's Sharia split". News.bbc.co.uk. Retrieved 21 November 2014. 
  12. "Nigeria: Family Code". Genderindex.org. Archived from the original on 3 December 2014. Retrieved 21 November 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)