Èdè Tápà (tàbí Nupe, Nupenci, Nyinfe, Anufe) jẹ́ èdèNàìjíríà (ní Ìpínlẹ̀ Niger, Kwárà, Kogí, Èkìtì, àti Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀ Abùjá).[1]

Nupe
Sísọ níNàìjíríà
Ọjọ́ ìdásílẹ̀1990
AgbègbèÌpínlẹ̀ Niger, Ìpínlẹ̀ Kwárà, Ìpínlẹ̀ Kogí, Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀ Abùjá
Ẹ̀yàÀwọn Nupe
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀800,000
Èdè ìbátan
ìsọèdè
Nupe Tako (Bassa Nge)
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-3nup

Ìró Ohùn

àtúnṣe

Èdè Tápà jẹ́ èdè oníròó ohùn, ìró ohùn márùn-ún ló wà. Wọ́n fi àmì ohùn sórí fáwẹ́lì láti fi ìró ohùn sílébù kan hàn.

Ìró ohùn Àmì ohùn
Ìró ohùn òkè (´) àmì ohùn òkè
Ìró ohùn àárín kò sí àmì ohùn
Ìró ohùn ìsàlẹ̀ (`) àmì ohùn ìsàlẹ̀
Ìró ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́ròkè (ˇ) àmì ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́ròkè
Ìró ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́rodò (ˆ) àmì ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́rodò

Fọnẹ́tíìkì

àtúnṣe

Fáwẹ́lì àìránmúpè márùn-ún ló wà nínú èdè Tápà: /a, e, i, o u/. Bákan náà ni fáwẹ́lì aránmúpè mẹ́ta ló wà: /ã, ĩ, ũ/.[2]

Kọ́ńsónáǹtì
Afèjìètèpè Afiyínfètèpè Àfèrìgìpè Afàjàfèrìgìpè Afàjàpè Afàfàsépè Afàfàséfètèpè Afitánnápè
Aṣẹ́nupè àìkùnyùn p t k kp /k͡p/
akùnyùn b d g gb /ɡ͡b/
Affricate àìkùyùn ts /t͡s/ c /t͡ʃ/
akùnyùn dz /d͡z/ j /d͡ʒ/
Àfúnnupè àìkùnyùn f s sh /ʃ/ h
akùnyùn v z zh /ʒ/
Aránmúpè m n
Àséèsétán l y /j/ w
Aréhọ́n r

Ìsọ̀rí

àtúnṣe

Ẹ̀rí ti onímọ̀ èdè fi hàn pé èdè Tápà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka èdè Tápà ti ẹbí Bẹ́núé-Kóńgò. Ìgbìrà, Gbari àti Gade jẹ́ èdè mìíràn tó wà nínú ẹ̀ka yìí. Èdè àdúgbò Tápà tó nǹkan bí méjì ló wà: Tápà àárín gbùngbùn àti Nupe Tako.[3]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àdàkọ:Èdè Nàìjíríà

  1. Project, Joshua (2014-11-01). "Nupe in Nigeria". Joshua Project. Retrieved 2023-06-14. 
  2. "Nupe language, alphabet and pronunciation". omniglot.com. 2023-06-14. Retrieved 2023-06-14. 
  3. "Nupe language". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2023-06-14.