Taxonomy not available for Carica; please create it automated assistant

Èso Ìbẹ́pẹ ( /pəˈpə/, US /pəˈpɑːjə/), ( /pəˈpɔː/[3]) tàbí ( /ˈpɔːpɔː/[3])[4] ni ó jẹ́ ohun ọ̀gbìn eléso tí ó jẹ́ ìkan lára ẹbi Carica papaya, èyí tí ó jẹ́ gbajúgbajà nínú àwọn ẹ̀yà èsò genus Carica tí wọ́n jẹ́ mọ́kànlélógún nínú ẹbí Caricaceae.[5] Ìlú Mesoamerica ni wọ́n ti kọ́kọ̀ ṣàwárì rẹ̀ tí wọ̀n sì gbìnín, tí ó fi wá wà káàkiri orílẹ̀ àgbáyè pátá lóde òní. [6][7] Ní ọdún 2020, orílẹ̀-èdè Índíà ni ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó pèsè èso ìbẹ́pẹ tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ àgbáyé pẹ̀lú ìdá méjìlélógójì (42%).

Ìbẹ́pẹ
Plant and fruit, from Koehler's Medicinal-Plants (1887)
Ipò ìdasí
Ìṣètò onísáyẹ́nsì [ edit ]
Irú:
Ìfúnlórúkọ méjì
Template:Taxonomy/CaricaCarica papaya

Bí orúkọ rẹ̀ ṣe wáyé

àtúnṣe

Gbólóhùn papaya ni wọ́n yọ láti ara èdè Arawak tí ó jẹ́ ẹ̀ka èdè Spanish.[8] Orúkọ rẹ̀ yí tí wọ́n pè ní papaya ni ó jẹ́ orúkọ tí ohun ọ̀gbìn eléso yí ń jẹ́ gan an. Àmọ́, orúkọ tí ó bá bá àwùjọ kọ̀ọ̀kan mu ni wọ́n lè pe èso náà.[6][9]

Bí ó ṣe rí

àtúnṣe

Ìbẹ́pẹ jẹ́ igi eléso tí ó ma ń ní ojú kékèké tí ewé ń gbà hù lára rẹ̀, ó ma ń ga tó ìwọ̀n bàtà 5–10 m (16–33 ft), tí àwọn ewé rẹ̀ náà sì ma ń gùn sókè ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé láti àárín lọ sí òkè igi náà pátá pàtá. Apá ìsàlẹ̀ igi ìbẹ́pẹ sábà ma ń jẹ́ ojú ogbẹ́ tí ewé ti hù tẹ́lẹ̀ tàbí ojú ibi tì èso rẹ̀ ti hù sí làra rẹ̀ nìgbà kan rí. Àwon ewé igi ìbẹ́pẹ ma ń fẹ̀ tó ìwọ̀n bàtà 50–70 cm (20–28 in), ewé rẹ sì ma ń ní ẹ̀ka méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó ma ń dán lójù, ó sì ma ń rí hàra-hàra lẹ́yìn.


Òdòdó rẹ̀

àtúnṣe

Irisi meji ni ododo ibẹpẹ ma n ni, akọkọ ma n ri sọọrọ, yoo si la si ọna marun un nigba ti o ba fẹ di ewe, eyi tumọ si wipe akọ ni ibẹpẹ naa. Irisi ẹlẹkeji ni wipe, ododo rẹ yoo ri roboto, oun naa yoo si pin si ọna marun un nigba ti o be fe di ewe tabi eso, yoo si sunmo abẹ eka igi naa daada, eyi tumọ si wipe abo ni irufẹ ibẹpẹ bẹẹ yoo jẹ.[10]:235 Atakọ atabo ibẹpẹ, aarin meji igi ati ẹka ewe ni awọn mejeeji yoo ti jade. Akọ ibẹpẹ ni tirẹ kii so eso kankan, o kan ma n ni ododo to pọ ni tirẹ ni, bakan naa ni abo rẹ kii n so eso pupọ ni tirẹ. Abo ibẹpẹ ni ododo lanu ni aṣalẹ ti wọn si ma n mu oorun adidun jade nigba ti iri ba sẹ si wọn ni alẹ́. [11]


Àwọn ìtọkasí

àtúnṣe
  1. Àdàkọ:Cite iucn
  2. "Carica papaya L.". U.S. National Plant Germplasm System. 9 May 2011. Retrieved 5 September 2017. 
  3. 3.0 3.1 "Papaw". Collins Dictionary. n.d. Retrieved 25 April 2014. 
  4. In North America, papaw or pawpaw usually means the plant belonging to the Annonaceae family or its fruit. Ref.: Merriam-Webster's Collegiate Dictionary (2009), published in United States.
  5. "Carica L.". World Flora Online. World Flora Consortium. 2022. Retrieved 17 November 2022. 
  6. 6.0 6.1 Morton, Julia F. (1987). "Papaya; In: Fruits of Warm Climates". Purdue University Center for New Crops and Plant Products. pp. 336–346. Retrieved 27 October 2023. 
  7. Chávez-Pesqueira, Mariana; Núñez-Farfán, Juan (1 December 2017). "Domestication and Genetics of Papaya: A Review". Frontiers in Ecology and Evolution 5. doi:10.3389/fevo.2017.00155. 
  8. Àdàkọ:OEtymD
  9. Àdàkọ:OEtymD
  10. Ronse De Craene, L.P. (2010). Floral diagrams: an aid to understanding flower morphology and evolution. Cambridge: Cambridge University Press. ISBN 978-0-521-49346-8. https://books.google.com/books?id=24p-LgWPA50C. 
  11. "Tree Directory". One Million Trees. 2022-07-25. Retrieved 2023-12-13.