Ìbàdàn Grammar School

Ìbàdàn Grammar School ni ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama kan tí ó wà ní agbègbè Mọ̀lété ní ìgboro ìlú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .

Àwòrán Ìbàdàn Grammar School

Ìtàn bí wọ́n ṣe dá a sílẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ọdún 1913. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí ó lààmì-laaka nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n wà ní ìlú Ìbàdàn.[1]. Lásìkò tí ètò ẹ̀kọ́ bá ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lámèyítọ́ ni wọ́n máa ń wá láti wá ṣe àbẹ̀wò sí ọgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ńlá láwùjọ Ìbàdàn ni wọ́n máa ń rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ yí fún ètò ẹ̀kọ́ tó yanrantí. [1] Ní ọdún kẹtàlélọ́gbọ̀n àkókọ́ tí wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ọkùnrin nikan ni wọ́n ń gbà wọlé láti kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí di ilé-ẹ̀kọ́ fún takọ-tabo ní ọdún 1941. Láàrín ọdún 1950 sí 1960, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé-ẹ̀rí "Higher School Certificate"(HSC) nígba tí wọ́n bá parí ẹ̀kọ́ iwe mẹ́fà. Ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ akọ́kọ́ ni Alexander Babátúndé Akínyẹlé. [2]

Àwọn àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́

àtúnṣe

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde níbẹ̀

àtúnṣe

Àwọn Itọ́kasí

àtúnṣe

Ìtàkùn ìjásóde

àtúnṣe

"Ibadan Grammar School, Old Students Association". 

Coordinates: 7°21′00″N 3°53′38″E / 7.350°N 3.894°E / 7.350; 3.894


Àdàkọ:Nigeria-school-stub