Ìtàn Darul Uloom Deoband (History of Darul Uloom Deoband)
Ìtàn Darul Uloom Deoband (tí a tún mọ̀ pẹ̀lú orúkọ Urdu rẹ̀ Tareekh e Darul Uloom Deoband) jẹ́ ìwé itan alápá méjì tí Syed Mehboob Rizwi kọ ní ọdún 1976. Gbogbo àwọn èniyàn gbà iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìtọ́kasí àkọ́kọ́ tí ó f'ẹsè múlẹ̀ lọ́rí ẹ̀ka ìmọ̀ náà [1] Iṣẹ́ yìí tọ'pasẹ̀ Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ọgọ́rùn-ọdún àti ipá tí Darul Uloom Deoband ń kó láti ara dídunúmọ́ ṣíṣe àtẹ̀jádè àtìgbàdégbà lati ọjọ́ gbọgbọrọ.[1] Apá kiní sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láti ìdásílẹ̀ Darul Uloom Deoband títí di ọdún 1976 ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ní àkókò kan náà, apá keji sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìlànà ìgbékalẹ̀ tí ń júwe Darul Uloom Deoband.[1] Títúmọ̀ apá kiní sí Gẹ̀ẹ́sì ṣáájú ayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún ti Darul Uloom Deoband ṣe, tí ìtúmọ apá Kejì jẹ́ títẹ̀jáde lẹ́hìn ayẹyẹ náà,[2] ti ìtumọ̀ ní èdè Lárúbáwá ń farahàn nínú ìwé àtìgbàdégbà tí Al-Da’i nìgbà gbogbo.[3]
Fáìlì:Cover of History of Darul Uloom Deoband.jpg English cover | |
Olùkọ̀wé | Syed Mehboob Rizwi |
---|---|
Àkọlé àkọ́kọ́ | تاریخ دارالعلوم دیوبند |
Country | India |
Language | Urdu |
Subject | Darul Uloom Deoband |
Genre | History |
Publisher | Darul Uloom Deoband |
Publication date | 1976 |
Published in English | 1980 |
OCLC | 20222197 |
Website | darululoom-deoband.com |
Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀
àtúnṣeMuhammad Tayyib Qasmi kọ ìwé kan ní ṣókí ti ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Darul Uloom Ki Sad Sali Zindagi ní ọdún 1965, ó fún wa ní ọ̀rọ̀ àkorí kúkúrú nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ Darul Uloom Deoband , ètò ẹ̀kọ́, ìhìnrere, àti àwọn ìṣàkóso rẹ̀.
Àkóónú
àtúnṣeÌwé náà jẹ́ àkọọ́lẹ̀ ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ náà, tí ó ń ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn amóríyá, àti àwọn ènìyàn tí ó kópa. Ó sọ nípa àfojúsùn àwọn Olùdásílẹ̀, àwọn àfojúsùn ilé-ẹ̀kọ́ náà, àwọn olùkọ rẹ̀, àwọn akẹ́ẹ̀kọ́, ẹ̀ka-ẹ̀kọ́, ìwé ìtọ̀nà rẹ̀, àti ìdàgbàsókè tí ó tẹ̀le e àti ipa tí Darul Uloom Deoband kó ní àwọn agbègbè oríṣiríṣ, láàrin orílẹ-èdè náà àti káàkiri àgbá-nlá-ayé. Ìfihàn àtúnṣe àkọ́kọ́ láti ọwọ́ Muhammad Tayyib Qasmi ní àádọ́ta ojú-ìwé , tí ó sàlàyé ìtàn ìlọsíwájú àti àwọn àṣeyọrí Darul Uloom Deoband.[4]
Ìgbàwọlé
àtúnṣeTaqi Usmani Taqi Usmani ka ìwé náà ohun tí ó ṣe pàtàkì púpọ fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àti àwọn ènìyàn tí ń gbẹ òǹgbẹ ìmọ.[5] Muhammadullah Khalili Qasmi, ònkọ̀wé Darul Uloom Deoband Ki Jame O Mukhtasar Tareekh, pé é ní ìgbìyànjú tí ó pàtàkì jùlọ nínú Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ Darul Uloom Deoband.[6] Saeed Ahmad Akbarabadi Saeed Ahmad Akbarabadi jẹ́wọ́ pé ònkọ̀wé náà kún ojú òṣùwọ̀n, ó yin ìwé náà fún ìṣàfihàn Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ṣókí nípa ìtàn ẹ̀kọ́ àti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Ìsìláámù nípasẹ àwọn orísun òdodo, àsọyé, àti Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ tí ó dára[4] Ní ìdàkejì, Muhammad Naveed Akhtar láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ghazi ṣe àtokò pé ìwé náà lo ọ̀nà kíkọ tí ó lẹ̀ (bíi ẹni fi ẹ̀lẹ̀ sọ ohun tí ó yẹ kí a là mọ́lẹ̀) tàbí sísọ̀rọ̀ pẹ̀lù ẹ̀bẹ̀, tí kò ní jẹ́ kí òye èróngbà ẹgbẹ́ náà tí ó ṣe pàtàkì gan-an ye àwọn ènìyàn dáadáa.[7]
Àṣeélẹ̀
àtúnṣeNi ọdun 2016, Majlis-e Shura ti Darul Uloom Deoband yan Muhammadullah Qasmi láti kọ Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ti ọdún àádọ́jọ àkọ́kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà, ìmísí èyí wá nípasẹ̀ ìwé iṣaaju tí Sayed Rizvi kọ pẹ̀lú àkọ́lé Darul Uloom Deoband Ki Jame O Mukhtasar Tareekh.[1] Abu Ukashah bu ẹnu àtẹ́ lu èyí ní ọdún 2019, ẹni tí ó jiyàn pé Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ò wúlò àtipé ìtọ́kasí ìfẹ̀ láti ṣe àtúnṣe àṣeélẹ̀ Rizwi; Dípò bẹ́ẹ̀, ó dábàá kí wọ́n kọ Ìtàn Darul Uloom Deoband apá kẹta.[8] Ní ìgbẹ̀yìn ọdún náà, Abu Hisham Qasmi dábà pé fífi “Mukhtasar” (ní ṣókí) sínú àkọlé ìwé tuntun náà túmọ̀ sí pé Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ Darul Uloom Deoband le koko, nítorí náà kí wọ́n ṣọ́ra fún kíkóyán iṣẹ́ ìpìlẹ̀ kéré.
See also
àtúnṣeReferences
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 Qasmi, Muhammadullah (2020) (in ur). Darul Uloom Deoband Ki Jame O Mukhtasar Tareekh (3rd ed.). India: Shaikh-Ul-Hind Academy. p. 39. OCLC 1345466013. https://archive.org/download/dar-al-aloom-deoband-ki-jame-aor-mukhtasar-tareekh/Dar%20al%20aloom%20deoband%20ki%20jame%20aor%20mukhtasar%20tareekh%20%D8%AF%D8%A7%D8%B1%D8%A7%D9%84%D8%B9%D9%84%D9%88%D9%85_%D8%AF%DB%8C%D9%88%D8%A8%D9%86%D8%AF_%DA%A9%DB%8C_%D8%AC%D8%A7%D9%85%D8%B9_%D9%88_%D9%85%D8%AE%D8%AA%D8%B5%D8%B1_%D8%AA%D8%A7%D8%B1%DB%8C%D8%AE_%D8%AF%D8%A7%D8%B1%D8%A7%D9%84%D9%85%D8%A4%D9%84%D9%81%DB%8C%D9%86.pdf.
- ↑ Rizwi, Syed Mehboob (1981) (in en). History of the Dar al-Ulum Deoband. 2. UP, India: Idara-e Ihtemam, Darul Uloom Deoband. p. 3. OCLC 20222197. https://archive.org/details/2VolumeBookOnTheHistoryOfDarAlUlumDeoband.
- ↑ Qasmi, Abu Hisham (2019) (in ur). Tareekh Ke Qatil Haqaeq Ke Aaine Mein. India: Kutubkhana Deoband. p. 24. https://archive.org/download/tareekhkeqatilhaqaeqkeaainemein/Tareekh%20ke%20Qaatil%20Haqaeq%20ke%20Aaine%20mein.pdf.
- ↑ 4.0 4.1 Akbarabadi, Saeed Ahmad (1978). "Muhbub Hasan Rizvi ki kitaab 'Tareekh Darul Uloom Deoband' ki isha'at" (in ur). Monthly Burhan (India: Nadwatul Musannifeen): 195. https://articles.rasailojaraid.com/Resources/ArticleFiles/20/2219/31602.pdf. Retrieved 28 November 2023.
- ↑ Usmani, Taqi (2005) (in ur). Tabsre. Pakistan: Maktaba Ma'ariful Quran. pp. 136. https://archive.org/details/Tabsre_201610.
- ↑ Qasmi 2019, p. 39.
- ↑ Akhtar, Muhammad Naveed (2022). "Darul Ulum Deoband: Preserving Religious And Cultural Integrity Of South Asian Muslims Through Structural And Strategic Innovations" (in en). Hamdard Islamicus 45 (3): 84. doi:10.57144/hi.v45i3.326. ISSN 0250-7196. https://hamdardislamicus.com.pk/index.php/hi/article/view/326. Retrieved 26 December 2023.
- ↑ Ukashah, Abu (2019) (in ur). Tareekh ke Qatil. Hyderabad, India: Faran Publications. OCLC 1106138522. https://archive.org/download/tareekhkeqaatilabuukashahrahman/Tareekh%20Ke%20Qaatil-Abu%20Ukashah%20Rahman.pdf.