Òkè-Ìmẹ̀sí
Ìlú Òkè-Ìmẹ̀sí jẹ́ ìlú kan lára awọn ìlú tí ó korajọ pọ̀ di ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ Oòrùn Èkìtì LGA ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì.[1] [2][3][4] Wọ́n fi léde wípé iye àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ìlú náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n( 30,000).
Bí ó ṣe tó
àtúnṣeÌlú Òké-Ìmẹ̀sí wa ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òké-Ìmẹ̀sí tó 7.82° ìbú ní apá Gúsù nígbat tí ó tó 4.92° òró ní apá Àríwá tí ó sì tó 541 fífẹ́ ní iye. Coordinates: 7°49′0″N 4°55′0″E / 7.81667°N 4.91667°E Ìkóró-Èkìtì àti Ìjerò-Èkìtì ni ó pààlà pẹ́lú Òké-Ìmẹ̀sí ní apá àríwá nígbàtí òun àti Ẹfọ̀n Alààyè pààlà ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ní apá Gúsù ni Ìmẹ̀sí-Ilé wà sí Òké-Ìmẹ̀sí, tí ìlú Òké-Ìmẹ̀sí sì pààlà pẹ̀lú àwọn ìlú bíi: Ẹ̀sà-Òkè àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[5] Bí ìlú náà ṣe ní òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ó jẹ́ kí ó dùn ún wò ati láti lọ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àyè ìgbafẹ́. Bákan náà ni ọyẹ́ tí ó ma ń mú níbẹ̀ ní àsìkò ọyẹ́ ma ń tutù mọ́ni fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni. Àwọn ilẹ̀ ibẹ̀ gbogbo ni ó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá fún nkan ọ̀gbìn, bákan náà ni àwọn ohun alùmónì oríṣiríṣi sòódó síbẹ̀.
Ìtàn ìlú Òké-Ìmẹ̀sí
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wípé gbogbo ọmọ káàrọ-oò-jíire ni wọ́n ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orírun baba-ńla wọn, bá kan náà ni ti ìlú Òké-Ìmẹ̀sí rí. Mọ̀lẹ́bí àti ìbátan kan náà ni Ìlú Òkè-Ìmẹ̀sí, Ìmẹ̀sí-Ilé àti Ilé-Ifẹ̀. Ọba àti aláṣẹ pátápátá ti ìlú Òkèmẹ̀sí ni wọ́n ń pè ní Ọwá Oòyè ti ìlú 'Òké-Ìmẹ̀sí'. Orúkọ ọba tí ó wà ní orí àpèrè àṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Ọba Gbádébọ̀ Adédèjì
Àwọn lààmì-laaka ènìyàn láti ìlú Òké-Ìmẹ̀sí
àtúnṣe- Rẹ̀mí Adédèjì, ònkọ̀wé ọmọ bí ìlú Òké-Ìmẹ̀sí tí wọ́n bí ní ọdún 1937.
- Kọ́lá Ògúnmọ́lá, gbajú-gbajà ònkọ̀tàn eré sinimá Yorùbá tí wọ́n bí ní ìlú Òké-Ìmẹ̀sí ní ọdún 1925
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Agan, Okemesi Ilu (2014-10-16). "Welcome to Okemesi!". okemesi Ilu Agan. Archived from the original on 2021-01-24. Retrieved 2020-12-21.
- ↑ "Ekiti: A rocky state and its untapped potentials". Sun News. September 11, 2014. http://sunnewsonline.com/new/?p=81261.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2012-07-24. Retrieved 2020-12-21.
- ↑ http://www.maplandia.com/niger/ekitiwest/oke-mesi/
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2016-11-09. Retrieved 2020-12-21.