Àwọn Ìjẹ̀bú jẹ́ ẹ̀yà kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n jẹ́ lára àwọn ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ sí gúúsù àárín gbùngbùn ilẹ̀ Yorùbá, tó wà ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Èdè Ìjẹ̀bú jẹ́ èdè tí wọ́n máa ń sọ, èdè ti wọ́n yàtọ̀ sí èdè Yorùbá, ṣùgbọ́n wọ́n sun mọ́ ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìjẹ̀bú dẹ̀ máa ń sọ èdè Yorùbá bí èdè abínibí ti wọn torí pé ìgbélárugẹ èdè Yorùbá ju ìyẹn ti èdè Ìjẹ̀bú lọ nítorí pé àwọn onígbàgbọ́ nílẹ̀ Yorùbá ti lo èdè Yorùbá bí èdè ẹ̀sìn ti wọn, ó ti sì jẹ́ èdè ti ilé-ìwé náà ní sáà ìjọba amúnisìn títí dìsin.

Àpèjúwe

àtúnṣe

Ìjẹ̀bú pín ààlà ní àríwá pẹ̀lú àwọn Ìbàdàn, ní ìwọ̀-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbá, àti ní ìlà-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìlàjẹ, gbogbo sì jẹ́ àkópọ̀ ẹgbẹ́-ẹgbẹ́ Yorùbá mìíràn. Ìjẹ̀bú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo ẹ̀yà ìsàlẹ̀ ẹ̀yà Yorùbá. Wọ́n dẹ̀ sọ pé àwọn Ìjẹ̀bú ni tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti dá àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Òyìnbó sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kárùn-úndínlógún (15th century). Àwọn Ìjẹ̀bú, bí ó tílẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n pín sí oriṣiriṣi ìpín (pẹ̀lú Ìjẹ̀bú-Òde, Ìjẹbú-Igbó, Ìjẹ̀bú-Ìmuṣin, Ìjẹ̀bú-Ifẹ̀, Àgọ́-Ìwòyè àti Ìjẹ̀bú-Ọ̀sọ̀sà ), wọ́n ṣì wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí lábẹ́ àṣẹ ti Awùjalẹ̀, tó wà ní Ìjẹ̀bú-Òde. Èèyàn láyìíkà ilẹ̀ Yorùbá mọ àwọn Ìjẹ̀bú fún ìṣówó àti gàárí (tó wá láti ẹ̀gẹ́) ti wọn tó gbajúmọ̀ ní gbogbo àgbáyé.