Ẹ̀yà ara ìfọ̀
Ẹ̀yà ara ìfọ̀, tàbí ibùsọ̀rọ̀, ni àwọn ẹ̀ya ara kan tí ó dá wà fún ọ̀rọ̀ sísọ́ tàbí kí á lò wọ́n fún àgbékalẹ̀ èdè láti ẹnu. Àwọn èyà ara ìfọ̀ náà ni:
- ètè méjèjì,
- Eyín, eyín nfihan ipele àlàfíà ti ènìyàn wa lapapọ. ẹyín gbọdọ wa ni mimọ láìsí jijẹra, ki o funfun ki o le koko ki o sin ma dan pẹlu ori ti mu daradara. Àgbàlagbà yẹ kio ni eyín mejilelọgbọn (merindinlogun ni abala oke ati isalẹ). Ni ọdún méjì àti àbọ̀, ọmọdé yẹ ki o ni eyín ogún keeke, (mẹwa-mẹwa ni abala oke ati isalẹ) Iwadi fi idi rẹ múlẹ pe awọn ohun ti ko tọ nípa eyín ni, eyín ti ko pe, eyín ti o sọnu, eyín ti o ge ati eyín ti ko duro deede. Awọn aràn tí o ma ùn se eyín ni wọnyi jijẹra nipa igo ounjẹ ọmọde (baby-bottle tooth decay), epulis, meth mouth and Hutchinson's teeth.
- erìgì òkè
- erìgì tìsàlẹ̀,
- Àjà ẹnu,
- káà ọ̀fun,
- tááná àti
- ahọ́n pẹ̀lú ìṣesí rẹ̀.
Àwọn Ìṣesí ẹ̀yà ara ìfọ̀
àtúnṣeÌṣesí méjì ló wà fún àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó wà, ìṣesí alkọ̀ọ́kọ́ ni
- ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó ń sún. Lára àwọn wọ̀nyí ni ahọ́n], ètè àti káà ọ̀fun.
- ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí kíì sún. Àwọn wọ́nyí ni eyín, erìgì òkè àti erìgì ìsàlẹ̀ àti àjà ẹnu.
- Àkíyèsí pàtàkì: bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a ka tááná mọ́ ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó ń sún, ṣùgbọ́n kòsí lára wọn, ó kàn jẹ́ ọ̀nà tí ohùn àti ọ̀rọ̀ ń gbà lásán ni.Ẹ̀wẹ̀ ahọ́n nìkan ni ó jẹ́ pé ma ń ṣiṣẹ́ jùlọ nínú àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ nípa ètò ìró àti ìbánisọ̀rọ̀.
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Rachael-Anne Knight (2012), Phonetics – A course book, Cambridge University Press, p.27