Ẹja yíyan
Ẹja yíyan jẹ́ ẹja tí a ṣètọ́jú nípasẹ̀ yíyan. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ènìyàn ti máa ń yan ẹja. Wọ́n máa ń ṣe é láti fi pa oúnjẹ́ mọ́.[1]
Ìlànà
àtúnṣeA lè se ìlànà yíyan ẹja bí a bá yan ní òtútù níbi tí ooru rẹ̀ kò bá ju 30 °C lọ tàbí bí a bá yan ní gbígbóná níbi tí ooru rẹ̀ bá tó 80 °C. Àwọn ipò tí wọ́n ti ń yan ni yóò pinnu bí ẹja tí wọ́n yan náà ṣe máa rí, bó ṣe máa dùn tó àti bó ṣe máa wúlò tó. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń gbé nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹja ni pé kí wọ́n fi nǹkan pa á lára, kí wọ́n sì fọ ẹja náà mọ́ tónítóní, ìyẹn ni pé kí wọ́n yọ ẹ̀jẹ̀ àti ìfun rẹ̀ kúrò, kí wọ́n sì fọ ẹja náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá fi iyọ̀ sínú omi iyọ̀ tó ti yó, èyí á sì dín omi tó wà nínú ẹja náà kù, á sì mú kí àwọn èròjà aṣaralóore tó wà ní ara ẹja náà dì gbagidi.[1]
Irúfẹ́ ọbẹ̀ àti oúnjẹ tí ó bá lọ
àtúnṣeẸja tí a yan jẹ́ pípé fún Ọbẹ̀ Ilá ti ilẹ̀ Nàìjíríà, Ìrẹsì alásèpọ̀ àti Abacha. Nígbà míì, a máa rí i nínú Ọbẹ̀ Ewúro àti Ọbẹ̀ Orá (Oha) àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọbẹ̀ àbínibí Nàìjíríà.[2] Ẹja yíyan máa ń sábà lọ nínú ata dindin fún ìrẹsì. Irúfẹ́ ata díndín yìí wọ́pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá láàárín àwọn Yorùbá.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Ogbadu, L.J. (2014). "PRESERVATIVES". Encyclopedia of Food Microbiology. Elsevier. p. 141–148. doi:10.1016/b978-0-12-384730-0.00261-5. ISBN 978-0-12-384733-1.
- ↑ "Smoked Fish (Nigerian Style)". All Nigerian Recipes. 2019-04-21. Retrieved 2024-11-24.