Abà tàbí Abúlé ni ìletò kan tí a kọ́ ilé oríṣríṣi sí tí àwọn ènìyàn dá sílẹ̀ fún gbígbé. Abà tàbí abúlé ma ń fẹ̀, tóbi tí ó sì ma ń ní èrò púpọ̀ ju ahéré lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, abúlé ló sábà ma ń dàgbà sókè di ìlú ńlá nípa bí àwọn ènìyàn bá ṣe ń pọ̀ si. Kí á tó lè pe ibì kan ní abúlé, ó ní láti jẹ́ wípé iye àwọn ènìyàn tí ó ń gbé níbẹ̀ tó ọgọ́rùn ún sí ẹgbẹ̀rún kan níye. Púpọ̀ àwọn abúlé tàbí abà ni wọ́n ń wà ní ìgbèríko tàbi àrọko tí wọ́n sì ma ń yan iṣẹ́ ọ̀gbìn láàyò lọ́pọ̀ ìgbà tàbí nka mìíràn gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ ajé. Àwọn ilé inú abúlé ma ń sábà fún pọ̀ tàbí sún mọ́ ara wọn , èyí sì ni ó ma m mú ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán wà láàrín àwọn olùgbé ibẹ̀.

کھوئیاںKhuian Village of Pakistan
Saldanda Village of Nepal
A village in Strochitsy, Belarus, 2008.
An alpine village in the Lötschental Valley, Switzerland
Hybe in Slovakia with Western Tatra mountains in background
Berber village in Ourika valley, High Atlas, Morocco

.[1].

Àwọn Ìtọ́ka síÀtúnṣe

  1. Dr Greg Stevenson, "What is a Village?" Archived 23 August 2006 at the Wayback Machine., Exploring British Villages, BBC, 2006, accessed 20 October 2009