Abisoye Ajayi Akinfolarin
Abísóyè Àjàyí Akínfọlárìn tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn ún, ọdún 1985 (19 May 1985) ní ìpínlẹ̀ Òndó jẹ́ oníṣẹ́ àdáni àti olù polongo ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ìyá tí kò ní ànfàní láti kẹ́kọ̀ọ́. Oùn ni olùdásílẹ̀ àjọ 'Pearls Africa Youth Foundation', tí kìí ṣe ti ìjọba tí ó sì ń lo àjọ náà láti kọ́ àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ìyá nípa ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ. Wọ́n fún Akínfọlárìn ní àmì-ẹ̀yẹ Akọni CNN (CNN Heroes) ti ọdún 2018 ní ọjọ́ Kínní oṣù Kọkànlá, ọdún 2018, nígbà tí wọ́n tún fi orúkọ rẹ̀ sínú Àwọn obìnrin ọgọ́rún àkọ́kọ́ ti BBC (100 Women (BBC)|100 Women) ní òpin oṣù yí kan náà.
Abisoye Ajayi-Akinfolarin | |
---|---|
Abísóyè Àjàyí Akínfọlárìnn, 2018 | |
Ọjọ́ìbí | ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn ún, ọdún 1985 19 May 1985 (33 years) Ìpínlẹ̀ Òndó,Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | University of Lagos |
Iṣẹ́ | Aṣègbè fódọ́mọbìnrin, obìnrin àti olùṣòwò |
Ọmọ ìlú | Ìpínlẹ̀ Èkìtì , Nàìjíríà |
Website | Pearls Africa.org |
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeÀjàyí Akínfọlárìn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Ilé iṣẹ́ E. D. P Audit and Security Associates. Níbi tí ó ti ṣíṣẹ́ fún odidi ọdún Méje gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ṣẹ́, ṣáájú kí ó tó ṣiṣẹ́ dé ipò Associate Consultant ní Ilé iṣẹ́ náà. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa Ìmọ̀ ẹ̀rọ, Skínfọlárìn ṣàkíyèsí wípé iye àwọn obìnrin tí ó nímọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ́rọ kò tó nkan, pàá pàá jùlọ bí ìwádí tí ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ní ọdún 2013 ní agbọ́nrin yí fi han wípé ìdá mẹ́jọ péré nínú ìdá ọgọ́rùn ún àwọn obìnrin ló nímọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Èyí ni ó gún Àjàyí ní kẹ́ṣẹ́ láti dá àjọ tirẹ̀ kalẹ̀ tí yóò ma ṣàmójútó àlébù yí.[1] Ní ọdún 2012, Àjàyí dá Pearls Africa Youth Foundation' kalẹ̀ láti lè mú ìdàgbàsókè bá àwọn obìnrin nínú ìmọ̀ ẹrọ. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ wọn ni: GirlsCoding, G.C Mentors, GirlsInSTEM and Empowered Hands.[2]Láti ọdún 2012, ilé iṣẹ́ rẹ̀ ti kọ́ àwọn obìnrin tí ó tó irinwó (400) lákọ̀ọ́ yanjú.[3]
Àmì ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá àti ìdánimọ̀ rẹ̀
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Disadvantaged Girls Change their Communities by Learning to Code". CNN. Retrieved 1 November 2018.
- ↑ "Pearls Africa". Viva Naija.com. Archived from the original on 2019-04-15. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Top 10 CNN Heroes of 2018 revealed". CNN. Retrieved 1 November 2018.
- ↑ "BBC 100 Women 2018: Who is on the list?" (in en-GB). 2018-11-19. https://www.bbc.com/news/world-46225037.
- ↑ "ONE's 2018 Women of the Year Awards". ONE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-19. Archived from the original on 2019-08-19. Retrieved 2019-02-04.