Ada ọmọ daddy
Ada, Ọmọ Daddy jẹ́ eré àgbéléwò tí wọ́n gbé jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2023,tí ó ń pa ni lẹ́rìn-ín tí Yakubu Olawale sì kọ. Mercy Aigbe[1], Akay Mason àti Adebayo Tijani ni wọ́n gbé e jáde tí wọ́n sì darí rẹ̀. Fíìmù náà dá lórí , ìtànjẹ nípa òbí tí àṣírí sì tú ní ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó. Àwọn òṣèré Nollywood bíi Charles Okafor , Sola Sobowale, Mercy Aigbe, Chiwetalu Agu àti Uche Ndubuisi.[2][3]
Ada ọmọ daddy | |
---|---|
Adarí |
|
Olùgbékalẹ̀ | Mercy Aigbe |
Òǹkọ̀wé | Yakubu Olawale |
Àwọn òṣèré | |
Orin | Adam Songbird |
Ìyàwòrán sinimá | Barnabas Emordi |
Olóòtú | Adio Solanke |
Olùpín | Cinemax distribution |
Déètì àgbéjáde | 15 December 2023 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
Agbékalẹ̀ eré náà
àtúnṣeAda Omo Daddy sọ ìtàn Pero (Omowumi Dada) ,ẹni tí ó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó pẹ́lú Victor (Tayo Faniran). Ilé-ayé Pero yí padà ní ọ̀nà tí ó yani lẹ́nu nígbà tí Ifeanyi (Charles Okafor) dédé yọjú tí ó sì sọ wípé òun ni bàbá tí ó bí i,èyí tí ó dá wàhálà sílẹ̀ ní ilé Balogun tí ó tòòrò tẹ́lẹ̀ . Jíjáde tí Ifeanyi jáde lójijì yìí, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé kò kọbi ara tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ti yí padà báyìí ,tú àwọn àṣírí tí ó ti wà sẹ́yìn ,tí ó sì gbọ́dọ̀ ní ìyànjú kí Pero àti Victor tó ṣe ìgbéyàwó. [4]
Àwọn òṣèré
àtúnṣe- Sola Sobowale bíi Mrs. Ireti Balogun
- Mercy Aigbe bíi Motunrayo tó ti dàgbà
- Omowumi Dada bíi Peresola Balogun
- Tayo Faniran bíi Victor
- Charles Okafor
- Chiwetalu Agu bíi Uncle Ndubuisi
- Uche Ndubuisi
- Taiwo Adeyemi
- Adeniyi Johnson bíi Ifeanyi (nígbà tó ṣì kéré)
- Carol King bíi Mrs. Ekpeyong
- Dele Odule bíi Chief Balogun
- Tomi Ojo bíi Fara
- Nkechi Blessing bíi Ndidi
- Unusual Phyna bíi Ìrètí (ní ọmọdé)
- Miriam Peters bíi Ezinne
Ìgbàwọlé
àtúnṣeAda Omo Daddy wà lára fíìmù tí Premium Times fi sí ara fíìmù mẹ́wàá àkọ́kọ́ fún àsìkò ọdún ní ọdún 2023.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Nigeria, Guardian (2023-09-02). "Mercy Aigbe: On why ' Ada Omo Daddy' is the movie to anticipate". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-02-19. Retrieved 2024-02-18.
- ↑ "Movie Title: Ada Omo Daddy". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2024-02-17. Retrieved 2024-02-18.
- ↑ Stephen, Onu (2023-12-26). "'Ada Omo Daddy': 'Wedding Party' copy that falls short in several ways". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-18.
- ↑ Oloruntoyin, Faith (2023-11-27). "Love becomes chaotic in Mercy Aigbe's star-packed 'Ada Omo Daddy' trailer". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-18.
- ↑ Olusola, Elijah (2023-12-25). "Ada Omo Daddy, Osato, Nine other movies to watch this season". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-19.