Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Egbeda
Egbeda jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Olú-ìlú rẹ̀ wà ní ìlú Egbeda. Wọ́n gé agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Egbeda kúrò nínú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Lagelu, ní ọdún 1989. Kóòdù ìfíwéránṣẹ́ ìlú náà ni 200109[1]
Egbeda | |
---|---|
LGA and town | |
Egbeda bus stop | |
Coordinates: 7°22′53″N 3°57′59″E / 7.3813°N 3.9665°ECoordinates: 7°22′53″N 3°57′59″E / 7.3813°N 3.9665°E | |
Country | Nigeria |
State | Oyo State |
Government | |
• Local Government Chairman and the Head of the Local Government Council | Oyedele Sikiru Sanda (PDP) |
Time zone | UTC+1 (WAT) |
Ìwọ̀n ilẹ̀
àtúnṣeÌlú yìí ní ilẹ̀ tó tóbi tó 191 km2 ài iye ènìyàn tó tó 281,573 ní ìka orí tí ó wáyé ní ọdún 2006.
Ìṣèjọba
àtúnṣeAgbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Egbeda pín sí ìpín mọ́kànlá (11), àwọn ni: Erunmu, Ayede/Alugbo/Koloko, Owo Baale/Kasumu, Olodan/Ajiwogbo, Olodo/Kumapayi I, Olodo II, Olodo III, Osegere/Awaye, Egbeda, Olode/Alakia, àti Olubadan Estate.
Alága kan tí wọ́n yàn sípò àti káńsẹ́lọ̀ mọ́kànlá lọ́ ń sẹ̀jọba ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ náà.
Oyè olùṣàkóso ìbílẹ̀ náà ni Elegbeda ti Egbeda, èyí ti Oba Victor Sunday Olatunde Okunola jẹ́ olórí náà lọ́wọ́lọ́wọ́. Wọ́n sì tún jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba àti ìjòye ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ojú ọjọ́
àtúnṣeOṣù tó gbóná jù tí oòrùn sì máa ń yọ jù ni oṣù Ẹ̀rẹnà (March), oṣù tó sì tutù jù ni oṣù Ògún (August). Ìwọn ojú ọjọ́ ìlú Egbeda máa ń ṣe ségesège, láti ìgbà tó kéré jù lọ àti ìgbà tó ga jù lọ.[2][3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 2009-10-07. Retrieved 2009-10-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Egbeda Climate, Weather By Month, Average Temperature (Nigeria) - Weather Spark". weatherspark.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-15.
- ↑ "Egbeda, Oyo, Nigeria - City, Town and Village of the world". en.db-city.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-15.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]