Agnes Osazuwa
Òrọ̀ ẹni | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Kẹfà 1989 Benin, Ìpínlẹ̀ Edo |
Agnes Osazuwa tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1989 (26 June 1989) ní ìlú Benin, Ìpínlẹ̀ Edo jẹ́ eléré-ìjẹ lórí pápá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó máa ń díje fún Nàìjíríà.[1]
Agnes ṣojú Nigeria ní ìdíje Òlímpíkì ti ọdún 2008 ní Beijing, lórílẹ̀-èdè China, ó díje nínú eré gbagigbagi onìwọ̀n mita 4x100 pẹ̀lú Gloria Kemasuode, Olúdàmọ́lá Ọ̀sáyọ̀mi àti Ene Franca Idoko. Ó tún kópa nínú ìdíje gbagigbagi oníwọ̀n mítà 4x100. Wọ́n gba àmìn-ẹ̀yẹ ipò kẹta nínú àṣekágbá ìdíje náà. Orílẹ̀-èdè Russia àti Belgium ni wọ́n gba ipò kìíní àti kejì.[1] lọ́dún 2016, wọn gba ipò kìíní ìdíje náà lọ́wọ́ orílẹ̀ èdè Russia, nítorí pé ọ̀kan nínú àwọn olùdíje náà, Yuliya Chermoshanskaya ní àṣírí rẹ̀ tú pé ó lógún olóró, èyí ní wón fi wá fi Nàìjíríà sí ipò kejì dípò ipò kẹta tí wọ́n kọ́kọ́ wà tẹ́lẹ̀.[2]
Àwọn àṣeyọrí ìdíje rẹ̀
àtúnṣeRepresenting Nàìjíríà | |||||
---|---|---|---|---|---|
2008 | World Junior Championships | Bydgoszcz, Poland | 9th (sf) | 100m | 11.68 (wind: -0.7 m/s) |
12th (h) | 4 × 100 m relay | 45.30 | |||
Olympic Games | Beijing, PR China | 2nd | 4 × 100 m relay | 43.04 s |
Àwọn ìtọ́kasí ìta
àtúnṣe- Àdàkọ:World Athletics
- Àdàkọ:IOC profile
- Àdàkọ:Olympic Channel
- Àdàkọ:SR/Olympics
- Agnes Osazuwa at NBC Olympics website
Àdàkọ:Nigeria-Olympic-medalist-stub
Àdàkọ:Nigeria-athletics-bio-stub
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Athlete biography: Agnes Osazuwa, beijing2008.cn, ret: 30 Aug 2008
- ↑ "Russia stripped of Beijing 2008 women's relay gold after positive retest by team member". insidethegames.biz. 16 August 2016.