Al-Da'i jẹ́ ìwé Lárúbáwá èyí tí wọ́n ń ṣe àtẹ́jáde rẹ̀ lóṣoṣù láti Darul Uloom Deoband, lábẹ́ ìdarí olóòtú Wahiduzzaman Kairanawi ní ọdún 1976.[1][2] Àfojúsùn pàtàkì ti ìwé náà ni àwọn ènìyàn pàtàkì - pátákí ti Darul Uloom Deoband àti àwọn tó ti kàwé gboyè nìkan. Látàrí ìyàtọ̀ rẹ̀, ó ti fa ọkàn àwọn onímọ̀ láti orílẹ̀ èdè India àti Arab world.[3] Abul Qasim Nomani ni ó ṣe àkójọpọ̀ ìwé náà nígbà tí Arif Jameel Mubarakpuri sì jẹ́ olóòtú àgbà. Noor Alam Khalil Amini jẹ̀ olóòtú pàtàkì fún ìwé yìí.

Gbígbà Wole

àtúnṣe

Qasim Yusuf al-Shaykh, onímọ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí kan láti Bahrain, yin ìwé náà, ó sọ wípé, "inú wa dùn púpọ̀ láti kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú àwọn ìwé ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ẹ kọ nibi tí a ti rí ẹ̀mí ti Islam àti èrò tí ń lani lọ́yẹ nípa ìgbàgbọ́. Inú wa sì dùn jùlọ nígbà tí a rí àwọn àyọkà nípa Muhammad Tayyib Qasmi, olórí Yunifásítì Mùsùlùmí ní Deoband àti àwọn ẹni pàtàkì mìíràn."[3]

Àwọn Ìtọ́kási

àtúnṣe

Citations

àtúnṣe
àtúnṣe