Alamu Atatalo
Àlàmú Tátalọ̀ ni olùdásílẹ̀ orin [1] ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀[2] . Orin tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orin ìbílẹ̀ Yorùbá. Àlàmú jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, ó sì gbajúmọ̀ gidi ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá látàrí ìwọ́hùn àti ìṣọwọ́ lè orin sákárà rẹ̀ ní àsìkò ọdún 1950 sí ọdún 1960. Amọ́ iyì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ń wọmi nígbà tí àwọn alátakò rẹ̀ parọ́ mọ lórí ẹ̀sùn tí kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Ó lo tó nkan bí ọdún mẹ́wàá kí ó tó ri ara rẹ̀ fọ̀ mọ́ kúrò nínú àkóbá náà láì sinmi. Lẹ́yìn tí ó bọ́ nínú ọ̀ràn, ó padà sórí ọpọ́n, ó sì gbapò rẹ̀ padà gẹ́gẹ́ olórí àti olùdásílẹ̀ orin Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó gbé àwọn àwo orin tó ń hoorù jáde lsbẹ́ ilé-iṣẹ́ agbórinjáde LP Records ní à àárín ọdún 1970. Orin Sẹ̀kẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti orin àwúrèbe ti Alhaji Dauda Epo-Akara ni ó gba ìgboro Ìbàdàn kan lásìkò yí ṣáájú kí orin Fújì tó wọlé dé wẹ́rẹ́ láti ẹnu olóyè Alhaji Sikiru Ayinde Barrister.
Àwọn Itọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Alamu Atatalo biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1985-03-08. Retrieved 2021-02-19.
- ↑ Pinterest (in Èdè Welshi) https://www.pinterest.com/pin/27795722674183766/. Retrieved 2021-02-19. Missing or empty
|title=
(help)