Amina Mama
Amina Mama (tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣú kẹsàn-án ọdún 1958) jẹ́ oǹkòwé, ajàfúnẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Gẹẹsi.[2] Àwọn ǹ kan tí ó dojúkọ gangan ni àwọn ǹ kan tí ó jẹ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn ìjọba amúnisìn, ti ológun àti ti abo. Amina ti gbé ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà, Yúróoṕù, àti Àríwá Amẹ́ríkà àti wípé ó ti ṣiṣẹ́ láti mú ìbáṣepọ̀ láàrin àwọn onímọ̀ àti olóyè obìnrin kákàak̀iri àgbáyé.
Amina Mama | |
---|---|
Mama ni odun 2019 | |
Orúkọ | Amina Mama |
Ìbí | 19 Oṣù Kẹ̀sán 1958 Kaduna, Colonial Nigeria |
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ | feminism, postcolonialism |
Ìjẹlógún gangan | women, militarism, police, neoliberalism, Africa |
Ipa látọ̀dọ̀
Amina of Zazzau, Aisha Lemu, Hajia Gambo Sawaba, Funmilayo Ransome-Kuti, Karl Marx, Louis Althusser, Antonio Gramsci, Jean-Paul Sartre, Simone de Beauvoir, Frantz Fanon, Nkrumah, Edward Said, Michel Foucault, Bessie Head, Nawal El Saadawi, Alifa Rifaat, Ama Ata Aidoo, Flora Nwapa, Angela Davis, Audre Lorde[1]
|
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé e rẹ̀
àtúnṣeA bí Mama ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà [3] ní ọdún 1958 ní ìdílé aládàlù. Bàbá rẹ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí ìyá rẹ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Gẹẹsi.[4] Gẹ́gẹ́ bí Mama ti sọ, ó ní ìpìnlẹ̀ ìdílé òun àti bí wọ́n ṣe tọ́ òun dàgbà ti mú kí òun ṣe àgbékalẹ̀ ìwóye ìgbéayé òun. Ní ọdún 1992, ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Nuruddin Farah ẹni tí ó bí ọmọ méjì fún ún.[5]
Amina Mama dàgbà ní Ipinle Kaduna, níbití onírúurú ẹ̀yà àti ẹ̀sìn gbé wà, ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n tọpasẹ̀ àwọn ẹbí bàbá rẹ padá lọ sí Bida. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn mọ̀lẹ́bí Mama ni wọ́n kó ipa nínú ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́ ti agbègbè wọn lẹ́yìn ìjọba amúnisìn. Ní ọdún 1966, ó fi agbègbè rẹ tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ nítorí rògbòdìyàn tí ó tako Mùsùlùmí.
Iṣẹ́ ẹ rẹ̀
àtúnṣeMama kúrò láti orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀-èdè Gẹẹsi láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ ọ rẹ̀ ní Yinifásítì ti St. Andrews tí ó wà ní ìlú Scotland, ní ọdún 1980 níbi tí ó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ lórí i Psychology, àti ilé-ìwé ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀-ọjà àti ìmọ̀-ọrọ̀ òṣèlú ni Yunifásítì ìlú London ní ọdún 1981 níbi tí ó ti gba oyè ẹlẹ́ẹ̀kejì nínú ìmọ̀ lórí Social Psychology. Ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Birkbeck, Yunifásítì ìlú London yi kanná àn ni ó ti gba oyè dọ́kítà lórí Organizational Psychology ní ọdún 1987. Àkọlé àtilẹ̀kọ ẹ̀kọ́ rẹ ni "Ẹ̀dá aláwọ̀ àti kókó-ọ̀rọ̀: ìwádì í nípa àwọn obìnrin aláwọ̀dúdú". Àwọn iṣẹ́ ẹ rẹ̀ tí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀ ló ní í ṣe pẹ̀lú ìfiwéra àwọn ipò ní àárín àwọn obìnrin ilẹ̀ Geesi àti ti ilẹ̀ Nàìjíríà.[6] Ó gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Netherlands àti lẹ́hìnńà padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì tún bá rúdurùdu púpọ̀ pàdé ní ọdún 2000[7]. Lẹ́hìnńà, ó gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa níbití ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Yunifásítì ìlú Cape Town. Ní Yunifásítì yí ni ó ti di olùdarí ti i African Gender Institute níbití ó ti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ ìwé ìròyìn ilé-ẹ̀kọ́ yi tí àkolè rẹ ń j́ẹ́ Feminist Africa. Mama ṣì ni olóòtú ìwé ìròyìn Feminist Africa yi.
Ní ọdún 2008, Mama gba ipò kan ní ilé-ẹ̀kọ́ Mills ní Oakland, California, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí ó ń lọ, ó ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ rẹ báyì í pé "Mo ti kọ́ pé Amẹ́ríkà ki i ṣe ńlá tàbí orísun ìjọba búburú". Ọ̀jọ̀gbọ́n Mama di alága ti Barbara Lee nínú adarí àwọn obìnrin ní Mills: òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ bọ́ sí ipò yi. Ó parapọ̀ láti kọ́ kíláásì tí wọ́n pè ní "Òfin tó dájú, Òṣèlú tó dájú" pẹ̀lú arábìnrin Lee, ẹni tí í ṣe arábìnrin ilé-ìgbìmọ̀ ìjọba lórí àwọn àkọlé nípa àwọn obìnrin Áfíríkà àti Áfíríkà-Amẹ́ríkà, pẹ̀lú àwọn ipa lórí i àbò, òṣì, HIV/AIDS àti ogun. Mama tún jẹ́ alága ti ẹ̀ẹ̀ka ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú California.[8]
Mama ni alága ti ìgbìmọ̀ àwọn olùdarí fún Global Fund for Women, àti wípé ó ń gba oríṣiríṣi àwọn àjọ àgbáyé òmíràn ní ìmọ̀ràn. Ó ti fi ìgbà kan wà lára ìgbìmọ̀ àwọn olùdarí tí Ile-iṣẹ Iwadi Iparapọ ti Ajo Agbaye fun Idagbasoke Awujọ.
Mama wà lára ìgbìmọ̀ tí ó ń fún ni ní ìmọ̀ràn fún àwọn ìwé ìròyìn ẹ̀kọ́ lórí abo, Meridians and Signs.[9][10]
Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ pàtàkì tí ó ti ṣe ni Beyond the Mask: Race, Gender and Subjectivity. Mama tún kó ipa nínú iṣẹ́ fíímù. Ní ọdún 2010, ó ṣe àgbéjáde fíímù naa tí í ṣe Àwọn Àjẹ́ ti Gambaga pẹ̀lú Yaba Badoe.[11]
Èrò o rẹ̀
àtúnṣeMama ṣe àpèjúwe ara a rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abo àti wípé òun kì í ṣe womanist, tí ó sì jiyàn wípé ọ̀rọ̀ nípa abo yi bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà àti wípé àwọn abo tí ó jẹ́ funfun "kò i ti lágbára tó láti jẹ́ ọ̀tá dé bi wípé a ó mà fi ojú ọ̀tá wo àwọn ìjọba oníṣòwò àgbáyé". Ó ti tako ìjíròrò lórí ìdàgbàsókè àwọn obìnrin fún yíyọ àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ní ìtunmọ̀ nípa ti abo. Ó tún ti jiyàn pé àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ Áfíríkà ń tẹ̀síwájú láti fi hàn nípa àwọn òfin ti ìbálòpọ̀ láàrín ara ẹni àti àwọn ti abo.
Apá ibi tí Mama ní ìfẹ́ sí jùlọ ni ti ìdánimọ̀ akọ-abo bí ó ṣe ní ìbátan sí ìjágun káríayé. Ó jẹ́ oǹtákò sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ti AFRICOM, èyí tí ó ṣe àpèjúwe bí ara ti ìwà àwọn olùṣèwádì ìṣèdiwọ̀n neocolonial.[12]
Àwọn ìwé tí ó ti kọ
àtúnṣe- The Hidden Struggle: Statutory and Voluntary Sector Responses to Violence Against Black Women in the Home. Runnymede, 1989; republished by Whiting and Birch, 1996. ISBN 9781861770059
- Black Women and the Police: A Place Where the Law is Not Upheld, in Inside Babylon: The Caribbean Diaspora in Britain, ed. Winston James and Clive Harris. London: Verso, 1993. ISBN 9780860914716.
- Beyond the Masks: Race, Gender, and Subjectivity. New York: Routledge, 1995. ISBN 9780415035446.
- National Machinery for Women in Africa: Towards an analysis. Third World Network, 2000. ISBN 9789988602017.
- "Is It Ethical to Study Africa? Preliminary Thoughts on Scholarship and Freedom". African Studies Review 50 (1), April 2007.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Amina Mama", GWS Africa Archived 2011-02-28 at the Wayback Machine., 5 August 2008.
- ↑ "Amina Mama Celebrates Her 62nd Birthday Today". ABTC. 2020-09-19. Retrieved 2020-11-08.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "One-way ticket just isn't an option". Times Higher Education (THE). 2006-01-13. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ Mama, A. (1995). Beyond the Masks: Race, Gender and Subjectivity. Critical psychology. Routledge. ISBN 978-0-415-03543-9. https://books.google.com.ng/books?id=fKR42BIjdxwC. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "A Somali Author as Guide to a Dantean Inferno". The New York Times. 2004-05-19. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ Humm, M. (1992) (in sv). Modern Feminisms: Political, Literary, Cultural. Culture & Gender. Columbia University Press. p. 150. ISBN 978-0-231-08073-6. https://books.google.com.ng/books?id=hOpVmxvwskMC&pg=PA150. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "One-way ticket just isn't an option". Times Higher Education (THE). 2006-01-13. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "Amina Mama - SSRC". archive.is. 2013-04-15. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "Indiana University Press". Indiana University Press. 2020-11-03. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "Masthead". Signs: Journal of Women in Culture and Society. 2012-08-22. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "About - A documentary film by Yaba Badoe - Enjoy The Best Casino Guide With Dealers Live". The Witches of Gambaga. 2019-07-18. Retrieved 2020-11-08.
- ↑ "Where we must stand: African women in an age of war". openDemocracy. Retrieved 2020-11-08.