Angela Okorie

Òṣéré orí ìtàgé

Angela Okorie jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ní ọdún 2015, ó gba àmì-ẹ̀ye fún ti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards. Ó ti kópa nínu àwọn fíìmù tó lé ní ọgọ́rùn-ún.

Angela Okorie
Àwòrán Angela Okorie ninu fiimu ti akole re n je Agaracha
Ọjọ́ìbíAngela Ijeoma Okorie
Cotonou, Benin
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó
Yunifásitì ìlú Èkó
Iṣẹ́Oṣere
Ìgbà iṣẹ́2009-iwoyi

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Okorie jẹ́ ẹ̀kẹẹ̀ta nínu àwọn ọmọ márùn-ún ti òbí rẹ̀. A bi ní ìlú Cotonou, orílẹ̀-èdè Benin Republic níbi tí ó ṣì dàgbà sí. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ eré ìtàgéYunifásitì ìlú Èkó.[2] Ó tún lọ sí Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ ìṣàkóso ìlú . Ó jẹ́ ará ìlú Ishiagu ní agbègbè Ivo ní Ìpínlẹ̀ Ẹ̀bònyì.[3]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

àtúnṣe

Okorie wọ Nollywood ńi ọdún 2009, lẹ́hìn ọdún mẹ́wàá níbi ìfẹwàṣiṣẹ́ fún ilé-iṣẹ́ ọṣẹ kan. Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó ti kópa ni Sincerity ní ọdún 2009.[4] Fíìmù náà wá látọwọ́ Stanley Egbonini tí Ifeanyi Ogbonna ṣì jẹ́ olùdarí rẹ̀, tó sì n ṣàfihan Chigozie Atuanya, Nonso Diobi, Yemi Blaq àti Oge Okoye.[5] Gẹ́gẹ́bí ìwé-ìròyìn Pulse Nigeria ti ṣe sọ́ dí mímọ̀, ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn tí ó kópa nínu eré Holy Serpent. Òun náà sì ti sọ́ di mímọ̀ pé ó wu òun láti kọ orin ìhìnrere ní ọjọ́ iwájú.[6] Ní ọdún 2014, ìwé ìròyìn Vanguard ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́bi ọ̀kan nínu “àwọn òṣèré tí àwọn èyàn n wá jùlọ” ní Nollywood. Bákan náà, ìwé ìròyìn The Nation náà tún ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́bi “gbajúmọ̀ òṣèré” tí ó maá n túmọ̀ àwọn ipa rẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn.[7] Ó tún ṣàlàyé wípé òún ní ìpinnu láti máa gbéréjáde.

Ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ó ti ṣe ìgbeyàwó ó sì ti ní ọmọkùnrin kan. Nínu àtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Dailypost, ó ṣàlàyé pé ìgbàgbogbo ni òun maá n ṣe ìgbìyànjú láti ya ẹbí rẹ̀ ya àwọn oníròyìn. Nígbàtí ó n sọ̀rọ̀ lóri ìbálòpọ̀ obìrin sí obìrin ní Nàìjíríà, ó ṣàlàyé pé òun kò faramọ, pàápàá nítorí wípé àṣà wá kọ̀ọ́.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe