Arárọ̀míre

eré amóhùn máwòrán tí ójáde ní ọdún 2009

The Figurine: Arárọ̀míre jẹ́ eré amóhùn máwòrán tí ójáde ní ọdún 2009 tí Kemi Adesoye kọ, tí Kunle Afolayan ṣàgbéjáde àti atọ́kùn, rẹ̀ tí ó sì tún kópa nínu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkan gbọ̀n. Ramsey Nouah àti Omoni Oboli kópa nínú rẹ̀.

Eré yìí sọ ìtàn àwọn ọ̀ré méjì tí wọ́n rí ère alágbára ní ojúbọ tí wọ́n ti pa tì nínú igbó nígbà tí wọ́n ń ṣàgùnbánirọ̀, tí ìkan nínú wọn gbé ère yìí lọlé. Láìmọ̀ pé ère Arárọ̀míre tí ó maa ń gbé ire fún ènìyàn tí ó bá ri fún ọdún meje pẹlú ìyà ọdún méje míràn tí ó tẹ̀le. Ayé àwọn ọ̀ré méjì yìí bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní dára, tí wọ́n sì ń ní ìlọsíwájú àti ìgbéga nínú iṣẹ́ àti okùn òwò wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́yìn ọdú méje yìí, Gbogbo nkan bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú fún wọn.[1][2]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe