Kemi Adesoye
Kẹ́mi Adésọyè jẹ́ Òǹkọ̀tàn tí ó kọ gbajú-gbajà eré The Figurine. Ó sì tún ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré onípele lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán bí Tinsel.
Kemi Adesoye | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Olúwakẹ́mi Adésọyè Kaduna, Ìpínlè Kaduna, |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | screenwriter |
Ìgbà iṣẹ́ | 1998–present |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rè
àtúnṣeWọ́n bí Adésọyè ní Ìpínlẹ̀ Kwara, ni won to ni Ipinle Kaduna.[1][2] She is the last of four children.[3]
Adésọyè fẹ́ràn láti máa wo àwọn eré bíi eré apanilẹ́rìín, eré adẹ́rùbani, eré oníṣe àti àwọn eré onípele àtìgbà dégbà lóriṣiríṣi. Gẹ́gẹ́ bí akẹ̣́kọ́ nínụ́ ìmọ̀ Architecture ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì. Nígbà tí ó wà ní ọmọ akẹ́kọ́, ìfẹ́ tí ó ní sí ìtàn kíkọ ni ó mu kí ó ṣalábàápàdé ìwé kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "The Elements of Script Writing" tí Irwin R. Blacker kọ. [1][2] Lásìkò yí, kò tíì mọ̀ wípé wọ́n lè fi ìtàn kíkọ ṣe iṣẹ́ oòjọ́ ẹni. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Federal University of Technology, Minna, ní Ìpínlẹ̀ Niger láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìkejì nínú ìmọ̀.[2] Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìwẹ́ kíkọ. Oríṣiríṣi ìpènijà ni ó kojú látàrí àìsí ilé-ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ni nípa ìtàn kíkọ nígbà náà.[2]Lẹ́yìn tí ó ṣàkíyèsí ìfẹ̣́ rẹ̀ sí ìtàn kíkọ ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ nípa bí a ṣe ń kọ ìtàn àpilẹ̀kọ ní orí ẹ̀rọ ayélujára, tí ó sì tún lọ kọ́ nípa bí a ṣe ń kọ nípa ìtàn àpilẹ̀kọ ní New York Film Academy ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLẹ́yìn tí Adésọyè jáde nílé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò fún bí ọdụ́n márùn ún.[3] O kọ ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1998. Ó lọ sí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti IFBA International Film and Broadcast Academy, níbi tí ó ti kọ́kọ́ mọ̀ nípa iṣẹ́ àkànṣe tí wọ́n pè ní "New Directions" tí MNet ṣagbátẹrù rẹ̀. Lásìkò yí, ilé-iṣẹ́ yí ń wá ẹni tí ó lè kọ ìtàn ṣókí fún wọn, ó sì kọ ìtàn kékeré kan fún wọn tí ó pè ní "The Special Gele". Wọ́n mú ìwé ìtàn rẹ̀, lóòtọ́ kò gbébá orókè nínú ìdíje yí, àmọ́ ó ní ìfọ̀kànblalẹ̀ wípé ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ dára. Ó kópa nínụ́ ìdíje yí ní ọdún méjì lẹ́yìn , ó sì jáwé olúborí nínú ìdíje náà lér\ léra. Wọ́n si ya eré náà sínú sinimá àgbéléwò. [2][4]
Eré yí ni ó fún Adésọyè ní ànfàní láti bá àwọn jànkàn jànkàn nídí iṣẹ́ sinimá bí Amaka Igwe pàdé. Lẹ́yìn èyí, ó di òǹkọ̀tàn fún ilé-iṣẹ́ DStv, tí ó sì ń kọ àwọn ìtàn eré bí Doctors Quarters. Lẹ́yìn ò rẹyìn, ó ṣalábàpàdé gbajú gbajà olùgbéréjáde Kúnlé Afọláyan, ó kọ eré abanilẹ́rù The Figurine fún tí eré náà sì gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bí Africa Movie Academy Awards lẹ̣́yìn tí wọ́n gbe jáde tán.[2] Látàrí àṣeyọrí eré The Figurine, Adésọyè di ẹni ayé ń fẹ́ pàá pàá jùlọ ní àwùjọ Nollywood gẹ́gẹ́ bị òǹkọ̀wé. Ó tún ti kọ oríṣiríṣi ìtàn onípele àtìgbàdégbà bii: Edge of Paradise, Tinsel, Hotel Majestic, àti àwọn oríṣiríṣi eré mìíràn bí Phone Swap.[2]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣeEré sinimá
àtúnṣe- Fifty (2015)
- New Horizons (Short) (2014)
- African Metropolis (2013)
- The Line-Up (Short) (2013)
- Phone Swap (2012)
- The Figurine (2009)
- Prize Maze
Eré orí amóhùnmạ́wòrán
àtúnṣeÀwọn àmì-ẹ̀yẹ àti Ìdánimọ̀ rẹ̀
àtúnṣeYear | Award | Category | Work | Result |
---|---|---|---|---|
2012 | 2012 Best of Nollywood Awards | Screenplay of the Year | Phone Swap | Wọ́n pèé |
2013 | 2013 Nollywood Movies Awards | Best Original Screenplay | Phone Swap | Gbàá |
2013 Golden Icons Academy Movie Awards | Best Original Screenplay | Phone Swap | Wọ́n pèé |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Iwuala, Amarachukwu (25 June 2015). ""Writers Should Learn To Let Go" – Kemi Adesoye". 360nobs.com. Retrieved 24 June 2016.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 Njoku, Benjamin (25 April 2015). "‘My story as a screenplay writer’ – Kemi Adesoye". Vanguard. Retrieved 24 June 2016.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Oluwadahunsi, Olawale (29 July 2015). "ARTISTE UNCENSORED: Good story is like well-designed building –Kemi Adesoye". National Mirror. Archived from the original on 12 August 2016. Retrieved 24 June 2016.
- ↑ "How I Wrote Figurine – Kemi Adesoye". Top Celebrities Nigeria. Archived from the original on 18 August 2016. Retrieved 24 June 2016.